وَإِمَّا تُعۡرِضَنَّ عَنۡهُمُ ٱبۡتِغَآءَ رَحۡمَةٖ مِّن رَّبِّكَ تَرۡجُوهَا فَقُل لَّهُمۡ قَوۡلٗا مَّيۡسُورٗا 28
Ti o ba kọ lati fun awọn eniyan wọnyi; nitori airi nkan ti iwọ yoo fun wọn, ni ẹniti nreti ohun ti Allah Yoo si fun ọ ninu arisiki, ki o yaa sọ gbolohun ti o lẹ, ti o si rọrun fun wọn gẹgẹ bi ki o se adua igbaaye arisiki fun wọn tabi ki o se adehun lati fun wọn ti Ọlọhun Ọba ba rọ ọ lọrọ arisiki.
وَلَا تَجۡعَلۡ يَدَكَ مَغۡلُولَةً إِلَىٰ عُنُقِكَ وَلَا تَبۡسُطۡهَا كُلَّ ٱلۡبَسۡطِ فَتَقۡعُدَ مَلُومٗا مَّحۡسُورًا 29
Mase ko owo rẹ ro nibi inawo, ma si na ina apa ki o maa baa di ẹni eebu lori ijẹ ahun rẹ nigbati o ba ko ọwọ rẹ ro nibi inawo, bẹẹni ki o ma jawọ kuro nibi inawo nitori ina apa rẹ nigbati o ko ba ri ohun ti iwọ yoo na.
إِنَّ رَبَّكَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرٗا 30
Dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ ma ngbaaye arisiki fun ẹniti o ba wu U, O si ma nfunlẹ arisiki mọ ẹniti o ba wu U nitori ọgbọn kan ti o ga, dajudaju Oun jẹ Olufunni niro ati Oluriran si ẹru Rẹ, nkankan ninu wọn ko pamọ fun Un, O ma npasẹ rẹ laarin bi o ti fẹ.
وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ خَشۡيَةَ إِمۡلَٰقٖۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُهُمۡ وَإِيَّاكُمۡۚ إِنَّ قَتۡلَهُمۡ كَانَ خِطۡٔٗا كَبِيرٗا 31
Ẹ mase maa pa ọmọ yin nitori ipaya kuro nibi osi nitori ọjọ ọla igbati ẹ ba nawo le wọn lori, awa ni a nla arisiki wọn bẹẹni awa ni a nla arisiki ti yin gan gan bọrun, dajudaju pipa wọn jẹ ẹsẹ ti o tobi; nigbati o ja si wipe ko si ẹsẹ fun wọn, ko si si idi kankan ti o sọ pipa wọn di dandan.
وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلزِّنَىٰٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةٗ وَسَآءَ سَبِيلٗا 32
Ẹ sọra fun agbere, ki ẹ si jinna si ohun ti yoo se yin lakin lati le se e, dajudaju o jẹ ibiti aburu pin si, o si jẹ ọna ti o buru nitori idapọ mọlẹbi ti yoo ti ẹyin rẹ jade ati iya Allah.
وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَمَن قُتِلَ مَظۡلُومٗا فَقَدۡ جَعَلۡنَا لِوَلِيِّهِۦ سُلۡطَٰنٗا فَلَا يُسۡرِف فِّي ٱلۡقَتۡلِۖ إِنَّهُۥ كَانَ مَنصُورٗا 33
Ki ẹ si mase pa ẹmin ti Allah da aabo bo ẹjẹ rẹ nitori igbagbọ tabi ifọkanbalẹ ayafi ti o ba lẹtọ si pipa nitori sisẹri kuro ninu ẹsin tabi agbere lẹyin mimọ kanga tabi gbigba ẹsan ipaniyan, ẹniti wọn ba pa niti abosi, ti ko si idi ti o fi lẹtọ si pipa, paapaa a ti se jijẹ gaba lori ẹniti o pa a fun ẹniti alamọri rẹ ba wa lọrun rẹ ninu awọn ti yoo jẹ ogun rẹ, o lẹtọ lati beere fun pipa a niti gbigba ẹsan, o si tun lẹtọ ki o se amujukuro laini gba nkankan dipo, bẹẹ ni o tun lẹtọ lati se amojukuro ki o si tun gba owo itanran ẹmin, ko gbọdọ kọja ẹnu aala eyiti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ fun un nibi gbigba ẹsan lara ẹniti o pa a, tabi ki o pa a pẹlu ohun ti o yatọ si ohun ti wọn fi pa a, tabi ki o pa ẹniti o yatọ si ẹniti o pa a, dajudaju ẹniti a kun lọwọ, ti a si se aanu fun.
وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ بِٱلۡعَهۡدِۖ إِنَّ ٱلۡعَهۡدَ كَانَ مَسُۡٔولٗا 34
Ẹ mase bi o se wu yin nibi dukia ẹniti baba rẹ ku ninu awọn ọmọ kekeeke ayaafi ohun ti yoo se ni anfaani ninu ohun ti o le mu idagbasoke ba a, tabi daabobo titi yoo fi depo pipe ni laakaye ati ọgbọn, ẹ pe ohun ti o wa laarin yin ati Allah ati ohujn ti o wa laarin yin ati awọn ẹru Rẹ ninu adehun laisi jija atabi dindin in ku, dajudaju Allah yoo beere olufuni ni adehun ni ọjọ igbende, njẹ o pe e ni, ki wọn le san lẹsan, tabi ko pe ki wọn le jẹ niya.
وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ إِذَا كِلۡتُمۡ وَزِنُواْ بِٱلۡقِسۡطَاسِ ٱلۡمُسۡتَقِيمِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ وَأَحۡسَنُ تَأۡوِيلٗا 35
Ẹ pe osunwọn nigbati ẹ ba nwọn fun ẹnikeji yin, ki ẹ si ma din ku, ki ẹ si wọn odiwọn pẹlu deede eyiti ko nii din nkankan ku tabi yinjẹ, eleyi ni pipe odiwọn ati osunwọn ti o leere ju fun yin ni aye ati lọrun, ati igbẹyin ti o dara ju dindin awọn osunwọn ku ati awọn odiwọn.
وَلَا تَقۡفُ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۚ إِنَّ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡبَصَرَ وَٱلۡفُؤَادَ كُلُّ أُوْلَٰٓئِكَ كَانَ عَنۡهُ مَسُۡٔولٗا 36
Mase tẹle - irẹ ọmọ Aadamọ- ohun ti ko si imọ fun ọ nibẹ, ti iwọ yoo wa maa tẹle erongba tabi ohun ti o ru wuyẹ lọkan, dajudaju ọmọ ẹda eniyan jẹ ẹniti a o bi leere nipa bi o se lo igbọran rẹ ati iriran rẹ ati ọkan rẹ boya daadaa ni tabi aburu, wọn yoo si san lẹsan lori rere, bẹẹni wọn yoo jẹ niya lori aburu.
وَلَا تَمۡشِ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَحًاۖ إِنَّكَ لَن تَخۡرِقَ ٱلۡأَرۡضَ وَلَن تَبۡلُغَ ٱلۡجِبَالَ طُولٗا 37
Mase rin lori ilẹ niti igberaga ati iyanran, dajudaju ti o ba nrin ori rẹ niti igberaga, irin rẹ ko le mu ilẹ san, bẹẹni inaro rẹ ko le de ibiti oke de niti gigun ati giga, ori ki waa ni igberaga rẹ da naa?!
كُلُّ ذَٰلِكَ كَانَ سَيِّئُهُۥ عِندَ رَبِّكَ مَكۡرُوهٗا 38
Gbogbo ohun ti irannileti rẹ re kọja, dajudaju aburu rẹ lọdọ Ọlọhun Ọba rẹ -irẹ ọmọ ẹda eniyan - jẹ ohun ti a kọ, Ọlọhun Ọba Allah ko nii yọnu si ẹniti o ba se e, bikosepe yoo korira rẹ.
Ẹkọ ti o ga ni fifesi pada fun awọn alasunmọ pẹlu aanu ati sise adehun fun niti adehun daadaa pẹlu dida wọn pọ nigba idẹkun ati wiwa awijare fun wọn pẹlu nkan ti o le jẹ itẹwọgba.
Ọlọhun Allah jẹ Ẹniti O le kẹ awọn ọmọ ju awọn wọn lọ; O wa kọ fun awọn obi mejeeji ki wọn pa awọn ọmọ wọn nitori ipaya osi ati aini, O si la arisiki gbogbo wọn bọrun.
Ẹri wa ninu awọn aayah naa wipe ẹniti o lẹtọ lati pani jẹ olowo ẹni, a ko gbọdọ gba ẹsan ayafi pẹlu iyọnda Rẹ, ti O ba se amojukuro igbẹsan ti jabọ.
Ninu aanu Allah ati ikẹ si ọmọ orukan ni pipa asẹ rẹ fun awọn alamojuto rẹ ki wọn sọ ọ, ki wọn si sọ dukia rẹ ati ki wọn se atunse rẹ, ki wọn si mu gbero titi yoo gbọn.