۞تِلۡكَ ٱلرُّسُلُ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۘ مِّنۡهُم مَّن كَلَّمَ ٱللَّهُۖ وَرَفَعَ بَعۡضَهُمۡ دَرَجَٰتٖۚ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلَ ٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ وَلَٰكِنِ ٱخۡتَلَفُواْ فَمِنۡهُم مَّنۡ ءَامَنَ وَمِنۡهُم مَّن كَفَرَۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلُواْ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ 253
Awọn wọnyi ni awọn ojisẹ ti A sọ fun ọ nipa wọn, A gbe ọla fun apakan lori apakan nipa iransẹ, ati awọn olutẹle, ati awọn ipo, ninu wọn ni ẹniti Ọlọhun Ọba Allah ba sọrọ gẹgẹ bi Anọbi Musa (ki ọla Ọlọhun maa ba) , atipe ninu wọn ni ẹniti Ọlọhun Ọba Allah gbe ga ni awọn ipo ti o ga gẹgẹ bi Anọbi Muhammad (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun) ; nigbati wọn ran si gbogbo eniyan patapata, ti wọn si se ni opin awọn Anọbi, ti wọn si gbe ọla fun awọn ijọ rẹ lori gbogbo awọn ijọ yoku, atipe A fun Anọbi Isa ọmọ Maryam ni oun ariseemọ ti o han (isẹ iyanu) eyi ti nda lori jijẹ Anọbi rẹ; gẹgẹ bi jiji oku dide, ati lilaju afọju, ati wiwo adẹtẹ san, ati wipe A se ikunlọwọ fun un pẹlu Jibreel (ki ọla Ọlọhun maa ba) , ni riro ni agbara lati le ba gbe asẹ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) duro. Ti Ọlọhun Ọba Allah ba fẹ ni, awọn ti wọn de lẹyin awọn ojisẹ, lẹyin igbati awọn amin ti o fi oju han wa de ba wọn, wọn ko ba ti ba ara wọn ja, sugbọn wọn yapa ni wọn se pin, o nbe ninu wọn ẹniti o gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ, o si tun nbẹ ninu wọn ẹniti ko gba A gbọ, ti Ọlọhun Ọba Allah ko ba fẹ ki wọn ba ara wọn ja, wọn ko ni ba ara wọn ja, sugbọn Ọlọhun Ọba Allah ma nse oun ti o wu U, ni O fi ma nfi ẹniti o ba wu mọ ọna lọ si ibi igbagbọ pẹlu ikẹ Rẹ ati ọla Rẹ, ati wipe yoo si maa si ẹniti o ba wu U lọna pẹlu deede Rẹ ati oye Rẹ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنفِقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا بَيۡعٞ فِيهِ وَلَا خُلَّةٞ وَلَا شَفَٰعَةٞۗ وَٱلۡكَٰفِرُونَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 254
Mo pe awọn ti wọn gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ, ti wọn si tun tẹle ojisẹ Rẹ, ẹ maa nan ninu nkan ti A pese fun yin ninu awọn oniranran owo ti o jẹ ẹtọ siwaju ki Ọjọ Igbende too de, nigba naa, ko nii si katakara ti ọmọniyan le ri anfaani ko jọ lati ara rẹ, ati wipe ko nii si ijọrẹ ti yoo se ni anfaani ni igba ilekoko, ko si nii si alagata ti o le kọdi inira kankan, tabi ti o le mu anfaani kan wa ayaafi lẹyin igbati Ọlọhun Ọba Allah ba yọnda fun ẹniti O ba fẹ, ti O si tun yọnu si, ati wipe awọn alaigbagbọ alabosi ni wọn l’ododo, nitori aini igbagbọ wọn si Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga.
