ثُمَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُخۡزِيهِمۡ وَيَقُولُ أَيۡنَ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تُشَٰٓقُّونَ فِيهِمۡۚ قَالَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ إِنَّ ٱلۡخِزۡيَ ٱلۡيَوۡمَ وَٱلسُّوٓءَ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ 27
Lẹyin igba naa Ọlọhun Ọba Allah yoo tun yẹpẹrẹ wọn ni ọjọ igbende pẹlu iya, Yoo si fi rẹ wọn nilẹ, Yoo si sọ fun wọn: nibo ni awọn akẹgbẹ Mi ti ẹ nmu papọ mọ Mi nibi ijọsin wa, ti ẹ si nba awọn Anọbi Mi ati awọn olugbagbọ ododo se ọta nitori wọn? Awọn onimimọ olureni sọpe: dajudaju iyẹpẹrẹ ati iya ni ọjọ igbende alukiyaamọ yoo sẹlẹ si awọn keferi.
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡۖ فَأَلۡقَوُاْ ٱلسَّلَمَ مَا كُنَّا نَعۡمَلُ مِن سُوٓءِۢۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 28
Awọn ti Malaika iku ati olukunlọwọ ninu awọn Malaika gba ẹmin wọn, awọn ni wọn gbe abosi wọ lori ẹmin ara wọn pẹlu sise keferi si Allah, wọn si gba ni ẹniti o jupa jusẹ silẹ nigbati iku sọkalẹ si wọn, wọn tako keferi ti wọn wa lori rẹ ati ẹsẹ; ni ẹniti nlero wipe atako naa yoo se wọn ni anfaani, wọn yoo sọ fun wọn: ẹ parọ, ẹ si jẹ keferi ti ẹ nse ẹsẹ, dajudaju Allah jẹ onimimọ pẹlu ohun ti ẹ se ni ile aye, nkankan ko pomọ fun un ni inu rẹ, Yoo si san yin lẹsan le lori.
فَٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَلَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ 29
Wọn yoo wọn: ẹ maa wọ awọn ẹnu ọna jahannamo ni ẹniti yoo maa gbe ibẹ gbere ni ibamun si isẹ yin, ibudarisi olugberaga si igbagbọ Allah ati ijọsin Rẹ lọkan soso ma buru o.
۞وَقِيلَ لِلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ مَاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡۚ قَالُواْ خَيۡرٗاۗ لِّلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۚ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞۚ وَلَنِعۡمَ دَارُ ٱلۡمُتَّقِينَ 30
Wọn yoo si sọ fun awọn ti wọn paya Ọlọhun Ọba pẹlu sise awọn asẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti O kọ: kinni Ọlọhun yin sọkalẹ fun Anọbi yin Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun? Wọn yoo dahun: Allah sọ oore ti o tobi kalẹ fun un, ẹsan ti o dara nbẹ fun awọn ti o se ijọ sin daradara, ti wọn si se daradara nibi ibalopọ wọn pẹlu awọn ẹda Rẹ ni ile aye, ninu rẹ ni aranse ati arisiki ti o gbaaye, bẹẹ ni ohun ti O pese fun wọn lọrun loore ju ohun ti O fẹ kọkọ se fun wọn ni aye lọ, ile awọn olupaya Ọlọhun wọn pataki nitori titẹle ayẹ Rẹ ati jijinna si ohun ti O kọ, ile tii se ile ọrun.
جَنَّٰتُ عَدۡنٖ يَدۡخُلُونَهَا تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ لَهُمۡ فِيهَا مَا يَشَآءُونَۚ كَذَٰلِكَ يَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلۡمُتَّقِينَ 31
Ọgba idẹra jẹ aaye ti o rinlẹ, ti wọn yoo wọ, awọn odo yoo maa san ni abẹ orule rẹ ati ni abẹ igi rẹ, ohun ti ẹmin wọn nfẹ yoo maa wa fun wọn ninu ọgba idẹra naa, gẹgẹ bi nkan jijẹ ati nkan mimu ati ohun ti o yatọ si i, Iru apejuwe eyiti wọn yoo san ni ẹsan fun awọn olupaya Ọlọhun ninu awọn ọmọlẹyin Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ohun naa ni wọn san ni ẹsan fun ijọ ti o ti siwaju.
ٱلَّذِينَ تَتَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ طَيِّبِينَ يَقُولُونَ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمُ ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 32
Awọn ti Malaika iku ati ilukun lọwọ ninu awọn Malaika gba ẹmin wọn wa lori mimọ ọkan kuro nibi keferi, awọn Malaika yoo maa ba wọn sọrọ pẹlu gbolohun wọn: alaafia ko maa bẹ fun yin, ẹ ti bọ kuro nibi gbogbo aleebu, ẹ maa wọ ọgba onidẹra pẹlu ohun ti ẹ se ni ile aye pẹlu adisọkan daradara ati isẹ rere.
هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَوۡ يَأۡتِيَ أَمۡرُ رَبِّكَۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 33
Njẹ awọn ẹlẹbọ olurọ yii nreti ju ki Malaika iku ati olukun lọwọ ninu awọn Malaika wa lati gba ẹmin wọn ati gbigba wọn loju ati lẹyin tabi ki asẹ Allah de lati pa wọn fin-in fin-in pẹlu iya ni ile aye lọ ni? Iru isẹ yii eyiti awọn ẹlẹbọ se ni Mẹkkah, ohun naa ni awọn ẹlẹbọ ti o siwaju wọn se, Allah si pa wọn run, bẹẹ ni ko se abosi si wọn nigbati o pa wọn run, bikose wipe awọn ni wọn se abosi ẹmin ara wọn pẹlu mimu u lọ si ibi iparun lati ibib sise keferi si Allah.
فَأَصَابَهُمۡ سَئَِّاتُ مَا عَمِلُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 34
Ijiya isẹ wọn si sọkalẹ le wọn lori eyiti wọn se nisẹ, iya ti wọn nfi nse yẹyẹ nigbati wọn ba nran wọn leti si rọkirika ara wọn.
Ọla ti nbẹ fun onimimọ ati wipe wọn jẹ ẹniti o ma nsọ ododo ni ile aye ati ọjọ ti awọn ẹlẹri yoo naro ati wipe dajudaju iwoyesi nbẹ fun gbolohun wọn ni ọdọ Ọlọhun ati ni ọdọ ẹda Rẹ.
Ninu ẹkọ awọn Malaika pẹlu Allah ni wipe dajudaju wọn ma nse afiti imọ si ọdọ Allah laimaa sọpe: dajudaju awa mọ ohun ti ẹ nse, wọn si ma nse afihan wipe awọn ko mọ ọ ayaafi pẹlu ẹka lati ọdọ Allah ti O ga julọ.
Ninu apọnle Allah ni bibẹ Rẹ lori fifun awọn ẹni Alujannah ni gbogbo ohun ti wọn ba ngbero debi wipe Yoo maa ran wọn leti awọn idẹkun eyiti ko ru wuyẹ ni ori ọkan wọn.
Isẹ ni okunfa ati ipilẹ nibi wiwọ ọgba idẹra ati lila kuro nibi ina, eleyi yoo si sẹlẹ lati ara ikẹ Allah ati idẹkun rẹ lori awọn olugbagbọ ododo, kii se pẹlu ete wọn tabi agbara wọn.