فَلَمَّا رَأَوۡهُ زُلۡفَةٗ سِيَٓٔتۡ وُجُوهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَقِيلَ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تَدَّعُونَ 27
Nigbati adehun naa sẹlẹ si wọn, ti wọn si fi oju kan iya ti o sun mọ, eleyi ni ọjọ igbende, oju awọn ti wọn se keferi si Allah si yi pada si dudu, wọn wa sọ fun wọn pe: eleyi ni ohun ti ẹ nwa ni ile aye, ti ẹ si nkanju rẹ.
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَهۡلَكَنِيَ ٱللَّهُ وَمَن مَّعِيَ أَوۡ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ ٱلۡكَٰفِرِينَ مِنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ 28
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ opurọ yii ni ẹniti o ko rira wọn: ẹ fun mi niro ti Allah ba pa mi, ti o si pa awọn ti wọn nbẹ pẹlu mi ninu awọn olugbagbọ ododo, tabi o kẹwa ti o si lọ asiko wa lara, taani ẹniti yoo la awọn keferi kuro nibi iya inira?! ẹnikankan ko le la wọn nibẹ.
قُلۡ هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ءَامَنَّا بِهِۦ وَعَلَيۡهِ تَوَكَّلۡنَاۖ فَسَتَعۡلَمُونَ مَنۡ هُوَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 29
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi: Oun ni ajọkẹ aye ti O npe yin lọ si ibi ijọsin Rẹ ni Oun nikan, a nigbagbọ si I, Oun nikan ni a si gbara le nibi alamọri wa, ẹ o si pada mọ - ti ko si ibuyẹ - ẹniti o wa ni anu ti o fi oju han yatọ si ẹniti o wa ni oju ọna tootọ.
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَصۡبَحَ مَآؤُكُمۡ غَوۡرٗا فَمَن يَأۡتِيكُم بِمَآءٖ مَّعِينِۢ 30
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ yii: ẹfun mi niro ti omin yin eyiti ẹ nmu ba gbẹ furufuru ni ilẹ ẹ ko le de ibẹ, taani yoo mu omin ti o pọ ti o nsan wa fun yin?! Ko si ẹnikankan yatọ si Allah.
سورة (MAKIYYAH)
Jijẹri Allah fun anọbi pẹlu iwa ti o dara, ati didaaboboo ati sise afirinlẹ rẹ.
نٓۚ وَٱلۡقَلَمِ وَمَا يَسۡطُرُونَ 1
(نٓۚ) (Nun) ọrọ ti gbawaju lori iran iru rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah, Allah fi gege ikọwe naa bura, O si tun fi ohun ti awọn eniyan nfi awọn gege ikọwe wọn se bura.
مَآ أَنتَ بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ بِمَجۡنُونٖ 2
Iwọ kii se - irẹ ojisẹ - were pẹlu idẹkun ti Allah se fun ọ nipa ijẹ anọbi, bikosepe o jẹ ẹniti o bọpa bọsẹ kuro nibi were eyiti awọn ẹlẹbọ nsọ pẹlu rẹ.
وَإِنَّ لَكَ لَأَجۡرًا غَيۡرَ مَمۡنُونٖ 3
Dajudaju ẹsan ti ko nii ja nbẹ fun ọ lori ohun ti o nfi ara kin nibi gbigbe isẹ riran naa de ọdọ awọn eniyan, ko si si iregun fun ẹnikankan le ọ lori lori rẹ.
وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٖ 4
Atipe dajudaju iwọ ni ẹniti iwa rẹ dara ju eyiti Alukuraani mu wa, iwọ ni ẹniti o nwu iwa ti o pe ju ti o wa ninu rẹ.
فَسَتُبۡصِرُ وَيُبۡصِرُونَ 5
Iwọ yoo si ri, awọn opurọ yii naa yoo si ri.
بِأَييِّكُمُ ٱلۡمَفۡتُونُ 6
Ẹniti o jẹ were gan ninu yin yoo fi oju han nigbati ododo ba hande.
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ 7
Dajudaju Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - mọ ẹniti o yẹ kuro ni oju ọna Rẹ, Oun nikan ni o si mọna lọ si ibẹ, O si mọ wipe awọn ni wọn sọnu kuro nibẹ, atipe dajudaju iwọ ni o mọna lọ si ibẹ.
فَلَا تُطِعِ ٱلۡمُكَذِّبِينَ 8
Mase tẹle - irẹ ojisẹ - awọn ti wọn npe ohun ti o mu wa nirọ.
وَدُّواْ لَوۡ تُدۡهِنُ فَيُدۡهِنُونَ 9
Wọn nrankan ki o ba wọn sọrẹ, ki o si se idẹkun fun wọn lori isiro ọjọ ẹsan, ki wọn yaa rọ fun ọ, ki wọn si se aanu pẹlu rẹ.
وَلَا تُطِعۡ كُلَّ حَلَّافٖ مَّهِينٍ 10
Mase tẹle ọlọpọ ibura lori ibajẹ ẹni yẹpẹrẹ.
هَمَّازٖ مَّشَّآءِۢ بِنَمِيمٖ 11
Ọlọpọ eebu fun awọn eniyan, ọlọpọ irin ofofo laarin wọn; lati se opinya laarin wọn.
مَّنَّاعٖ لِّلۡخَيۡرِ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ 12
Ọlọpọ ikọ rere, olukọja ẹnu aala si awọn eniyan nibi awọn dukia wọn ati awọn ọmọluwabi wọn ati ẹmin wọn, ọlọpọ ẹsẹ ati awọn asise.
عُتُلِّۢ بَعۡدَ ذَٰلِكَ زَنِيمٍ 13
Ẹni lile, ọdaju, olupe apemọra wiwa pẹlu ninu ijọ rẹ.
أَن كَانَ ذَا مَالٖ وَبَنِينَ 14
Nitoripe o jẹ olowo ati awọn ọmọ, o se igberaga kuro nibi igbagbọ si Allah ati si ojisẹ Rẹ.
إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 15
Ti wọn ba ka awọn aayah wa fun un, yoo sọpe: eleyi ni akọsilẹ ninu ọrọ eyesọ awọn ẹni alakọkọ.
سَنَسِمُهُۥ عَلَى ٱلۡخُرۡطُومِ 16
A o fi amin si ori imu rẹ, ti yoo ko aleebu ba a, ti yoo si wa pẹlu rẹ.
Gbigba iroyin ojisẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun pẹlu awọn iwa Alukuraani.
Awọn iroyin keferi jẹ iroyin aleebu ti o di dandan fun olugbagbọ ododo ki o jinna si ati titẹle awọn ẹni rẹ.
Ẹniti o ba pọ ni ibura yoo yẹpẹrẹ lọdọ ajọkẹ aye, ipo rẹ yoo si walẹ ni ọdọ awọn eniyan.