وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَٱسۡجُدۡ لَهُۥ وَسَبِّحۡهُ لَيۡلٗا طَوِيلًا 26
Ki o si ran an leti irun Mi loru: irun irọlẹ ati irun alẹ ati idaarun mọju lẹyin mejeeji.
إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ يُحِبُّونَ ٱلۡعَاجِلَةَ وَيَذَرُونَ وَرَآءَهُمۡ يَوۡمٗا ثَقِيلٗا 27
Dajudaju awọn ẹlẹbọ wọnyi nifẹ isẹmin aye, wọn si ma nse oju kokoro si i, wọn si ma ngbe ọjọ igbende ju si ẹyin wọn, ohun si ni ọjọ ti o wuwo; nitori awọn ile koko ati awọn idaamun ti o wa nibẹ.
نَّحۡنُ خَلَقۡنَٰهُمۡ وَشَدَدۡنَآ أَسۡرَهُمۡۖ وَإِذَا شِئۡنَا بَدَّلۡنَآ أَمۡثَٰلَهُمۡ تَبۡدِيلًا 28
Awa ni a da wọn, a si fun isẹda wọn ni agbara pẹlu fifun awọn isẹpo wọn ati awọn orikerike wọn ni agbara ati ohun ti o yatọ si i, ti a ba fẹ mu iparun ba wọn tabi jijiirọ wọn pẹlu apejuwe wọn, a o pa wọn run, a o si paarọ wọn.
إِنَّ هَٰذِهِۦ تَذۡكِرَةٞۖ فَمَن شَآءَ ٱتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلٗا 29
Dajudaju ọgba ọrọ yii jẹ isiti ati irannileti, ẹniti o ba fẹ igbamun oju ọna ti yoo mu de ibi iyọnu Ọlọhun rẹ, ki o gba a mun.
وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا 30
Ẹ ko le fẹ igbamun oju ọna lọsi ibi iyọnu Allah ayaafi ti Allah ba fẹ eleyi ni ọdọ yin, gbogbo ọrọ pata jẹ tiRẹ, dajudaju Allah jẹ onimimọ si ohun ti yoo se anfaani fun awọn ẹru Rẹ ati ohun ti ko le se wọn ni anfaani, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati ofin Rẹ.
يُدۡخِلُ مَن يَشَآءُ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ وَٱلظَّٰلِمِينَ أَعَدَّ لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمَۢا 31
Yoo fi ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ si inu ikẹ Rẹ, yoo si fi wọn se kongẹ igbagbọ ati isẹ rere, yoo si pese iya inira ni ọrun fun awọn ti wọn se abosi fun ẹmin ara wọn pẹlu keferi ati awọn ẹsẹ, ohun si ni iya ina.
سورة (MAKIYYAH)
Adehun iya fun awọn opurọ pẹlu wailu ni ọjọ igbende.
وَٱلۡمُرۡسَلَٰتِ عُرۡفٗا 1
Allah fi atẹgun ti o ntẹle ara wọn bura gẹgẹ bi amin awọn ẹsin.
فَٱلۡعَٰصِفَٰتِ عَصۡفٗا 2
O si tun fi awọn atẹgun ti o nfẹ gidigidi bura.
وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشۡرٗا 3
O si tun fi awọn atẹgun ti o nfan ojo bura.
فَٱلۡفَٰرِقَٰتِ فَرۡقٗا 4
O si tun fi awọn Malaaika ti o nsọkalẹ pẹlu ohun ti o nse onpinya laarin ododo ati ibajẹ bura.
فَٱلۡمُلۡقِيَٰتِ ذِكۡرًا 5
O si tun fi awọn Malaaika ti wọn nsọkalẹ pẹlu imisi bura.
عُذۡرًا أَوۡ نُذۡرًا 6
O nsọkalẹ pẹlu imisi titi wiwi awijare lati ọdọ Allah si awọn eniyan ati ikilọ fun awọn eniyan kuro nibi iya Allah.
إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٞ 7
Dajudaju ohun ti wọn se ni adehun pẹlu rẹ nipa ajinde ati isiro ati ẹsan yoo sẹlẹ, ti ko si ibuyẹ.
فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ 8
Nigbati wọn ba pa imọlẹ irawọ, ti itansan rẹ si lọ.
وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ 9
Nigbati sanmọ ba lanu nitori sisọkalẹ awọn malaika nibẹ.
وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ 10
Nigbati awọn oke ba di ohun ti wọn hu tiditidi ni aaye rẹ, ti wọn si fọ ti o fi di eruku.
وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتۡ 11
Nigbati wọn ba ko awọn ojisẹ jọ fun asiko ti o ni aala.
لِأَيِّ يَوۡمٍ أُجِّلَتۡ 12
Fun ọjọ ti o tobi, ti wọn kanju rẹ fun ẹri lori awọn ijọ rẹ.
لِيَوۡمِ ٱلۡفَصۡلِ 13
Fun ọjọ onpinya laarin awọn ẹru, ti ẹlẹtọ si han kuro ninu onibajẹ ati oloriire kuro ninu olori buruku.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ 14
Kinni o fi mọ ọ - irẹ ojisẹ - ohun ti ọjọ onpinya jẹ?!
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 15
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ yii jẹ ti awọn opurọ ti wọn npe ohun ti awọn ojisẹ mu wa lati ọdọ Allah nirọ.
أَلَمۡ نُهۡلِكِ ٱلۡأَوَّلِينَ 16
Se a ko mu iparun ba awọn ijọ ti wọn siwaju nigbati wọn se aimoore si Allah, ti wọn si pe awọn ojisẹ rẹ nirọ ni?!
ثُمَّ نُتۡبِعُهُمُ ٱلۡأٓخِرِينَ 17
Lẹyin naa a o fi awọn opurọ ninu ẹni ikẹyin tẹle wọn, a o si pa wọn run gẹgẹ bi a se mu iparun ba wọn.
كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ 18
Iru apejuwe iparun ti awọn ijọ naa ni a o fi pa awọn ẹlẹsẹ olupe ohun ti Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu wa nirọ run.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 19
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ yii jẹ ti olupe adehun iya Allah pẹlu fifi iya jẹ awọn ẹlẹsẹ.
Ewu sisọpọ mọ aye ati gbigbagbe ọrun.
Fifẹ ẹru yoo tẹle fifẹ ti Allah.
Mimu iparun ba awọn ijọ opurọ jẹ isesi Ọlọhun.