ٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُخۡرِجُهُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَوۡلِيَآؤُهُمُ ٱلطَّٰغُوتُ يُخۡرِجُونَهُم مِّنَ ٱلنُّورِ إِلَى ٱلظُّلُمَٰتِۗ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 257
Ọlọhun Ọba Allah yoo maa se amojuto awọn ti o ba ni igbagbọ pẹlu Rẹ, Yoo si maa fi se kongẹ, Yoo si tun maa ran wọn se, ati wipe Yoo si tun maa yọ wọn kuro ninu okunkun aigbagbọ ati aimọkan lọ si inu imọlẹ igbagbọ ati imọ, ati wipe alaigbagbọ awọn aayo wọn ni awọn nkan ti wọn mu ni orogun pọ mọ Ọlọhun ati awọn oosa, awọn ti wọn se aigbagbọ ni ọsọ fun wọn, nitorinaa ni wọn fi wa yọ wọn kuro ninu imọlẹ igbagbọ ati imọ, lọ si inu okunkun aigbagbọ ati aimọkan. Awọn naa ni awọn ara ile ina, wọn yoo si maa gbe ibẹ lọ gbere.
Ati wipe nigbati Ọlọhun Ọba Allah darukọ awọn ikọ meji naa, O fi apejuwe meji lelẹ lori ikọ mejeeji, ni O fi wa sọ bayi wipe:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِي حَآجَّ إِبۡرَٰهِۧمَ فِي رَبِّهِۦٓ أَنۡ ءَاتَىٰهُ ٱللَّهُ ٱلۡمُلۡكَ إِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِۧمُ رَبِّيَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا۠ أُحۡيِۦ وَأُمِيتُۖ قَالَ إِبۡرَٰهِۧمُ فَإِنَّ ٱللَّهَ يَأۡتِي بِٱلشَّمۡسِ مِنَ ٱلۡمَشۡرِقِ فَأۡتِ بِهَا مِنَ ٱلۡمَغۡرِبِ فَبُهِتَ ٱلَّذِي كَفَرَۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 258
Njẹ o ko wa ri - irẹ Anọbi - eemọ nibi ise akin olugbẹrugbọnri, ẹniti Ibraheem (ki ọla maa jẹ tirẹ) jiyan nibi jijẹ ti Allah jẹ Ọba, ati nibi sise ni ọkan soso, atipe dajudaju nkan naa sẹlẹ lati ọdọ rẹ nitoripe Ọlọhun Ọba Allah fun ni ọla, ni o fi gbẹru-gbọnri, Ibraheem waa salaye fun un, awọn iroyin Ọlọhun Ọba rẹ ni ẹni ti nsọ pe: Ọlọhun Ọba mi ni Ẹniti O ma nmu awọn ẹda bẹ ni abẹmi, ti O si tun ma npa wọn, olugbẹrugbọnri naa waa sọ niti sise orikunkun bayi wipe: emi ma nye, mo si tun ma npa, pẹlu wipe ki npa ẹniti mo ba fẹ, mo si ma nmojukuro ni ọdọ ẹniti mo ba fẹ, Ibraheem (ki ọla maa jẹ tirẹ) tun wa mu ẹri miran ti o tobi ju wa, o sọ fun wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba mi eyi ti mo njọsin fun, ni O ma nmu oorun wa lati agbegbe ila-oorun, iwọ naa mu wa lati igbegbe ibuwọ-oorun, ko wa si nkan ti o de ba olugbẹru-gbọnri naa ju ikagara ati ijakan-muna, o di ẹniti wọn bori rẹ pẹlu ẹri ti o lagbara ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi alabosi se kongẹ itẹle oju-ọna Rẹ; nitori abosi ati igbẹru-gbọnri wọn.
أَوۡ كَٱلَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرۡيَةٖ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحۡيِۦ هَٰذِهِ ٱللَّهُ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۖ فَأَمَاتَهُ ٱللَّهُ مِاْئَةَ عَامٖ ثُمَّ بَعَثَهُۥۖ قَالَ كَمۡ لَبِثۡتَۖ قَالَ لَبِثۡتُ يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۖ قَالَ بَل لَّبِثۡتَ مِاْئَةَ عَامٖ فَٱنظُرۡ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمۡ يَتَسَنَّهۡۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجۡعَلَكَ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِۖ وَٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡعِظَامِ كَيۡفَ نُنشِزُهَا ثُمَّ نَكۡسُوهَا لَحۡمٗاۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥ قَالَ أَعۡلَمُ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 259
Njẹ o ko waa ri apejuwe ẹniti nrekọja ni abule kan, ti gbogbo aja rẹ ti ja bọ, ti awọn ogiri rẹ si ti da wo, ti awọn olugbe inu rẹ naa ti parẹ tan, ti o wa pada di aayun ati nkan ti ko si nkankan lori rẹ mọ, ọkunrin yii waa sọ bayi ni ẹniti nseemọ: Bawo ni Ọlọhun Ọba Allah se fẹ gbeawon ara ilu yii dide lẹyin igbati won ti ku? ! Ni Ọlọhun Ọba Allah waa pa fun ọgọrun ọdun, lẹyin naa O jii pada, O wa bi leere, O si sọ fun un wipe: igba melo ni o lo ni oku? O waa sọ ni ẹniti nda lohun wipe: mo lo ọjọ kan tabi idaji ọjọ, O sọ fun: paapaa o lo ọgọrun ọdun ti o pe, boju wo nkan ti o wa pẹlu rẹ ninu ounjẹ ati nkan mimu, woo o si wa lori isesi rẹ, ti ko si yi pada, ti o si jẹ wipe nkan ti o yara bajẹ ti o si yara yipada julọ ni ounjẹ ati nkan mimu; boju wo kẹtẹkẹtẹ rẹ ti o ti di oku, lati le fi ọ se amin ti o han fun awọn eniyan, ti yoo si maa da lori agbara Ọlọhun Ọba Allah, lori gbigbe wọn dide, boju wo egungun kẹtẹkẹtẹ rẹ eleyi ti o ti tan ka, ti o si ti jinna si ara wọn, bawo ni A se fẹ gbe dide, ti A o si so apakan rẹ pọ mọ apakan, lẹyin naa ti A o si tun fi ẹran bo o lẹyin nkan naa, ati wipe A o si da isẹmin pada si lara, nigbati o wa ri nkan naa, alamọri ododo wa han si, o wa mọ agbara Ọlọhun, ni o fi wa sọ ni ẹni ti njẹwọ pẹlu nkan wipe: mo wa nmọ pe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Alagbara lori gbogbo nkan.
Ninu ohun ti o tobi julọ, ti o ma nse iyatọ awọn olugbagbọ ododo ni wipe dajudaju wọn wa lori imọna ati iriran lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ninu gbogbo isesi wọn tii se ti ẹsin ati ti aye, eleyi ti o yatọ si ti awọn alaigbagbọ.
Ninu awọn okunfa ẹgbẹrubọnri ti o tobi julọ ni gbigba itanjẹ pẹlu agbara ati ipo, titi ti ọmọniyan yoo fi fọju kuro nibi paapaa isesi rẹ.
Sise mima ba awọn ẹni-anu fọrọjomitoro ọrọ lofin lati se alaye ododo, ati lati si gaga kuro nibi anu wọn nibi ọnaamọ.
Titobi agbara Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ko si nkan ti o le da lagara, lara rẹ naa ni sisọ oku di alaaye.