ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ طُوبَىٰ لَهُمۡ وَحُسۡنُ مََٔابٖ 29
Awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ti wọn si nsisẹẹre ti yoo sun wọn mọ Allah, isẹmin ti o dara nbẹ fun wọn ni ọrun, bakanna ni igbẹyin daadaa nbẹ fun wọn ni alujannah.
كَذَٰلِكَ أَرۡسَلۡنَٰكَ فِيٓ أُمَّةٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهَآ أُمَمٞ لِّتَتۡلُوَاْ عَلَيۡهِمُ ٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَهُمۡ يَكۡفُرُونَ بِٱلرَّحۡمَٰنِۚ قُلۡ هُوَ رَبِّي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ مَتَابِ 30
Apejuwe isẹ riran eyiti a fi ran awọn ojisẹ ti wọn ti siwaju si awọn ijọ wọn; a ran iwọ naa - irẹ ojisẹ - si ijọ rẹ; ki o le maa ka alukuraani eyiti wọn fi ran nsẹ si ọ fun wọn, o to ni itọka si ijododo rẹ sugbọn ijọ rẹ ni wipe wọn jiyan amin yii; toripe wọn se keferi Ọba Ajọkẹ Aye lati ibib mimu ẹlomiran mọ Ọ, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: Ọba Ajọkẹ Aye ti ẹ nmu ẹlomiran mọ yii Ohun ni Ọlọhun mi eyiti ẹni a njọsin fun lododo kosi yatọ si I, Oun ni mo gbarale nibi gbogbo alamọri mi, bẹẹ ni ọdọ rẹ ni ironu piwada mi.
وَلَوۡ أَنَّ قُرۡءَانٗا سُيِّرَتۡ بِهِ ٱلۡجِبَالُ أَوۡ قُطِّعَتۡ بِهِ ٱلۡأَرۡضُ أَوۡ كُلِّمَ بِهِ ٱلۡمَوۡتَىٰۗ بَل لِّلَّهِ ٱلۡأَمۡرُ جَمِيعًاۗ أَفَلَمۡ يَاْيَۡٔسِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَن لَّوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَهَدَى ٱلنَّاسَ جَمِيعٗاۗ وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ تُصِيبُهُم بِمَا صَنَعُواْ قَارِعَةٌ أَوۡ تَحُلُّ قَرِيبٗا مِّن دَارِهِمۡ حَتَّىٰ يَأۡتِيَ وَعۡدُ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُخۡلِفُ ٱلۡمِيعَادَ 31
Ti o ba ja si wipe ninu iroyin tira kan ninu awọn tira Ọlọhun ni ki o mu oke kuro ni aaye rẹ tabi ki o mu ile san ki awọn odo tabi isẹlẹru waa jade nibẹ tabi kaa fun oku ki wọn si di alaaye - alukuraani ti A sọkalẹ fun ọ yii ki ba jẹ -irẹ ojisẹ - awijare ti o han de, ti ilapa rẹ yoo tobi, ti wọn ba jẹ ẹni ipaya ọkan sugbọn wọn jẹ oniyan jija, bikose wipe gbogbo asẹ pata ti Ọlọhun Ọba Allah ni nibi sisọ awọn isẹ iyanu tabi ohun ti yatọ si kalẹ, se awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ko wa mọ ni wipe ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ imọna awọn eniyan lapapọ laisọ awọn amin kalẹ, ki ba fi wọn mọna lapapọ? Sugbọn ko fẹ eleyi, awọn keferi si Ọlọhun ko nii yẹ ko nii gbo ni ẹniti isẹlẹ iyẹpẹrẹ ti o le koko yoo sẹlẹ si wọn lati ara keferi wọn ati ẹsẹ wọn tabi ki iparun ti ko pẹ pupọ sọkalẹ si wọn ni inu ile wọn titi ti adehun Ọlọhun Ọba yoo fi sọkalẹ pẹlu iya ti ko nii duro, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi imusẹ ohun ti O se ni adehun Rẹ silẹ nkigbati asiko ti O fi lelẹ fun un ba to.