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُۚ لَا تَأۡخُذُهُۥ سِنَةٞ وَلَا نَوۡمٞۚ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ مَن ذَا ٱلَّذِي يَشۡفَعُ عِندَهُۥٓ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيۡءٖ مِّنۡ عِلۡمِهِۦٓ إِلَّا بِمَا شَآءَۚ وَسِعَ كُرۡسِيُّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۖ وَلَا ئَُودُهُۥ حِفۡظُهُمَاۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ 255
Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti ko si ọlọhun ọba kankan ti wọn yoo maa jọsin fun ni tootọ ayaafi Oun nikan soso, yatọ si ẹniti o yatọ si, Olusẹmi ni ni isẹmi kan ti o pe perepere, ti ko si iku nibẹ ati adinku, Oludawa ni, ẹniti o da wa fun ara Rẹ ni, ni O fi rọrọ kuro lọdọ gbogbo ẹda Rẹ, ati wipe pẹlu Rẹ ni gbogbo awọn ẹda Rẹ fi nbẹ, ti wọn ko si lee rọrọ kuro ni ọdọ Rẹ, ninu gbogbo awọn isesi wọn, kii toogbe, bẹẹ si ni kii sun rara; nitori pipe isẹmi Rẹ ati didawa Rẹ, tiRẹ nikan soso ni ọla ohun ti nbẹ ninu awọn sanmọ ati ohun ti nbẹ ni inu ilẹ se, ẹnikankan ko ni ikapa lati se ipẹ fun ẹlomiran ni ọdọ Rẹ, ayaafi lẹyin iyọnda Rẹ ati iyọnu Rẹ. Oun ni O mọ nkan ti o ti re kọja ninu awọn alamọri ẹda Rẹ, ninu awọn nkan ti o ti sẹlẹ, ati ohun ti wọn dojukọ ninu nkan ti ko tii sẹlẹ, ati wipe wọn ko ni le rọkirika nkankan ninu imọ Rẹ (ti ọla Rẹ ga) ayaafi ohun ti O ba fẹ lati fi han wọn lori rẹ, Aga Rẹ rọkirika - ohun naa ni aaye ẹsẹ Ọlọhun Ọba Allah mejeeji - awọn sanmọ ati ilẹ lori gbigbaaye mejeeji ati titobi mejeeji, atipe sisọ awọn mejeeji ko le wuwo fun Un tabi le koko fun Un ko aarẹ ba, Oun ni Ọba ga fun ara Rẹ, ati agbara Rẹ, ati ibori Rẹ. Ọba titobi ninu ọla Rẹ ati agbara Rẹ.
لَآ إِكۡرَاهَ فِي ٱلدِّينِۖ قَد تَّبَيَّنَ ٱلرُّشۡدُ مِنَ ٱلۡغَيِّۚ فَمَن يَكۡفُرۡ بِٱلطَّٰغُوتِ وَيُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱسۡتَمۡسَكَ بِٱلۡعُرۡوَةِ ٱلۡوُثۡقَىٰ لَا ٱنفِصَامَ لَهَاۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ 256
Ko si ijẹninipa fun ẹnikankan lori wiwọ inu ẹsun Islam; toripe ohun ni ẹsin ododo ti o han, ni ko fi bukaata kankan lọ si ibi jijẹ ẹnikankan nipa lori rẹ, paapaa imọna yatọ si aanu, nitori naa ẹniti o ba ti se aigbagbọ pẹlu gbogbo nkan ti wọn jọsin fun lẹyin Ọlọhun Ọba Allah, ti o si tun bọpabọsẹ kuro nibẹ, ti o wa gba Ọlọhun gbọ ni Oun nikan soso; paapaa o ti dirọ mọ ẹsin pẹlu okunfa ti o lagbara julọ, ti ko ni ja lati yege ni ọjọ igbende, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah, Olugbọ awọn ọrọ ẹda Rẹ ni, Olumọ awọn isẹ wọn ni, ti Yoo si pada san wọn ni ẹsan le lori.
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ti da ọla laarin awọn ojisẹ Rẹ ati awọn Anọbi Rẹ, pẹlu imọ Rẹ ati oye Rẹ, mimọ fun Un.
Ifirinlẹ iroyin ọrọ sisọ fun Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) lori nkan ti o lẹtọ si gbigbọngbọn Rẹ, ati wipe dajudaju Ohun ni paapaa ti ba apakan awọn ojisẹ Rẹ sọrọ, gẹgẹ bi Musa ati Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla maa ba awọn mejeeji) .
Igbagbọ, ati imọna, ati aigbagbọ, ati aanu, gbogbo rẹ labẹ fifẹ Ọlọhun Ọba Allah ni ati ayanmọ Rẹ, nitorinaa ti Rẹ ni ọgbọn ati oye ti o jindo o se e, ti O ba fẹ, ki ba fi gbogbo ẹda mọna.
Ayatul Kurisiyy ohun naa ni aayah ti o tobi ju ninu iwe Ọlọhun Ọba Allah (Alukuraani) , nipa awọn nkan ti o ko sinu, ninu jijẹ Ọba ti Ọlọhun Ọba Allah jẹ, ati jijẹ eniti o leto lati se ijosin fun ati alaye awọn iroyin Rẹ.
Titẹle ẹsin alaafia ati wiwọ inu rẹ, yẹ ko jẹ ọranyan lati ibi iyọnu ati gbigba, ko si ijẹninipa ninu ẹsin Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .
Gbigba tira Ọlọhun Ọba Allah ati ilana ojisẹ Rẹ mu, ni atẹgun ti o tobi ju fun oriire ni ile aye ati erenjẹ ni ọjọ ikẹyin.