بَلۡ بَدَا لَهُم مَّا كَانُواْ يُخۡفُونَ مِن قَبۡلُۖ وَلَوۡ رُدُّواْ لَعَادُواْ لِمَا نُهُواْ عَنۡهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ 28
ọrọ ko ri bi wọn se nsọ lori wipe ti wọn ba da awọn pada awọn yoo ni igbagbọ, bikose wipe o han si wọn nkan ti wọn fi pamọ ninu ọrọ: وَٱللَّهِ رَبِّنَا مَا (كُن)َّا مُشۡرِكِينَ (a fi Ọlọhun Ọba bura, a kii se ẹlẹbọ) , nigbati awọn orikerike wọn njẹri le wọn lori, ti wọn ba ti ẹ kọ silẹ wipe ki wọn pada si ile aye, wọn yoo tun pada si ibi ohun ti wọn kọ fun wọn ni, bii keferi sise ati ẹbọ, dajudaju opurọ ni wọn nibi sise adehun igbagbọ nigbati wọn ba pada.
وَقَالُوٓاْ إِنۡ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنۡيَا وَمَا نَحۡنُ بِمَبۡعُوثِينَ 29
Awọn ọlọsẹbọ yii nsọ wipe: ko si isẹmin kankan ju eyiti a se yii lọ, wọn ko si nii gbe wa dide fun isiro isẹ.
وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ وُقِفُواْ عَلَىٰ رَبِّهِمۡۚ قَالَ أَلَيۡسَ هَٰذَا بِٱلۡحَقِّۚ قَالُواْ بَلَىٰ وَرَبِّنَاۚ قَالَ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ 30
Ti o ba ri - ire ojise -nigbati wọn ba da awọn ti wọn tako igbedide duro niwaju Ọlọhun Ọba wọn, iwọ yoo ri eemọ nibi aburu isesi wọn, nigbati Ọlọhun Ọba Allah ba sọ fun wọn: se kii se igbedide eyiti ẹ npe ni irọ ni yii, ododo ni ti o fi ẹsẹ rinlẹ ti ko si iyemeji nibẹ? ! Wọn yoo sọ wipe: a fi Ọlọhun Ọba wa bura ti o da wa, ododo ti o daju ni, ko si iyemeji nibẹ, Ọlọhun Ọba Allah yoo wa sọ fun ni igba yii: ẹ maa tọ iya wo eyiti ẹ ni ẹtọ si nitori keferi yin ti ẹ jẹ yii; ẹ ti pe e nirọ nigbati ẹ wa ni isẹmin aye.
قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِلِقَآءِ ٱللَّهِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَتۡهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةٗ قَالُواْ يَٰحَسۡرَتَنَا عَلَىٰ مَا فَرَّطۡنَا فِيهَا وَهُمۡ يَحۡمِلُونَ أَوۡزَارَهُمۡ عَلَىٰ ظُهُورِهِمۡۚ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ 31
Awọn ti npe ọjọ igbende nnirọ ti sofo, wọn si nwa ọna lati ma duro siwaju Ọlọhun Ọba Allah, titi ti igbende yoo fi ba wọn lojiji, ti wọn ko si nii ni imọ tẹlẹ, wọn yoo ma sọrọ niti ikabamọ ti o gbọnna: ofo wa o, ipadanu erongba wa o nitori aise koto nipa ti Ọlọhun Ọba Allah lori sise keferi si I, ati aimura silẹ de ọjọ igbende, wọn yoo gbe ẹsẹ wọn ru si ẹyin wọn, o ma se o, aida ti wọn ngbe ru yii.
وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا لَعِبٞ وَلَهۡوٞۖ وَلَلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يَتَّقُونَۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 32
Isẹmi aye eyiti ara ti sibẹ yii ko jẹ nkankan ju ere ati itanjẹ lọ fun ẹniti ko se ohun ti o yọ Ọlọhun Ọba Allah nimu, sugbọn ile ti ọrun, ohun ni o loore ju fun awọn ti wọn paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu sise nkan ti wọn pa wọn lasẹ rẹ, bii igbagbọ ati atẹle asẹ, ati gbigbe nkan ti wọn kọ fun ju silẹ, bii ẹbọ ati ẹsẹ, se ẹ ko se laakaye ni - ẹyin ọsẹbọ -? !
