وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ أَنتُمۡ قَلِيلٞ مُّسۡتَضۡعَفُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ تَخَافُونَ أَن يَتَخَطَّفَكُمُ ٱلنَّاسُ فََٔاوَىٰكُمۡ وَأَيَّدَكُم بِنَصۡرِهِۦ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 26
Ẹ tun ranti - ẹyin olugbagbọ ododo - igbati ẹ wa ni Mekkah pẹlu onka ti o kere, ti awọn ara ibẹ mu yin ni ọlẹ, ti wọn si nbori yin, ẹ npaya ki awọn ọta yin ma gba yin ni kiakia, Ọlọhun Ọba si fa yin sọdọ ki ẹ le dari si ọdọ Rẹ ni Mẹdinah, O fun yin lagbara pẹlu sise aranse fun yin lori awọn ọta yin ni oju ogun ti badiri jẹ ọkan nibẹ, O ran yin se pẹlu awọn nkan ti o dara, ninu ọpọ rẹ ni ikere ogun ti ẹ ri gba ni ọdọ awọn ọta yin, ki ẹ le ba dupẹ awọn idẹkun rẹ fun Ọlọhun, ki O le se alekun fun yin nibẹ, ẹ ko gbọdọ se aimoore si I, ki O maa ba gba ni ọwọ yin, tabi fi iya jẹ yin.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَخُونُواْ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ وَتَخُونُوٓاْ أَمَٰنَٰتِكُمۡ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 27
Ẹyin olugbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹ si tun ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ ko gbọdọ janba Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ pẹlu gbigbe itẹle asẹ Rẹ ju silẹ, tabi aijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si ma janba nkan ti wọn fi ọkan balẹ le yin lori ninu ẹsin ati ohun ti o yatọ si i, ti ẹ si mọ wipe ohun ti ẹ wa lori rẹ jẹ ijanba, ki ẹ ma baa wa ninu awọn onijanba.
Nigbati inifẹ si dukia ati ọmọ ma nti ẹru lọ si ibi ijanba, Ọlọhun Ọba Allah mu iro wa wipe mejeeji jẹ idaamun, O si sọ wipe:
وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَآ أَمۡوَٰلُكُمۡ وَأَوۡلَٰدُكُمۡ فِتۡنَةٞ وَأَنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥٓ أَجۡرٌ عَظِيمٞ 28
Ki ẹ lọ mọ - ẹyin olugbagbọ ododo - pe dajudaju awọn dukia yin ati awọn ọmọ yin jẹ aluba ati adanwo lati ọdọ Ọlọhun Ọba fun yin, o le kọ di yin kuro nibi isẹ ọrun, ki o si mu yin se ijanba, ki ẹ si lọ mọ wipe dajudaju Ọlọhun Ọba ni ẹsan ti o tobi lọdọ, ki ẹ ma jẹ ki ẹsan naa bọ mọ yin lọwọ nitori sisọ dukia ati awọn ọmọ yin, ki ẹ waa lọ se janba nitori ti wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تَتَّقُواْ ٱللَّهَ يَجۡعَل لَّكُمۡ فُرۡقَانٗا وَيُكَفِّرۡ عَنكُمۡ سَئَِّاتِكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۗ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ 29
Ẹyin olugbagbọ ododo si Ọlọhun Ọba Allah, ẹ ni igbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah ki ẹ si maa tẹle ojisẹ Rẹ, ki ẹ mọ wipe ti ẹ ba npaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nkan ti O kọ, Yoo se ohun ti ẹ yoo fi mọ iyatọ laarin ododo ibajẹ fun yin, ti ko nii da oju ru, ti yoo si pa nkan ti ẹ se ni asise rẹ fun yin, yoo si fi ori awọn ẹsẹ yin ji yin, Ọlọhun Ọba Allah jẹ ọlọla ti o tobi, ninu ọla Rẹ ti o tobi ni Alujannah ti o pese fun awọn olupaya Ọlọhun Ọba ninu awọn ẹru Rẹ.