وَلَقَدِ ٱسۡتُهۡزِئَ بِرُسُلٖ مِّن قَبۡلِكَ فَأَمۡلَيۡتُ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ ثُمَّ أَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ عِقَابِ 32
Iwọ kii se akọkọ ojisẹ ti awọn ijọ rẹ yoo pe nirọ tabi fi se yẹyẹ, awọn ijọ kan ti se yẹyẹ siwaju tirẹ - irẹ ojisẹ - pẹlu ojisẹ wọn, wọn si pe wọn nirọ, a si lọ awọn ti nse keferi si ojisẹ wọn lara titi ti wọn fi lero wipe wọn ko nii pa awọn run lẹyin eyi mo gba wọn mu lẹyin ilọlara pẹlu oniranran iya, bawo ni o se ri iya mi si wọn si? Paapaa iya ti o le koko nii se.
أَفَمَنۡ هُوَ قَآئِمٌ عَلَىٰ كُلِّ نَفۡسِۢ بِمَا كَسَبَتۡۗ وَجَعَلُواْ لِلَّهِ شُرَكَآءَ قُلۡ سَمُّوهُمۡۚ أَمۡ تُنَبُِّٔونَهُۥ بِمَا لَا يَعۡلَمُ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَم بِظَٰهِرٖ مِّنَ ٱلۡقَوۡلِۗ بَلۡ زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ مَكۡرُهُمۡ وَصُدُّواْ عَنِ ٱلسَّبِيلِۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٖ 33
Se ẹniti o duro lori sisọ arisiki gbogbo ẹda ti o si tun nsọ gbogbo ẹmin pẹlu isẹ ti o se, ti O si san wọn lẹsan lori isẹ wọn ni O lẹtọ ki a jọsin fun ni tabi awọn oosa yii ti ko lẹtọ ki a sin? Awọn keferi ti sọ wọn di akẹgbẹ Ọlọhun niti sise abosi ati ijẹri eke, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: ẹ darukọ awọn akẹgbẹ ti ẹ njọsin fun pẹlu Ọlọhun yii fun wa ti ẹ ba jẹ olododo lori ohun ti ẹ nsọ, tabi ẹ fẹ maa fun Ọlọhun Ọba Allah niro nkan ti ko mọ lori ilẹ ni, bi awọn orogun tabi ẹ ti ẹ nfun niro ohun ti o han ninu ọrọ ti kii se ododo ni bi? Bikose wipe esu ni o se ete aburu yii lọsọ fun awọn keferi ni wọn fi se keferi si Allah, o wa mu wọn kuro ni oju ọna itọsọna ati imọna, ẹniti Allah ba mu kuro ni oju ọna imọna, olufimọna kankan ti yoo fi mọna ko si.
لَّهُمۡ عَذَابٞ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَشَقُّۖ وَمَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٖ 34
Iya nbẹ fun won ninu isẹmin aye pẹlu pipa ti yoo sẹlẹ si wọn ati mimu lẹru ti yoo sẹlẹ si wọn lati ọwọ awọn olugbagbọ ododo, bẹẹ ni iya ti ọrun eyiti o nreti wọn si le ju le wọn lori, o si tun wuwo ju iya ti aye lọ; nitori ilekoko ati itẹsiwaju ti ko nii ja lojiji, olukọdi wọn tii yoo sọ wọn kuro nibi iya ọjọ igbende ko si.
Dajudaju ipilẹ nibi gbogbo tira ti o sọkalẹ ni wipe o wa nitori imọna, kii se lati wa sisọkalẹ awọn awọn aayah, eleyi jẹ asẹ Ọlọhun Ọba ti O ga, ti O ma npebubu rẹ nigbati o ba fẹ ati bi o se fẹ.
Mimu ti Ọlọhun Ọba Allah ti O ga fi ọkan anọbi wa balẹ ati fifi mọ ọ wipe oju ọna ti awọn ẹlẹbọ ntọ pẹlu rẹ ninu oju ọna ipeni nirọ kii se titun, boyẹ nipe awọn anọbi ti o ti re kọja lọ ti dojukọ iru rẹ.
Nibi sisọ apakan awọn ẹru nu, esu ma ndebi sise ohun ti wọn nse ni ẹsẹ ati ibajẹ lọsọ fun wọn.