وَمَثَلُ ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمُ ٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِ ٱللَّهِ وَتَثۡبِيتٗا مِّنۡ أَنفُسِهِمۡ كَمَثَلِ جَنَّةِۢ بِرَبۡوَةٍ أَصَابَهَا وَابِلٞ فََٔاتَتۡ أُكُلَهَا ضِعۡفَيۡنِ فَإِن لَّمۡ يُصِبۡهَا وَابِلٞ فَطَلّٞۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ 265
Apẹrẹ awọn olugbagbọ ododo, awọn ti wọn nna awọn dukia wọn, ni ẹniti wọn fi nwa iyọnu Ọlọhun Ọba Allah, ti ọkan wọn si balẹ pẹlu ododo adehun Ọlọhun Ọba Allah, yatọ si wipe wọn jẹ wọn nipa, gẹgẹ bi apẹrẹ ọgba, ti o wa ni oke ti o ga, ti o si dara, ti o ojo ti o pọ wa sọkalẹ sibẹ, ni o wa mu eso adipele jade, ti o ba wipe ojo ti o pọ ko sọkalẹ sibẹ, ojo ti o fuyẹ ti sọkalẹ sibẹ, o si ti too lati jẹ ki ilẹ rẹ dara, bakannaa ni awọn inawo awọn aluse afọmọ, Ọlọhun Ọba Allah yoo maa gba, Yoo si se ẹsan rẹ ni adipele, koda ki o jẹ ohun ti o kere, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti O nri gbogbo ohun ti ẹ nse, isesi awọn oluse afọmọ ko si nii pamọ fun Un ati awọn oluse sekaarimi, Yoo si pada san olukuluku ni ẹsan ohun ti o tọ sii.
Lẹyin igba naa ni O wa fi apẹrẹ kan lelẹ (ti ọla Rẹ ga) , ti yoo yaworan isesi ẹniti o nna owo rẹ ni ti sekarimi, ni O fi wa sọ wipe:
أَيَوَدُّ أَحَدُكُمۡ أَن تَكُونَ لَهُۥ جَنَّةٞ مِّن نَّخِيلٖ وَأَعۡنَابٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ لَهُۥ فِيهَا مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ وَأَصَابَهُ ٱلۡكِبَرُ وَلَهُۥ ذُرِّيَّةٞ ضُعَفَآءُ فَأَصَابَهَآ إِعۡصَارٞ فِيهِ نَارٞ فَٱحۡتَرَقَتۡۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَتَفَكَّرُونَ 266
Se ẹnikan ninu yin wa nrankan sibi ki ọgba kan wa fun un, ti ọpẹ nbẹ nibẹ ati ‘inab’, ti o nsan ti aarin rẹ awọn akere mọdo ti o dun, ti o si nbẹ fun un ninu rẹ awọn oniranran awọn eso ti o dara, ti ogbo waa de si ẹniti o nii, ti o ti waa di agbalagba, ti ko ni agbara lati se isẹ ati lati ko nkan jọ, ti o si jẹ wipe awọn ọmọ keekeeke ti o lẹ ni o ni, ti wọn ko ni ikapa lati se isẹ, ti ọwọ atẹgun ti o le, ti ina ti o si ni agbara nbẹ nibẹ waa fi ọwọ ba ọgba naa, ni gbogbo ọgba naa ba jo, ti o si jẹ wipe oun jẹ ẹniti o ni bukaata si ju, nitori ogbo rẹ, ati lilẹ awọn ọmọ rẹ? ! Isesi ẹniti nna owo rẹ lati se afihan si awọn eniyan, da gẹgẹ bi apẹrẹ ọkunrin yii; ti yoo waa ba Ọlọhun Ọba Allah ni Ọjọ Igbende laini awọn daadaa kankan, ni asiko kan ti oun ni bukaata ti o lagbara sii, apẹrẹ alaye yii, Ọlọhun Ọba Allah nse alaye fun yin, ohun ti yoo se yin ni anfaani ni aye ati ni Ọjọ Ikẹyin, ki ẹ le baa jẹ ẹniti yoo maa ronu sii.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنفِقُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا كَسَبۡتُمۡ وَمِمَّآ أَخۡرَجۡنَا لَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِۖ وَلَا تَيَمَّمُواْ ٱلۡخَبِيثَ مِنۡهُ تُنفِقُونَ وَلَسۡتُم بَِٔاخِذِيهِ إِلَّآ أَن تُغۡمِضُواْ فِيهِۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ حَمِيدٌ 267
Ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ maa na ninu owo ti o jẹ ẹtọ, ti o si dara eyiti ẹ ko jọ, ki ẹ si tun maa na ninu ohun ti a mu jade fun yin ninu awọn irugbin ilẹ, ẹ si ma gba eyiti ti ko dara ni ero ninu rẹ lati maa na, ti o jẹ wipe ti wọn ba fun yin, ẹ ko nii gbaa ayaafi igbati ẹ ba gbe oju si ẹgbẹ, ti ẹ si jẹ ẹni ti o korira lori aidaa rẹ, bawo ni ẹ o se maa yọnu fun Ọlọhun Ọba Allah ohun ti ẹ ko yọnu si fun awọn ẹmin yin? ! Ki ẹ si lọọ mọ pe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Ẹniti o rọrọ kuro nibi awọn inawo yin ni, Ẹniti a ma nyin ni ni paapaa Rẹ, ati awọn isẹ Rẹ.
Nigbati O pawọn lasẹ lati maa na ohun ti o dara, O waa kilọ fun wọn nibi ete esu ati royiroyi rẹ, ni O wa sọ wipe:
ٱلشَّيۡطَٰنُ يَعِدُكُمُ ٱلۡفَقۡرَ وَيَأۡمُرُكُم بِٱلۡفَحۡشَآءِۖ وَٱللَّهُ يَعِدُكُم مَّغۡفِرَةٗ مِّنۡهُ وَفَضۡلٗاۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ 268
Esu yoo maa dẹru bayin nibi osi, yoo si maa se yin loju lọyin lori sise ahun, yoo si maa peyin lọ si ibi mima da awọn ẹsẹ, ati awọn iyapa, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah nse adehun aforijin ti o tobi fun awọn ẹsẹ yin fun yin, ati irisiki ti o gbaaye, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Olugbaaye ọla, Ẹniti O ni imọ pẹlu awọn isesi awọn ẹru Rẹ.
يُؤۡتِي ٱلۡحِكۡمَةَ مَن يَشَآءُۚ وَمَن يُؤۡتَ ٱلۡحِكۡمَةَ فَقَدۡ أُوتِيَ خَيۡرٗا كَثِيرٗاۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ 269
O ma nfun ẹniti O ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ ni eyiti o dara nibi ọrọ sisọ ati ise kongẹ nibi isẹ sise, ati wipe ẹniti wọn ba fun ni nkan naa, paapaa wọn ti fun ni oore ti o pọ, ati wipe ko si nii ronu, bakannaa ko si nii gba isiti pẹlu awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah ayaafi awọn onilaakaye ti o pe perepere, eyiti wọn yoo maa tan imọlẹ pẹlu imọlẹ rẹ, ti wọn yoo si maa mọna pẹlu imọna rẹ.
Awọn olugbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga niti ootọ, wọn ma nni igbẹkẹle nibi adehun Ọlọhun Ọba Allah ati ẹsan Rẹ, tori naa ni wọn fi ma nna awọn dukia wọn, ati wipe wọn si ma nna laini ibẹru ati ibanujẹ, ati aiyijusi awọn royiroyi esu gẹgẹ bi dida ẹru bani pẹlu osi ati bukaata.
Sise afọmọ wa ninu ohun ti o tobi, ti o ma nfi ibukun si awọn isẹ ni, ti o si ma njẹ ki o gbeeru.
ọmọniyan ti ofo rẹ tobi ju ni ẹniti o ba nse afihan isẹ rẹ si awọn eniyan; tori wipe dajudaju ko si fun ninu ẹsan lori isẹ rẹ ayaafi ẹyin wọn ati lilu lọgọ ẹnu wọn.