قَدۡ نَعۡلَمُ إِنَّهُۥ لَيَحۡزُنُكَ ٱلَّذِي يَقُولُونَۖ فَإِنَّهُمۡ لَا يُكَذِّبُونَكَ وَلَٰكِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ 33
Awa mọ pe - ire ojise - iwọ banujẹ lori pipe ọ nirọ ni gbangba, lọ mọ wipe wọn ko pe ọ nirọ ninu ẹmin wọn; nitori wipe wọn mọ ododo rẹ ati ifọkantan rẹ, sugbọn wọn jẹ alabosi, wọn ntako asẹ rẹ ni gbangba, sugbọn o da wọn loju ninu ẹmin wọn.
وَلَقَدۡ كُذِّبَتۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَ فَصَبَرُواْ عَلَىٰ مَا كُذِّبُواْ وَأُوذُواْ حَتَّىٰٓ أَتَىٰهُمۡ نَصۡرُنَاۚ وَلَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَٰتِ ٱللَّهِۚ وَلَقَدۡ جَآءَكَ مِن نَّبَإِيْ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 34
Ma lero wipe ipenirọ yii nkan ti o mu wa nikan ni, wọn ti pe awọn ojisẹ nirọ siwaju ti rẹ, awọn ijọ wọn se wọn ni suta, sugbọn wọn fi suuru pade rẹ, lori ipepe ati igbiyanju si oju ọna ti Ọlọhun Ọba Allah, titi ti aranse fi waa ba wọn lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, oluyi aranse ti Ọlọhun Ọba Allah ti kọ pada ko si, tabi adehun ti O ti se fun awọn ojisẹ Rẹ, paapaa o ti waa ba ọ - ire ojise - iro awọn ti o ti siwaju rẹ ninu awọn ojisẹ ati ohun ti wọn ba pade ni ọdọ awọn ijọ wọn, ati ohun ti Ọlọhun Ọba Allah fi ta wọn lọrẹ ninu aranse lori awọn ọta wọn pẹlu pipa wọn run.
وَإِن كَانَ كَبُرَ عَلَيۡكَ إِعۡرَاضُهُمۡ فَإِنِ ٱسۡتَطَعۡتَ أَن تَبۡتَغِيَ نَفَقٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ أَوۡ سُلَّمٗا فِي ٱلسَّمَآءِ فَتَأۡتِيَهُم بَِٔايَةٖۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَمَعَهُمۡ عَلَى ٱلۡهُدَىٰۚ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ 35
Ti o ba le lara rẹ - ire ojise - nkan ti o nba pade ni ọdọ wọn lori pipe ọ nirọ ati gigun wọn kuro nibi ohun ti o gbe wa ba wọn ni ododo, ti o ba ni agbara lati le ba wa ọna ni ori rẹ, tabi akasọ lọ si oke sanmọ, ki o le mu ẹri ati awijare wa yatọ si ohun ti a fi kun ọ lọwọ yii, ki o ya se bẹẹ, ti Ọlọhun Ọba Allah ba gbero lati pa wọn ; pọ lori imọna ti o gbe wa ni, ki ba pa wọn pọ, sugbọn ko gbero eleyi nitori ọgbọn kan ti o de ogongo, mase wa ninu awọn alaimọkan si eyi, ki ẹmin rẹ ma baa mọ daamu lori wipe wọn ko ni igbagbọ.
Ninu deedee Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga ni ki O ko olujọsin ati ẹniti a nsin, olutẹle ati ẹniti a ntẹle papọ ni gbangba alukiyaamọ, ki apakan wọn le jẹri lori apakan.
Kii se gbogbo ẹniti ngbọ alukuraani ni yoo se anfaani nibẹ, o seese ki gaga kan bi ebibo ọkan, tabi edidi eti kọ dii lati ma se anfaani nibẹ.
Alaye wipe dajudaju awon osebo bi o tile jewipe won npa iro ni ifojuhan, won mo daju ninu ara won pelu jije ododo anabi (ki ike ati ola ma ba) .
Itutu ẹmin Anọbi ati kikun lọwọ lati le jẹ ki o mọ wipe ipenirọ yii kii se fun ohun nikan, o jẹ ojupọnna awọn ẹlẹbọ nibi ibasepọ wọn si awọn ojisẹ ti o ti re kọja.