فَإِن لَّمۡ تَجِدُواْ فِيهَآ أَحَدٗا فَلَا تَدۡخُلُوهَا حَتَّىٰ يُؤۡذَنَ لَكُمۡۖ وَإِن قِيلَ لَكُمُ ٱرۡجِعُواْ فَٱرۡجِعُواْۖ هُوَ أَزۡكَىٰ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ عَلِيمٞ 28
Ti ẹ ko ba ri ẹnikankan ninu awọn ile naa, ẹ ko gbọdọ wọ ibẹ titi wọn yoo fi yọnda fun yin lati wọ ọ lati ọdọ ẹniti o ni ikapa iyọnda, ti awọn ti o ni ile naa ba sọ fun yin wipe: (ẹ pada) ki ẹ yaa pada, ki ẹ si maa wọ ibẹ, dajudaju eleyi yoo fọ yin mọ ni ọdọ Allah, Allah jẹ onimimọ nipa ohun ti ẹ nse, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
لَّيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَدۡخُلُواْ بُيُوتًا غَيۡرَ مَسۡكُونَةٖ فِيهَا مَتَٰعٞ لَّكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا تَكۡتُمُونَ 29
Ko si laifi fun yin ki ẹ wọ ile kan laigba iyọnda, ile ti o kari, ti ẹnikankan ko ni i, ti wọn pese rẹ lati jẹ anfaani fun ọpọ eeyan; gẹgẹ bi awọn ilee isẹ ati awọn ibusọ ninu awọn ọja, bẹẹni Ọlọhun Allah mọ ohun ti ẹ se afihan ninu awọn isẹ yin ati awọn isesi yin ati ohun ti ẹ nfi pamọ, nkankan ko pamọ fun Un ninu rẹ, yoo si san yin lẹsan le lori.
Nigbati wiwo jẹ ifiransẹ lọsi ibi igbere, Allah pasẹ rirẹ oju nilẹ fun idaabobo lati ọdọ Rẹ, O si sọpe:
قُل لِّلۡمُؤۡمِنِينَ يَغُضُّواْ مِنۡ أَبۡصَٰرِهِمۡ وَيَحۡفَظُواْ فُرُوجَهُمۡۚ ذَٰلِكَ أَزۡكَىٰ لَهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرُۢ بِمَا يَصۡنَعُونَ 30
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn olugbagbọ ododo ki wọn ko oju wọn ro kuro nibi wiwo ounti ko tọ si wọn ninu awọn obinrin ati awọn ihoho, ki wọn si sọ awọn abẹ wọn kuro nibi bibọsi inu eewọ, ẹniti o ba si ikoraro yii kuro nibi wiwo ounti Allah se ni eewọ, ti o si so abe, ohun ni ounti o mọ ju fun un ni ọdọ Allah, dajudaju Allah jẹ olufunniro ounti wọn se, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
وَقُل لِّلۡمُؤۡمِنَٰتِ يَغۡضُضۡنَ مِنۡ أَبۡصَٰرِهِنَّ وَيَحۡفَظۡنَ فُرُوجَهُنَّ وَلَا يُبۡدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا مَا ظَهَرَ مِنۡهَاۖ وَلۡيَضۡرِبۡنَ بِخُمُرِهِنَّ عَلَىٰ جُيُوبِهِنَّۖ وَلَا يُبۡدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا لِبُعُولَتِهِنَّ أَوۡ ءَابَآئِهِنَّ أَوۡ ءَابَآءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوۡ أَبۡنَآئِهِنَّ أَوۡ أَبۡنَآءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوۡ إِخۡوَٰنِهِنَّ أَوۡ بَنِيٓ إِخۡوَٰنِهِنَّ أَوۡ بَنِيٓ أَخَوَٰتِهِنَّ أَوۡ نِسَآئِهِنَّ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُنَّ أَوِ ٱلتَّٰبِعِينَ غَيۡرِ أُوْلِي ٱلۡإِرۡبَةِ مِنَ ٱلرِّجَالِ أَوِ ٱلطِّفۡلِ ٱلَّذِينَ لَمۡ يَظۡهَرُواْ عَلَىٰ عَوۡرَٰتِ ٱلنِّسَآءِۖ وَلَا يَضۡرِبۡنَ بِأَرۡجُلِهِنَّ لِيُعۡلَمَ مَا يُخۡفِينَ مِن زِينَتِهِنَّۚ وَتُوبُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ جَمِيعًا أَيُّهَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 31
Ki o si sọ fun awọn olugbagbọ ododo lobinrin ki wọn ko oju wọn ro kuro nibi wiwo nkan ti ko tọ ọ fun un lati wo ninu nkan eewọ, ki wọn si sọ abẹ wọn pẹlu jinnna si ibajẹ ati bibo ihoho, ki wọn si mase fi ọsọ wọn han fun awọn ajoji ayaafi eyi ti o ba han nibẹ ninu ohun ti ko rọrun fifi pamọ gẹgẹbi asọ, ki wọn si fi ibori wọn bo awọn ọrun asọ wọn ki o le ba bo irun ori wọn ati awọn oju wọn ati awọn ọrun wọn, wọn ko si gbọdọ fi ọsọ wọn ti o fuyẹ han ayaafi fun awọn ọkọ wọn tabi awọn baba wọn tabi awọn baba iyawo wọn tabi awọn ọmọ wọn tabi awọn ọmọ iyawo wọn tabi awọn iya wọn lọkunrin tabi awọn ọmọ ọmọ iya lọkunrin tabi awọn ọmọ ọmọ iya wọn lobinrin tabi awọn obinrin wọn ninu ẹniti wọn fi ọkan balẹ si lọdọ, ti o jẹ olugbafa lobinrin tabi awọn oluse keferi lobinrin tabi eyiti wọn nikapa ninu awọn ẹru boya akọ ni wọn ni tabi abo tabi awọn ti wọn ntẹle wọn, ti wọn ko ni ironu kankan nipa awọn obinrin tabi awọn ọmọ keekeeke ti wọn ko ti maa naga wo ihoho awọn obinrin nitori kikere wọn, awọn obinrin ko gbọdọ maa fi ẹsẹ wọn lu ara wọn nitori erongba ki wọn le mọ ohun ti wọn fi pamọ lọsọ gẹgẹ bi nkan ọrun tabi ohun ti o jọ ọ, ki ẹ sẹri pada si ọdọ Allah ni apapọ -ẹyin olugbagbọ ododo ninu yiyọju ati ohun ti o yatọ si i; ni ireti ki ẹ le baa jere pẹlu ohun ti ẹ nwa, ki ẹ si la pẹlu ohun ti ẹ nbẹru.
Titọ wiwọ awọn aaye ọpọ eeyan laini iyọnda ninu.
Jijẹ dandan rirẹ oju nilẹ fun ọkunrin ati obinrin kuro nibi ohun ti ko lẹtọ fun wọn.
Jijẹ dandan ẹha fun obinrin.
Kikọ lilo awọn ọna to le mu ara ya.