وَإِذۡ يَمۡكُرُ بِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِيُثۡبِتُوكَ أَوۡ يَقۡتُلُوكَ أَوۡ يُخۡرِجُوكَۚ وَيَمۡكُرُونَ وَيَمۡكُرُ ٱللَّهُۖ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلۡمَٰكِرِينَ 30
Ranti - ire ojise - nigbati awọn ọlọsẹbọ kora jọ le ọ lori lati da ete si ọ pẹlu ki wọn o se ọ mọle tabi pa ọ, tabi le ọ kuro ni ilu rẹ lọ si ilu miran, wọn dete si ọ, Ọlọhun Ọba Allah si da ete wọn pada le wọn lori, Ọlọhun Ọba ndọgbọ, Oun ni O si loore ju ni ọlọgbọn.
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا قَالُواْ قَدۡ سَمِعۡنَا لَوۡ نَشَآءُ لَقُلۡنَا مِثۡلَ هَٰذَآ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ 31
Ti wọn ba ka awọn amin wa fun wọn, wọn yoo sọ niti isori kunkun ati isegberaga si ododo wipe: a ti gbọ iru eleyi ri, ti a ba fẹ iru ọrọ yii bi ti Alukuraani, awa naa ko ba sọ, Alukuraani ko jẹ nkankan ju irọ awọn ẹni akọkọ lọ; a ko le gba a gbọ.
وَإِذۡ قَالُواْ ٱللَّهُمَّ إِن كَانَ هَٰذَا هُوَ ٱلۡحَقَّ مِنۡ عِندِكَ فَأَمۡطِرۡ عَلَيۡنَا حِجَارَةٗ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ أَوِ ٱئۡتِنَا بِعَذَابٍ أَلِيمٖ 32
Tun ranti - ire ojise - nigbati awọn ọlọsẹbọ sọ wipe: iwọ Ọlọhun Ọba, ti o ba se wipe ododo ni nkan ti Muhammad mu wa jẹ, sọ okuta kalẹ lati oke sanmọ le wa lori, ki o pa wa rẹ, tabi ki O mu iya ti o le koko wa ba wa, wọn sọ eleyi niti idopin nibi iyan jija ati atako.
وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُعَذِّبَهُمۡ وَأَنتَ فِيهِمۡۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ مُعَذِّبَهُمۡ وَهُمۡ يَسۡتَغۡفِرُونَ 33
Ọlọhun Ọba ko fẹẹ fi iya jẹ awọn ijọ rẹ - boya wọn wa ninu awọn ijọ ti wọn njẹpe ni, tabi awọn ijọ ti o npepe - pẹlu ijiya ti yoo pa wọn tan yan-an yan-an, nigbati iwọ - irẹ Muhammad - jẹ alaaye ti o nbẹ ni aarin wọn, bibẹ rẹ ninu wọn jẹ ifọkan balẹ fun wọn kuro nibi iya, Ọlọhun Ọba ko le fi iya jẹ wọn nigbati wọn ba nwa aforijin kuro nibi isẹ wọn.
Idupẹ jẹ idẹkun ti o tobi, ti ọla Ọlọhun Ọba ma nti ara rẹ lekun, o si ma ndin ku latara gbigbagbe rẹ.
Ipo ti o tobi nbẹ fun gba fipamọ nibi deede isesi awọn olugbafa fun Ọlọhun Ọba Allah, nigbati wọn ba duro sinsin le lori, ti wọn si fi nwuwa, o si jẹ itọka mimọ ẹmin ati deedee isẹ rẹ.
Ohun ti o wa ni ọdọ Ọlọhun ninu ẹsan lori kiko ẹmin duro kuro nibi ohun ti a kọ jẹ ohun ti o loore ju awọn anfaani ti nsẹlẹ nigbati a ba de ibi ohun ti a kọ lọ, nitori dukia tabi awọn ọmọ.
Alaye nipa gigọ laakaye awọn olugunri wa ninu awọn aayah naa; toripe wọn ko sọpe: ti o ba ja si wipe eleyi jẹ ododo ni ọdọ rẹ, fi wa mọ ọna lọ si ibẹ.
Ọla ti nbẹ fun wiwa aforijin ati ibukun rẹ wa ninu awọn aayah naa, o si jẹ olukọdi kan ninu awọn olukọdi sisẹlẹ iya.