فَإِذَا ٱسۡتَوَيۡتَ أَنتَ وَمَن مَّعَكَ عَلَى ٱلۡفُلۡكِ فَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي نَجَّىٰنَا مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ 28
Ti o ba wa ni ori ọkọ oju omin, iwọ ati ẹniti o ba wa pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo yoo la ki o sọ wipe: ọpẹ ni fun Allah eyiti O la wa ninu awọn ijọ keferi, ki o pa wọn run.
وَقُل رَّبِّ أَنزِلۡنِي مُنزَلٗا مُّبَارَكٗا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡمُنزِلِينَ 29
Ki o si sọ pe: Ọlọhun mi, sọ mi kalẹ ni ori ilẹ ni isọkalẹ ibukun toripe Iwọ ni O loore ju ninu awọn olusọni kalẹ.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ وَإِن كُنَّا لَمُبۡتَلِينَ 30
Dajudaju nibi eleyi ti A sọ yii nipa lila Nuha ati awọn olugbagbọ ododo pẹlu rẹ ati kiko iparun ba awọn keferi; jẹ awọn itọka ti o gbọngbọn lori agbara Wa nipa riran awọn ojisẹ Wa se ati pipa awọn olupe wọn nirọ run, bikosepe awa jẹ olugbidanwo fun ijọ Nuha pẹlu riran an si wọn ki olugbagbọ le hande kuro ninu keferi ati olutẹle kuro ninu ẹlẹsẹ.
ثُمَّ أَنشَأۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِمۡ قَرۡنًا ءَاخَرِينَ 31
Lẹyin naa A mu ijọ miran jade lẹyin igbati a ti pa ijọ Nuha run.
فَأَرۡسَلۡنَا فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡهُمۡ أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۚ أَفَلَا تَتَّقُونَ 32
A si gbe ojisẹ dide ninu wọn ti npe wọn lọ si ọdọ Allah, o si sọ fun wọn: ẹ maa sin Allah ni ọkan soso, ko si olujọsin fun tootọ kankan fun yatọ si Oun ti mimọ nbẹ fun, se ẹ ko nii paya Allah ni pẹlu jijinna si ohun ti O kọ ati imusẹ awọn nkan ti o pasẹ rẹ?!
وَقَالَ ٱلۡمَلَأُ مِن قَوۡمِهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِلِقَآءِ ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَتۡرَفۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا مَا هَٰذَآ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يَأۡكُلُ مِمَّا تَأۡكُلُونَ مِنۡهُ وَيَشۡرَبُ مِمَّا تَشۡرَبُونَ 33
Awọn ẹni iyi ati awọn ẹni isiwaju ninu ijọ rẹ, awọn ti wọn se keferi si Allah, ti wọn si pe ọjọ ikẹyin nirọ ati ohun ti o nbẹ ninu rẹ ẹsan ati iya ati ẹniti o kọja ẹnu aala ju ninu wọn lori idẹkun ti A gba wọn laaye ninu idẹkun ni isẹmin aye sọ wipe, wọn sọ fun awọn olutẹle wọn ati akorijọpọ wọn -: kinni eleyi jẹ bi kii ba se abara bi ti yin, ti o njẹ ninu ohun ti ẹ njẹ, ti o si nmu ninu ohun ti ẹ nmu, ko ni ẹsa kankan le yin lori ti wọn yoo fi waa gbe dide lojisẹ si yin.
وَلَئِنۡ أَطَعۡتُم بَشَرٗا مِّثۡلَكُمۡ إِنَّكُمۡ إِذٗا لَّخَٰسِرُونَ 34
Ti ẹ ba le maa tẹle abara bi ti yin, o fi han wipe dajudaju ẹ ti ẹni ofo nitori ẹ ko le se anfaani pẹlu titẹ le e, ti ẹ ba ti gbe awọn ọlọhun yin ju silẹ, o tun jẹ itẹle ẹniti ko ni ọla le yin lori.
أَيَعِدُكُمۡ أَنَّكُمۡ إِذَا مِتُّمۡ وَكُنتُمۡ تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَنَّكُم مُّخۡرَجُونَ 35
Se ẹniti o npinnu wipe ojisẹ ni oun se adehun fun yin ni wipe ti ẹ ba ku, ti ẹ si ti di yẹpẹ ati eegun ti o ti kẹfun wipe ẹyin yoo jade ninu saare yin ni alaaye?! Se eleyi ni laakaye?!
۞هَيۡهَاتَ هَيۡهَاتَ لِمَا تُوعَدُونَ 36
O jinna tefetefe ohun ti o se ni adehun rẹ yii gẹgẹ bi mimu yin jade ni alaaye ninu saare yin lẹyin iku yin, ibusẹri si yin si jẹ yeepẹ ati eegun ti o ti kẹfun.
إِنۡ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنۡيَا نَمُوتُ وَنَحۡيَا وَمَا نَحۡنُ بِمَبۡعُوثِينَ 37
Ko si isẹmin kankan ju isẹmin aye lọ, ko si isẹmin ọrun, awọn alaaye yoo ku ninu wa ko si ni sẹmin, wọn bi awọn miran ti wọn yoo si tun sẹmin, wọn ko si ni mu wọn jade lẹyin iku wa fun isiro ni ọjọ igbende.
إِنۡ هُوَ إِلَّا رَجُلٌ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا وَمَا نَحۡنُ لَهُۥ بِمُؤۡمِنِينَ 38
Kinni eleyi ti o npe ara rẹ ni ojisẹ fun yin jẹ bi kii ba se ọkunrin kan ti o nhun irọ mọ Allah, awa kii se ẹniti yoo nigbagbọ si i.
قَالَ رَبِّ ٱنصُرۡنِي بِمَا كَذَّبُونِ 39
Ojisẹ naa sọpe: Ọlọhun mi, ran mi se le wọn lori pẹlu ki O ba mi gba ẹsan lara wọn pẹlu pipe mi nirọ.
قَالَ عَمَّا قَلِيلٖ لَّيُصۡبِحُنَّ نَٰدِمِينَ 40
Ọlọhun rẹ si jẹpe rẹ ni ẹniti o nsọ bayi pe: lẹyin asiko diẹ awọn olupe ohun ti o mu wa nirọ yii yoo pada di alabamọ lori ohun ti o sẹlẹ si wọn nipa irọ pipa.
فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ بِٱلۡحَقِّ فَجَعَلۡنَٰهُمۡ غُثَآءٗۚ فَبُعۡدٗا لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ 41
Ohun iparun ti o le koko si gba wọn mu nitori igberaga ti o jẹ ki wọn lẹtọ si iya naa, o si sọ wọn di ẹni iparun gẹgẹ bi rọtirọti agbara, iparun ki o maa bẹ fun awọn ijọ alabosi.
ثُمَّ أَنشَأۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِمۡ قُرُونًا ءَاخَرِينَ 42
A gbe awọn ijọ kan dide ati awọn awọn ijọ ijọ miran gẹgẹ bi ijọ Luth, ijọ Shuaibu ati ijọ Yuunus.
Jijẹ dandan didupẹ fun Allah lori idẹkun.
Yiyayọpọrọ ni ile aye wa ninu okunfa ifọnu ati igunri kuro nibi ododo.
Igbẹyin kefei jẹ abamọ ati ofo.
Abosi jẹ okunfa nibi jinna si ikẹ Allah.