وَمَآ أَنفَقۡتُم مِّن نَّفَقَةٍ أَوۡ نَذَرۡتُم مِّن نَّذۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُهُۥۗ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٍ 270
Ohun ti ẹ ba na ninu inawo, o jẹ ohun ti o kere ni tabi ohun ti o pọ, niti wiwa iyọnu Ọlọhun Ọba Allah, tabi nipa wipe ẹ duuni mọ sise titẹle ti Ọlọhun Ọba Allah, lati ọdọ ara yin, ti wọn ko jẹyin nipa rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah mọ gbogbo nkan naa, nkankan ko si ni sọnu lọdọ rẹ ninu rẹ, Yoo si pada san yin lẹsan le lori, ni ẹsan ti o tobi, ko si si fun awọn alabosi ti wọn jẹ ẹniti o ma nkọ ohun ti o jẹ dandan le wọn lori, awọn ti wọn ma nkọja ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah, awọn alaranse ti wọn yoo kọ iya Ọjọ Igbende fun wọn.
إِن تُبۡدُواْ ٱلصَّدَقَٰتِ فَنِعِمَّا هِيَۖ وَإِن تُخۡفُوهَا وَتُؤۡتُوهَا ٱلۡفُقَرَآءَ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۚ وَيُكَفِّرُ عَنكُم مِّن سَئَِّاتِكُمۡۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ 271
Ti ẹ ba se afihan ohun ti ẹ ba na ninu saara pẹlu owo, saara naa ma dara pupọ ni saara yin, ti ẹ ba wa fi pamọ, ti ẹ si fun awọn olosi, ohun ni o loore ju fun yin ju ki ẹ se afihan rẹ lọ; toripe ohun ni o sun mọ sise afọmọ, o si nbẹ nibi saara awọn ti wọn se afọmọ, idaabobo awọn ẹsẹ wọn, ati aforijin fun un, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni olufunni niro ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ninu isesi yin ko si lee pamọ fun Un.
۞لَّيۡسَ عَلَيۡكَ هُدَىٰهُمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يَشَآءُۗ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَلِأَنفُسِكُمۡۚ وَمَا تُنفِقُونَ إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ ٱللَّهِۚ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يُوَفَّ إِلَيۡكُمۡ وَأَنتُمۡ لَا تُظۡلَمُونَ 272
Ko si fun iwọ - irẹ Anọbi - fifi wọn mọ ọna lọ si ibi gbigba ododo, ati titẹriba fun un, ati gbigbe wọn si ori rẹ, ati wipe ohun ti o jẹ dandan fun ọ, ni jijuwọn niwe lọsi ibi ododo, ati fifi mọ wọn, toripe dajudaju sise kongẹ ododo ati mima ọna lọ si ibẹ wa ni ọwọ Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe Oun ni O ma nfi ẹniti o ba wu U mọna. Ohun ti ẹ ba na ninu daradara, anfaani rẹ yoo pada si ọdọ yin; toripe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah rọrọ kuro nibẹ, ki inawo yin yaa jẹ ohun ti o mọ fun Ọlọhun Ọba Allah, ẹ ko waa ri awọn olugbagbọ ododo ni tootọ, wọn ko nii na ayaafi lati wa iyọnu Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe ohun ti ẹ ba na ninu daradara, o kere ni tabi o pọ, dajudaju ẹyin wọn yoo fun yin ni ẹsan rẹ perepere, ti ko ni adinku, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii se abosi ẹnikankan.
Nigbati O darukọ ninawo si oju ọna Rẹ, ti O si pe awọn olugbagbọ ododo si ibẹ, O wa se alaye fun wọn, awọn ibi ti wọn yoo maa nawo si, ni O fi waa sọ wipe:
لِلۡفُقَرَآءِ ٱلَّذِينَ أُحۡصِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا يَسۡتَطِيعُونَ ضَرۡبٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ يَحۡسَبُهُمُ ٱلۡجَاهِلُ أَغۡنِيَآءَ مِنَ ٱلتَّعَفُّفِ تَعۡرِفُهُم بِسِيمَٰهُمۡ لَا يَسَۡٔلُونَ ٱلنَّاسَ إِلۡحَافٗاۗ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٌ 273
Ẹ maa fun awọn olosi, awọn ti wọn jẹ wipe o kọ fun wọn lati jagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ninu irin-ajo lati wa arisiki, ti alaimọkan yoo maa lero pẹlu isesi wọn wipe ọlọrọ ni wọn, nitori sise amojukuro wọn nibi mima beere, yoo si maa da wọn mọ, ẹniti o ba garun wo wọn pẹlu awọn amin wọn ninu bukaata ti o fi oju han lori awọn ara wọn, ati awọn asọ wọn, ninu iroyin wọn ni wipe dajudaju awọn kii se awọn olosi yoku, awọn ti wọn ma nbeere lọwọ awọn eniyan, ni ẹniti ntẹpẹlẹ mọ ibeere wọn, ohun ti ẹ ba na ninu owo ati ohun ti o yatọ sii, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah nimọ pẹlu rẹ, ati wipe Yoo si pada san yin ni ẹsan lori rẹ, ẹsan ti o tobi.
ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُم بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ 274
Awọn ti wọn nna awọn dukia wọn, niti wiwa iyọnu Ọlọhun Ọba Allah ni oru ati ọsan, ni kọkọ ati ni gbangba laini sekarimi ninu tabi sekagbọmi, ẹsan wọn yoo maa bẹ fun wọn ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ni Ọjọ Igbende, ko si si ibẹru fun wọn nibi ohun ti wọn dojukọ ninu alamọri wọn, wọn kosi ni maa banujẹ lori ohun ti o bọ fun wọn ni ile aye, ọla kan ni lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ati idẹra.
nigbati olugbagbọ ododo ba nse afọmọ nibi awọn inawo rẹ, ati awọn saarẹ rẹ, ko si inira fun un nibi sise afihan rẹ ati ifipamọ rẹ pẹlu bi o se dara si, bi o ti lẹ jẹ wipe fifi pamọ ni o tun fi ni ere ati ẹsan, toripe ohun ni o sun mọ ise afọmọ ju.
Pipe awọn olugbagbọ ododo lọsi bi bibojuwo ati nini akolekan awọn ti wọn ni bukaata, awọn ti ilamojukuro kọ fun wọn nibi sise afihan isesi wọn, ati bibeere lọwọ awọn eniyan.
Sise mima nawo si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ni ofin ni gbogbo asiko ati igba, ati titobi ẹsan rẹ, nibi ti O ti se adehun le lori (ti ọla Rẹ ga) pẹlu ẹsan ti o tobi ni aye ati ni Ọjọ Ikẹyin.