ثُمَّ يَتُوبُ ٱللَّهُ مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ عَلَىٰ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 27
Lẹyin igba naa, ẹniti o ba sẹri kuro nibi keferi ati ọna anu rẹ lẹyin ijiya naa, dajudaju Ọlọhun Ọba yoo gba ironu piwada rẹ toripe Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluforijini fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, yoo si kẹ wọn nigbati wọn ma ngba ironu piwada lẹyin keferi sise ati ẹsẹ dida.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡمُشۡرِكُونَ نَجَسٞ فَلَا يَقۡرَبُواْ ٱلۡمَسۡجِدَ ٱلۡحَرَامَ بَعۡدَ عَامِهِمۡ هَٰذَاۚ وَإِنۡ خِفۡتُمۡ عَيۡلَةٗ فَسَوۡفَ يُغۡنِيكُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦٓ إِن شَآءَۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 28
Ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo ninu Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si tẹle nkan ti wọn se ni ofin fun wọn dajudaju awọn ọlọsẹbọ jẹ ẹgbin; nitori keferi ati abosi ati iwa eebu ati awọn adamọ ti ko dara ti o wa pẹlu wọn; wọn ko gbọdọ wọ ayika ile ọwọ naa –ninu rẹ naa ni masalaasi ọwọ naa wa- ti wọn ba jẹ oluse hajj tabi umura lẹyin ọdun wọn yii ti o jẹ ọdun kẹsan hijirah, ti ẹ ba npaya - ẹyin olugbagbọ ododo - osi nitori dida nkan ti wọn ngbe fun yin ninu ounjẹ ati owo sise ti o yatọ si ara wọn, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo to yin ninu ọla Rẹ ti o ba fẹ, dajudaju Allah jẹ onimimọ pẹlu isesi yin eyiti ẹ wa lori rẹ, ọjọgbọn nibi nkan ti o ndari.
قَٰتِلُواْ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَلَا يُحَرِّمُونَ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَلَا يَدِينُونَ دِينَ ٱلۡحَقِّ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ حَتَّىٰ يُعۡطُواْ ٱلۡجِزۡيَةَ عَن يَدٖ وَهُمۡ صَٰغِرُونَ 29
Ki ẹ yaa baja - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn keferi ti ko nigbagbọ ninu Allah wipe O jẹ Ọlọhun Ọba ti ko ni orogun, wọn ko si ni igbagbọ nipa ọjọ igbende, wọn ko si jina si oun ti Allah se ni eewọ le wọn lori ati ojisẹ Rẹ gẹgẹ bi okunbete, ẹran ẹlẹdẹ, oti, owo igbọbe ati ounti o yato si, wọn ko si tẹriba fun ofin Ọlọhun Ọba Allah, ninu awọn yahuudi ati nasaara, titi ti wọn yoo fi maa san wo itanran pẹlu ọwọ wọn ni ẹniti a ti bori.
وَقَالَتِ ٱلۡيَهُودُ عُزَيۡرٌ ٱبۡنُ ٱللَّهِ وَقَالَتِ ٱلنَّصَٰرَى ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ ٱللَّهِۖ ذَٰلِكَ قَوۡلُهُم بِأَفۡوَٰهِهِمۡۖ يُضَٰهُِٔونَ قَوۡلَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَبۡلُۚ قَٰتَلَهُمُ ٱللَّهُۖ أَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ 30
Dajudaju yahuudi ati nasaara ẹlẹbọ ni wọn nse, awọn yahuudi di ẹlẹbọ pẹlu Allah nitori wipe wọn npe Huṣayri ni ọmọ Ọlọhun Ọba Allah, nasaara naa si se ẹbọ pẹlu Rẹ nitori wipe wọn npe ẹni mimọ Isa ni ọmọ Ọlọhun Ọba Allah, eleyi ni ọrọ ti wọn hun, ti wọn si nsọ pẹlu ifẹ inu wọn laisi awijare le lori, wọn fi gbolohun wọn yii jọ awọn ọlọsẹbọ ti wọn ti siwaju, awọn ti wọn sọ wipe: dajudaju awọn malaika jẹ ọmọbinrin Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba Allah ga ju eleyi lọ niti titobi, Ọlọhun Ọba Allah yoo pa wọn run lori yiyi kuro nibi ododo ti o fi oju han lọsi ibi ibajẹ?!
ٱتَّخَذُوٓاْ أَحۡبَارَهُمۡ وَرُهۡبَٰنَهُمۡ أَرۡبَابٗا مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَٱلۡمَسِيحَ ٱبۡنَ مَرۡيَمَ وَمَآ أُمِرُوٓاْ إِلَّا لِيَعۡبُدُوٓاْ إِلَٰهٗا وَٰحِدٗاۖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ سُبۡحَٰنَهُۥ عَمَّا يُشۡرِكُونَ 31
Awọn yahuudi sọ awọn onimimọ inu wọn, bẹẹ ni awọn nasaara sọ olujọsin fun wọn di; awọn ọlọhun yatọ si Allah, ti nsọ nkan ti Ọlọhun Ọba Allah se leewọ fun wọn ti ẹtọ, wọn si nsọ nkan ti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ di eewọ, awọn nasaara si sọ ẹni mimọ Isa ọmọ maryam di ọlọhun pẹlu Allah, Ọlọhun Ọba Allah ko si pasẹ fun awọn onimimọ yahuudi ati awọn ti nasaara njọsin fun, bẹẹ ni ko pasẹ fun huṣayri ati Isa ọmọ Maryam bikose wipe ki wọn o maa sin lohun nikan soso, wọn ko si gbọdọ se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, Ohun ti mimọ nbẹ fun jẹ Ọlọhun Ọba aaso, ko si si ẹniti ijọsin tọsi yatọ si I, mimọ ni fun Un, O si mọ kọja ki akẹgbẹ wa pẹlu Rẹ lọ gẹgẹ bi awọn olusẹbọ se nsọ ati awọn ti o yatọ si wọn.
Ẹri lori titọ sisopọ ọkan pẹlu awọn okunfa arisiki ti o wa ninu awọn aayah yii ko si le igbarale jinna.
Ẹri lori wipe arisiki kii se igbiyanju wa ninu awọn aayah naa, o si jẹ ọla lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ti o si la pinpin rẹ bọrun.
Owo itanran jẹ ọkan ninu awọn ẹsa mẹta, ti Islam sẹri rẹ si awọn ọta, ti ohun ti wọn gba lero nibẹ jẹ ki gbogbo alamọri ọrọ jẹ ti gbogbo awọn olugbafa lati le fa ifẹsẹwalẹ awọn keferi yọ.
Ẹgbin ati aburu wa ni ara yahuudi eyiti ti o mu ni akin lati da oju kọ Ọlọhun Ọba Allah, ati lati le mu ẹdinku titobi Ọlọun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun.