وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ذَرُونِيٓ أَقۡتُلۡ مُوسَىٰ وَلۡيَدۡعُ رَبَّهُۥٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمۡ أَوۡ أَن يُظۡهِرَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡفَسَادَ 26
Fir'aona wa sọpe: ẹ fi mi silẹ ki npa Musa ki o jẹ jijya fun un, ki o wa pe Ọlọhun Ọba rẹ ki o gba silẹ lọwọ Mi, emi ko ka ki o pe Ọlọhun rẹ kun, dajudaju mo npaya ki o ma yi ẹsin yin pada ti ẹ wa lori rẹ tabi ki o ma fi ibajẹ han si ori ilẹ pẹlu pipaniyan ati rirun awọn nkan.
وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِنِّي عُذۡتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرٖ لَّا يُؤۡمِنُ بِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ 27
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọ nigbati o mọ idẹruba fir'aona fun: dajudaju emi lugọ, mo si nwa idaabobo lọdọ Ọlọhun mi tii se Ọlọhun yin kuro ni ọdọ gbogbo olusegberaga nibi ododo ati igbagbọ si i, ti ko si nigbagbọ nipa ọjọ igbende ati isiro pẹlu iya eyiti o wa nibẹ.
وَقَالَ رَجُلٞ مُّؤۡمِنٞ مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَكۡتُمُ إِيمَٰنَهُۥٓ أَتَقۡتُلُونَ رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّيَ ٱللَّهُ وَقَدۡ جَآءَكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ مِن رَّبِّكُمۡۖ وَإِن يَكُ كَٰذِبٗا فَعَلَيۡهِ كَذِبُهُۥۖ وَإِن يَكُ صَادِقٗا يُصِبۡكُم بَعۡضُ ٱلَّذِي يَعِدُكُمۡۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ مُسۡرِفٞ كَذَّابٞ 28
Ọkunrin kan ti o jẹ olugbagbọ si Allah ninu awọn ara ile fir'aona, ti o fi igbagbọ rẹ pamọ fun awọn ijọ rẹ sọpe, ni ẹniti o nkorira ipinnu wọn lori pipa Musa: se ẹ o pa ọkunrin kan ti ko ni ẹsẹ ju wipe o sọpe: Allah ni Ọlọhun mi, paapaa o si ti mu awọn awijare ati awọn ẹri ti o tọka si ijẹ ododo rẹ nibi ohun ti npe apemọra rẹ wipe dajudaju o jẹ ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun rẹ?! Bi o ba ti lẹjẹ sipe o jẹ opurọ, inira irọ rẹ yoo sẹri lọ ba, ti o ba si jẹ olododo, apakan ohun ti wọn se ni adehun fun un ninu iya yoo sẹlẹ si yin ni kiakia, dajudaju Allah kii fi olukọja ẹnu aala ẹniti o nparọ mọ Ọ tabi mọ awọn ojisẹ Rẹ se kongẹ ododo.
يَٰقَوۡمِ لَكُمُ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَ ظَٰهِرِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَن يَنصُرُنَا مِنۢ بَأۡسِ ٱللَّهِ إِن جَآءَنَاۚ قَالَ فِرۡعَوۡنُ مَآ أُرِيكُمۡ إِلَّا مَآ أَرَىٰ وَمَآ أَهۡدِيكُمۡ إِلَّا سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ 29
Ẹyin ijọ mi, ti yin ni ikapa oni ni ẹniti yoo bori ni ilẹ Misirọ, taani yoo ran wa se kuro nibi iya Allah ti o ba wa ba wa lati ibi pipa Musa?! fir'aona sọpe: irori jẹ temi, bẹẹni idajọ jẹ idajọ mi, paapaa mo si ri wipe ki npa Musa; lati daabobo aburu ati ibajẹ naa, nko tọka yin si ibikankan ayaafi si ibi deedee ati dọgba.
وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُم مِّثۡلَ يَوۡمِ ٱلۡأَحۡزَابِ 30
Ẹniti o nigbagbọ sọrọ fun awọn ijọ rẹ niti sise isiti: ẹmi nbẹru le yin lori - ti ẹ ba pa Musa niti abosi ati ọta - iya kan gẹgẹ bi iya awọn ijọ eyiti wọn kora jọ lori ojisẹ wọn ninu awọn ẹni isaaju ti Allah si pa wọn run.
مِثۡلَ دَأۡبِ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۚ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلۡمٗا لِّلۡعِبَادِ 31
Gẹgẹ bi isesi ẹniti o se aimoore ti o si pe awọn ojisẹ nirọ bii ijọ Nuha ati Hadi ati Samuud ati awọn ti o wa lẹyin ti wọn, paapaa Allah ti pa wọn run nitori keferi ati pipe awọn ojisẹ Rẹ nirọ, bẹẹni ko gbero abosi fun awọn ẹru naa bikosepe o fi iya jẹ wọn nitori awọn ẹsẹ wọn; ni ẹsan ti o se deedee.
وَيَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ يَوۡمَ ٱلتَّنَادِ 32
Ẹyin ijọ mi, dajudaju emi bẹru le yin lori ni ọjọ igbende, ọjọ yii ni awọn eniyan yoo maa pariwo apakan wọn nitori asunmọ tabi iyi ni ẹniti o nrope ọna yii yoo se wọn ni anfaani ni aaye ibẹru yii.
يَوۡمَ تُوَلُّونَ مُدۡبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنۡ عَاصِمٖۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٖ 33
Ọjọ ti wọn yoo pẹyinda ni ẹniti nsaalọ niti ipaya kuro nibi ina, olukọdi kan ko si fun yin ti yoo kọ fun yin kuro nibi iya Allah, ẹniti Allah ba dagunla si, ti ko si fi se kongẹ igbagbọ ko si olumọna kan fun un ti o le fi mọ ọna; nitoripe dajudaju imọna kongẹ wa lọ ọwọ Allah nikan soso.
lilugọ olugbagbọ ododo si ọdọ Ọlọhun rẹ ki o le daabobo kuro nibi ete awọn ọta rẹ.
Titọ pipa igbagbọ mọ nitori anfaani kan eyiti o bori tabi titi ibajẹ danu.
Titi isiti fun awọn eniyan siwaju wa ninu awọn iroyin ẹni igbagbọ.