Nigbati O se iseni lojukokoro (ti ọla Rẹ ga) sibi nina owo si oju ọna Rẹ nitori ohun ti o nbẹ nibẹ ninu riran ara ọni lọwọ ati aanu sise laarin awọn Musulumi, O waa kilọ nibi ohun ti o le tako nkan naa, ohun naa ni owo ele, ni O wa sọ wipe:
ٱلَّذِينَ يَأۡكُلُونَ ٱلرِّبَوٰاْ لَا يَقُومُونَ إِلَّا كَمَا يَقُومُ ٱلَّذِي يَتَخَبَّطُهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ مِنَ ٱلۡمَسِّۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡبَيۡعُ مِثۡلُ ٱلرِّبَوٰاْۗ وَأَحَلَّ ٱللَّهُ ٱلۡبَيۡعَ وَحَرَّمَ ٱلرِّبَوٰاْۚ فَمَن جَآءَهُۥ مَوۡعِظَةٞ مِّن رَّبِّهِۦ فَٱنتَهَىٰ فَلَهُۥ مَا سَلَفَ وَأَمۡرُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۖ وَمَنۡ عَادَ فَأُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 275
Awọn ti wọn nfi riba se isẹ se, ti wọn si ngba, wọn ko ni dide ni Ọjọ Igbende lati awọn saare wọn ayaafi gẹgẹ bi ẹniti esu fi ọwọ ba se ma ndide, yoo waa dide ninu saare rẹ, ti yoo ma ti ẹsẹ bọ ẹsẹ, gẹgẹ bi ẹniti ko mọ oun ti o nse se ma nti ẹsẹ bọ ẹsẹ ati isubu rẹ; iyen nipe pẹlu idi wipe wọn se jije riba ni ẹtọ, wọn ko si se iyatọ laarin riba ati laarin oun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ, nibi awọn ikowojọ olowo, wọn wa sọ wipe: dajudaju karakata da gẹgẹ bi owo ele nibi jijẹ ẹtọ, olukuluku wọn ma nse okunfa lilekun owo, ati gbigberu rẹ, Ọlọhun Ọba Allah waa da ọrọ pada si wọn, O si ba fifi nkan we nkan jẹ, O si tun pe wọn ni onirọ, O wa salaye wipe dajudaju Ohun (ti ọla Rẹ ga) se karakata ni ẹtọ, nitori ohun ti o nbẹ nibẹ ninu anfaani ti o kari, ati eyiti o jẹ ẹsa, ati wipe o si se riba ni eewọ nitori ohun ti o nbẹ nibẹ ninu abosi, ati jijẹ owo awọn eniyan pẹlu ailẹtọ laini pasipaarọ, ẹniti isiti ba waa ba lati odọ Ọlọhun Ọba rẹ, ti o nbẹ nibẹ kikọ ati sise ikilọ fun ni kuro nibi owo ele, ti o waa kuro nibẹ, ti o si tun waa ronu piwada lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah kuro nibẹ; oun ti o ti lọ nbẹ fun un ninu gbigba ti o gba owo ele, ko si ẹsẹ kankan fun un nibẹ, alamọri rẹ si di ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nibi ohun ti o dojukọ lẹyin nkan naa, ẹniti o ba waa pada lọsi ibi mima gba owo ele, lẹyin igbati kiko ti de si etigbọ rẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ti awijare si ti duro le lori, iru ẹni bẹẹ ti ni ẹtọ si ki o wọ ina, ati mima bẹ nibẹ lọ gbere. Ati wipe mima bẹ ninu ina lọ gbere yii, ohun ti wọn gba lero pẹlu rẹ ni, wiwa nibẹ fun igba ti o gun, toripe mima bẹ ninu ina gbere eyiti yoo maa bẹ bẹẹ, ko ni wa fun ẹnikankan ju awọn alaigbagbọ lọ, ẹ ko ri awọn ti wọn ba jẹ olumọ Ọlọhun Ọba lọkan soso, wọn ko nii maa bẹ nibẹ lọ gbere.
Lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah darukọ mima nawo si oju ọna Rẹ, ati mima gba owo ele, O waa se alaye iyatọ ti nbẹ laarin awọn mejeeji nibi ẹsan, ti O fi waa sọ wipe:
يَمۡحَقُ ٱللَّهُ ٱلرِّبَوٰاْ وَيُرۡبِي ٱلصَّدَقَٰتِۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيمٍ 276
Ọlọhun Ọba Allah yoo pa owo elele run, Yoo si mu lọ, ninu ko jẹ ohun ti a ri pẹlu wipe ki o tan, tabi ohun ti o jọ nkan naa, tabi ohun ti a ko ri pẹlu fifa alubarika kuro nibẹ ati wipe Yoo maa se alekun awọn saara, Yoo si ma jẹ ki o gberu pẹlu sise adipele ẹsan rẹ, daadaa sise kan pẹlu ẹsan mẹwa iru rẹ rẹ ni lọsi bii ọgọrun meje adipele, lọsi awọn adipele ti o pọ, Yoo si tun maa fi ibukun sinu awọn owo awọn ti wọn nse saara, Ọlọhun Ọba Allah kii nifẹ gbogbo ẹniti o ba jẹ alaigbagbọ olorikunkun, ti o nse eewọ ni ẹtọ, ti o si nlọ ninu awọn iyapa ati awọn ẹsẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 277
Dajudaju awọn ti wọn gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ti wọn si se awọn isẹ ti o dara, ti wọn si mu irun wa ni pipe lori bi Ọlọhun Ọba se se ni ofin, ti wọn si yọ saka awọn dukia wọn fun awọn ti wọn ni ẹtọ sii, ẹsan wọn nbẹ fun wọn ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ati wipe ko si ibẹru fun wọn nibi ohun ti wọn dojukọ ninu awọn alamọri wọn, ati wipe awọn ko nii ma ba inu jẹ lori ohun ti o bọ fun wọn ni ile aye ati idẹra rẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَذَرُواْ مَا بَقِيَ مِنَ ٱلرِّبَوٰٓاْ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 278
Mo pe ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si tun ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ bẹru Ọlọhun Ọba Allah pẹlu wipe ki ẹ maa mu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ, ki ẹ si jinna si awọn ohun ti O kọ, ki ẹ si fi mima wa gbigba ohun ti o ku fun yin ninu awọn owo elele ni ọdọ awọn eniyan silẹ, ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo ni tootọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati pẹlu ohun ti O kọ fun yin nibẹ ninu owo ele.
فَإِن لَّمۡ تَفۡعَلُواْ فَأۡذَنُواْ بِحَرۡبٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۖ وَإِن تُبۡتُمۡ فَلَكُمۡ رُءُوسُ أَمۡوَٰلِكُمۡ لَا تَظۡلِمُونَ وَلَا تُظۡلَمُونَ 279
Ti ẹ ko ba se ohun ti wọn pa yin lasẹ pẹlu rẹ, ki ẹ ya lọọ mọ, ki ẹ si tun mọ amọdaju pẹlu ogun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ati wipe ti ẹ ba ronu piwada lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹ si fi owo ele silẹ, ẹyin ni ẹ ni odiwọn ohun ti ẹ dogo ninu awọn ipilẹ awọn owo (owo idokowo) yin, ti ẹ ko nii se abosi ẹnikankan pẹlu gbigba ele lori ipilẹ owo yin, ati wipe wọn ko ni se abosi yin pẹlu adinku nibẹ.
وَإِن كَانَ ذُو عُسۡرَةٖ فَنَظِرَةٌ إِلَىٰ مَيۡسَرَةٖۚ وَأَن تَصَدَّقُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 280
Ati wipe tiobajẹwipe ẹniti ẹyin nbeere gbese yin ni ọwọ rẹ jẹ ẹniti ara nni, ti ko ri ohun ti yoo fi di gbese rẹ, ẹ lọ bibeere rẹ lara di igba ti owo naa yoo rọrun fun un, ti yoo si ri ohun ti yoo fi san gbese naa, ati wipe ki ẹ se saara fun un pẹlu fifi bibeere gbese naa silẹ, tabi jija apakan rẹ ju silẹ, o loore fun yin, ti ẹ ba jẹ ẹniti o mọ ọla nkan naa ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .
وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا تُرۡجَعُونَ فِيهِ إِلَى ٱللَّهِۖ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 281
Ati wipe ki ẹ paya ọjọ kan ti ẹ o pada nibẹ lapapọ lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe ẹyin yoo si duro niwaju Rẹ, lẹyin igba naa ni wọn yoo fun ẹmin kọọkan ni ẹsan ohun ti o ba se ninu daadaa tabi aburu, wọn ko nii se abosi wọn pẹlu sise adinku ẹsan awọn daadaa wọn, tabi sise alekun iya lori awọn aida wọn.
Ninu awọn ẹsẹ ti o tobi jijẹ owo ele wa, tori idi eleyi Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) se adehun iya fun ẹniti o njẹ pẹlu ogun ati iparẹ ni ile aye ati titi ẹsẹ bọ ẹsẹ ni Ọjọ Ikẹyin.
Didunni mọ awọn idajọ Ṣẹria nibi ibasepọ olowo de, yoo sọ ibukun ati igberu kalẹ sinu rẹ.
Ọla suuru lori ẹniti ara ba nni ati gbigbe ọrọ ni fufuyẹ fun un, pẹlu sise saara fun un pẹlu apakan gbese naa tabi gbogbo rẹ.