إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ لَيُسَمُّونَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ تَسۡمِيَةَ ٱلۡأُنثَىٰ 27
Dajudaju awọn ti ko nigbagbọ nipa ajinde, wọn yoo maa sọ orukọ awọn Malaaika ni orukọ abo pẹlu adisọkan wọn wipe wọn jẹ awọn ọmọbinrin Allah ni ile ikẹyin, giga Allah ju gbolohun wọn lọ ni giga ti o tobi.
وَمَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّۖ وَإِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡٔٗا 28
Ko si si imọ fun wọn ti wọn fi ara ti nibi pipe wọn ni orukọ abo, wọn ko tẹle nkankan nibi eleyi ju idandan ati royiroyi lọ, bẹẹni dajudaju idandan ko le rọrọ nibi ododo kankan ti yoo duro fi wa duro ni aaye rẹ.
فَأَعۡرِضۡ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكۡرِنَا وَلَمۡ يُرِدۡ إِلَّا ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا 29
Ki o ya gunri - irẹ ojisẹ - kuro lọdọ ẹniti o pẹyin da kuro nibi iranti Allah, ti ko si ka a kun, ko si gbero ju isẹmin aye lọ, ko si sisẹ fun ọrun rẹ; nitoripe ko ni igbagbọ si i.
ذَٰلِكَ مَبۡلَغُهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱهۡتَدَىٰ 30
Eleyi ti awọn ẹlẹbọ nsọ yii - nipa pipe awọn malaika ni orukọ abo - ohun ni opin ibi ti imọ wọn de nitoripe wọn jẹ alaimọkan, wọn ko de ipo amọdaju, dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - Oun ni ẹniti o mọ ju nipa ẹniti o kuro ni oju ọna ododo, Oun si ni ẹniti O mọ ju nipa nipa ẹniti o mọna si oju ọna Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibi eleyi.
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَسَٰٓـُٔواْ بِمَا عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ بِٱلۡحُسۡنَى 31
Ti Allah nikan ni gbogbo ohun ti o wa ni gbogbo sanmọ, ti Rẹ si ni ohun ti o wa ni ilẹ niti inikapa ati isẹda ati idari, ki o le sẹsan fun awọn ti wọn se aidara nibi isẹ wọn ni ile aye pẹlu ohun ti wọn lẹtọ si ninu iya, yoo si sẹsan fun awọn olugbagbọ ododo ti wọn se isẹ daradara.
ٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ إِلَّا ٱللَّمَمَۚ إِنَّ رَبَّكَ وَٰسِعُ ٱلۡمَغۡفِرَةِۚ هُوَ أَعۡلَمُ بِكُمۡ إِذۡ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَإِذۡ أَنتُمۡ أَجِنَّةٞ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡۖ فَلَا تُزَكُّوٓاْ أَنفُسَكُمۡۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَنِ ٱتَّقَىٰٓ 32
Awọn ti o takate si awọn ẹsẹ nla ati awọn asise ti o buru ayaafi awọn ẹsẹ keekeeke, wọn ma nse amojukuro eleyi pẹlu gbigbe awọn ẹsẹ nla ju silẹ ati pipọ nibi itẹle awọn asẹ, dajudaju Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - jẹ ẹniti o gbaaye ni aforijin, yoo fi ori jin awọn ẹsẹ ẹru Rẹ nigbati wọn ba sẹri kuro nibẹ, Oun ti mimọ nbẹ fun nikan ni O nimọ ju nipa awọn isesi yin ati awọn alamọri yin nitori wipe o da baba yin Adamọ lati ibi yerupẹ ati nigbati ẹ wa ninu ikun awọn iya yin, ti wọn nda yin ni isẹda kan lẹyin isẹda, nkankan ko pamọ fun Un nibi eleyi, ẹ ko gbọdọ yin ẹmin ara yin pẹlu ibẹru, Oun ti mimọ nbẹ fun nikan ni O nimọ nipa ẹniti o nbẹru Rẹ; pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si awọn ohun ti O kọ.
أَفَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي تَوَلَّىٰ 33
Njẹ o ri biburu isesi ẹniti o gunri kuro nibi ẹsin alaafia lẹyin igbati o ti sunmọ ọ.
وَأَعۡطَىٰ قَلِيلٗا وَأَكۡدَىٰٓ 34
Ti o si nna diẹ ninu owo lẹyin naa ti o si nkọ; nitoripe dajudaju ahun jẹ adamọ rẹ pẹlu eleyi naa o jẹ ẹniti o se afọmọ ẹmin rẹ.
أَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلۡغَيۡبِ فَهُوَ يَرَىٰٓ 35
Se imọ kọkọ nbẹ pẹlu rẹ ni ti o nri, ti o si nfi kọkọ sọrọ?!
أَمۡ لَمۡ يُنَبَّأۡ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ 36
Tabi o jẹ oludadapa irọ mọ Allah?! Tabi wọn ko fun ẹniti o sọrọ nipa Allah yii niro nipa ohun ti o wa ninu iwe alakọkọ ni eyiti Allah sọkalẹ fun Musa?
وَإِبۡرَٰهِيمَ ٱلَّذِي وَفَّىٰٓ 37
Iwe Ibrahim ẹniti o se gbogbo ohun ti Ọlọhun Ọba rẹ la bọ lọrun ti o si pe e.
أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰ 38
Atipe eniyan kan ko nii gbe ẹsẹ ẹnikeji rẹ.
وَأَن لَّيۡسَ لِلۡإِنسَٰنِ إِلَّا مَا سَعَىٰ 39
Atipe dajudaju ko si fun ọmọniyan ju ẹsan isẹ ti o se lọ.
وَأَنَّ سَعۡيَهُۥ سَوۡفَ يُرَىٰ 40
Atipe dajudaju yoo pada ri isẹ rẹ ni riri oju ni ọjọ igbende.
ثُمَّ يُجۡزَىٰهُ ٱلۡجَزَآءَ ٱلۡأَوۡفَىٰ 41
Lẹyin naa wọn yoo fun ni ẹsan isẹ rẹ ni pipe ti ko nii ni ẹdinku.
وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلۡمُنتَهَىٰ 42
Atipe dajudaju ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ni - irẹ ojisẹ - ibusẹrisi awọn ẹru ati ibugunlẹ si wọn lẹyin iku wọn.
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَضۡحَكَ وَأَبۡكَىٰ 43
Atipe dajudaju Oun ni ẹniti o nmu idunnu ba ẹniti o ba wu U, yoo si pa a lẹrin, bẹẹni o nmu ibanujẹ ẹniti o ba wu U, yoo si pa a lẹkun.
وَأَنَّهُۥ هُوَ أَمَاتَ وَأَحۡيَا 44
Atipe dajudaju Oun ni O npa awọn alaaye ni ile aye, O si nji awọn oku pẹlu ajinde.
Pinpin awọn ẹsẹ si awọn ti o tobi ati awọn ti o kere.
Ewu sisọrọ nipa Allah laisi imọ.
Ilenisa kuro nibi fifọ ẹmin mọ.