وَيَٰقَوۡمِ لَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مَالًاۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۚ وَمَآ أَنَا۠ بِطَارِدِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْۚ إِنَّهُم مُّلَٰقُواْ رَبِّهِمۡ وَلَٰكِنِّيٓ أَرَىٰكُمۡ قَوۡمٗا تَجۡهَلُونَ 29
Ẹyin ijọ mi, emi ko wa owo lọwọ yin lori mimu isẹ naa de opin, ẹsan mi ko jẹ lati ibi kankan ayaafi ọdọ Allah, emi ko si gbe jinna jijoko mi pẹlu awọn alaini ninu awọn olugbagbọ ododo, awọn ti ẹ nfẹ ki nle jinna, dajudaju wọn yoo pade Ọlọhun Ọba wọn ni ọjọ igbende, yoo si san wọn lẹsan lori igbagbọ wọn, sugbọn mo nri yin ni ijọ ti ko gbọ agbọye ododo ipepe yii nigbati ẹ nwa lile awọn ọlẹ ninu awọn olugbagbọ ododo jina.
وَيَٰقَوۡمِ مَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِن طَرَدتُّهُمۡۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ 30
Ẹyin ijọ mi, taani yoo ti iya Ọlọhun Ọba Allah kuro fun mi, ti mo ba le awọn olugbagbọ ododo yii kuro niti abosi laisi ẹsẹ? Abi ẹ ko woye ni, ki ẹ lọ si ibi ohun ti o dara ju fun yin, ti yoo si se anfaani?!
وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ إِنِّي مَلَكٞ وَلَآ أَقُولُ لِلَّذِينَ تَزۡدَرِيٓ أَعۡيُنُكُمۡ لَن يُؤۡتِيَهُمُ ٱللَّهُ خَيۡرًاۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا فِيٓ أَنفُسِهِمۡ إِنِّيٓ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 31
Nko sọ fun yin - ẹyin ijọ mi -: pẹpẹ ọrọ Ọlọhun Ọba Allah eyiti arisiki rẹ wa nibẹ nbẹ ni ọdọ mi, yoo na fun yin ti ẹ ba nigbagbọ, nko si ni sọ fun yin wipe mo mọ kọkọ, nko si tun ni sọ fun yin: wipe mo wa ninu awọn Malaika bikose wipe abara bii ti yin ni moo se, nko si nii sọ nipa awọn alaini ti ẹ nyẹpẹrẹ loju yin, ti ẹ si nkere wọn wipe: Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi wọn se kongẹ tabi fi wọn mọ ọna, Allah mọ adisọkan wọn ati isesi wọn, dajudaju ti mo ba pe apemọra eleyi ninu alabosi ti yoo lẹtọ si iya Allah ni mo wa.
قَالُواْ يَٰنُوحُ قَدۡ جَٰدَلۡتَنَا فَأَكۡثَرۡتَ جِدَٰلَنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 32
Wọn sọ niti isorikunkun ati isegberaga: irẹ Nuha paapaa o ti ba wa ja, o si nwo wa niran, o ba wa ja lọpọ, o si wo wa niran naa bẹẹ, yaa fun wa ni ijiya ti o se adehun fun wa ti o ba jẹ olododo nibi ohun ti ẹ npe apemọra rẹ.
قَالَ إِنَّمَا يَأۡتِيكُم بِهِ ٱللَّهُ إِن شَآءَ وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ 33
Nuha sọ fun wọn wipe: ẹmi ko nii mu iya wa ba yin, Ọlọhun Ọba Allah ni yoo wa ba yin ti o ba fẹ, ẹyin ko si ni agbara lati bọ kuro nibi iya Allah nigbati o ba gbero iya fun yin.
وَلَا يَنفَعُكُمۡ نُصۡحِيٓ إِنۡ أَرَدتُّ أَنۡ أَنصَحَ لَكُمۡ إِن كَانَ ٱللَّهُ يُرِيدُ أَن يُغۡوِيَكُمۡۚ هُوَ رَبُّكُمۡ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 34
Isiti mi ati iranileti mi ko le se yin ni anfaani ti Ọlọhun Ọba Allah ba gbero lati sọ yin nu kuro ni oju ọna tootọ, ti o si dagunla si yin kuro nibi imọna nitori ori kunkun yin, Oun ni Ọlọhun yin, Oun ni O ni ikapa ọrọ yin, O le sọ yin nu ti O ba fẹ, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o sẹri si ni ọjọ igbende, Yoo si san yin lori awọn isẹ yin.
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ إِنِ ٱفۡتَرَيۡتُهُۥ فَعَلَيَّ إِجۡرَامِي وَأَنَا۠ بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُجۡرِمُونَ 35
Okunfa kekefri ijọ Nuha ni wipe wọn di adisọkan wipe o hun ẹsin yii ti o mu wa mọ Ọlọhun Ọba Allah ni, sọ fun wọn wipe: - ire ojise - ti mo ba hun, emi nikan ni mo ni ijiya ẹsẹ mi, nko ni gbe ẹsẹ irọ ti ẹ pa kankan, mo bọri kuro nibẹ.
وَأُوحِيَ إِلَىٰ نُوحٍ أَنَّهُۥ لَن يُؤۡمِنَ مِن قَوۡمِكَ إِلَّا مَن قَدۡ ءَامَنَ فَلَا تَبۡتَئِسۡ بِمَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ 36
Ọlọhun Ọba Allah ransẹ si Nuha: pe dajudaju ko nigbagbọ ninu ijọ rẹ - irẹ Nuha - ayaafi ẹniti o ti gbagbọ siwaju, mase banujẹ - irẹ Nuha - nitori nkan ti wọn nse nisẹ gẹgẹ bi irọ pipa, ise yẹyẹ ni awọn asiko ti o gun naa.
وَٱصۡنَعِ ٱلۡفُلۡكَ بِأَعۡيُنِنَا وَوَحۡيِنَا وَلَا تُخَٰطِبۡنِي فِي ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ إِنَّهُم مُّغۡرَقُونَ 37
Se ọkọ oju omin ki a maa ri, ki a si maa daabobo o, ati lati ibi imisi Wa ki a le kọ ọ bi iwọ yoo se se, mase bami sọrọ lati lọ awọn ti wọn se abosi ẹmin ara wọn nibi keferi sise lara, dajudaju ẹni itẹri ni wọn - ko si ibuyẹ - sinu okun Tufanu; ni ijiya fun wọn lori titako lori keferi.
Nini amojukuro olupepe si oju ọna Allah ati wipe o nrankan si ẹsan lọdọ Ọlọhun Ọba nikan.
Jijẹ eewọ lile awọn alaini olugbagbọ ododo jinna ati didi dandan sise apọnle wọn ati bibọwọ fun wọn.
Jijẹ aaso Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga nikan soso nibi imọ kọkọ.
Sise lofin jija awọn keferi niyan ati wiwo wọn niran.