إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونِۢ 25
Ayaafi awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se awọn isẹ rere, ẹsan ti ko nii ja nbẹ fun wọn; ohun si ni ọgba idẹra naa.
سورة (MAKIYYAH)
Sise afihan agbara Allah ati kikari imọ Rẹ ti o kun ati adehun iya Rẹ ti o le fun awọn ti wọn nsọ awọn olugbagbọ ododo lọwọ lẹsẹ.
وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡبُرُوجِ 1
Allah fi sanmọ ti o kun fun awọn aaye oorun ati awọn aaye osupa ati ohun ti o yatọ si mejeeji bura.
وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡمَوۡعُودِ 2
O si tun fi ọjọ igbende ti o se adehun lati ko awọn ẹda jọ nibẹ bura.
وَشَاهِدٖ وَمَشۡهُودٖ 3
O si fi gbogbo ẹlẹri gẹgẹ bi anọbi ti yoo jẹri lori awọn ijọ rẹ ati gbogbo ohun ti a jẹri le lori gẹgẹ bi awọn ijọ ti wọn yoo jẹri lori anọbi wọn bura.
قُتِلَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأُخۡدُودِ 4
Wọn sẹbi le awọn ti wọn gbẹ iho ni ilẹ niti gbigbẹ ti o tobi.
ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلۡوَقُودِ 5
Wọn si ko ina nibẹ, wọn si ju awọn olugbagbọ ododo nibẹ ni aaye.
إِذۡ هُمۡ عَلَيۡهَا قُعُودٞ 6
Ni ẹniti o njoko ni inu iho ti o kun fun ina yii.
وَهُمۡ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ شُهُودٞ 7
Wọn si jẹ ẹlẹri lori ohun ti awọn olugbagbọ ododo nse nipa ifiyajẹni ati ifulẹmọni; nitori pipesẹ wọn nibẹ.
وَمَا نَقَمُواْ مِنۡهُمۡ إِلَّآ أَن يُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ 8
Awọn keferi yii ko bu awọn olugbagbọ ododo kankan ayaafi nitoripe wọn nigbagbọ si Allah alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, Ẹni ẹyin nibi gbogbo nkan.
ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ 9
Ẹniti inikapa gbogbo sanmọ ati inikapa ilẹ jẹ tiRẹ nikan, Oun ni ẹniti o nri gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun ni ọdọ awọn ẹru Rẹ.
إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُواْ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَتُوبُواْ فَلَهُمۡ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمۡ عَذَابُ ٱلۡحَرِيقِ 10
Dajudaju awọn ti o fi iya ina jẹ awọn olugbagbọ ododo lọkunrin ati awọn olugbagbọ ododo lobinrin ki wọn le mu wọn kuro nibi igbagbọ si Allah nikan soso, lẹyin naa ti wọn ko si ronu piwada lọsi ọdọ Allah kuro nibi awọn ẹsẹ wọn, iya ina jahannamọ nbẹ fun wọn ni ọjọ igbende, bakannaa ni iya ina eyiti yoo jo wọn nbẹ fun wọn; ni ẹsan lori ohun ti wọn se fun awọn olugbagbọ ododo nipa jijowọn ni ina.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ جَنَّٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡكَبِيرُ 11
Dajudaju awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si se awọn isẹ rere, ọgba idẹra ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ati awọn igi rẹ nbẹ fun wọn, ẹsan yii ti wọn tọju fun wọn ni erenjẹ ti o tobi, ti erenjẹ kankan ko sun mọ ọ.
إِنَّ بَطۡشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ 12
Dajudaju igbamun Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - fun alabosi –koda bi o lọ ọ lara fun asiko kan- jẹ alagbara.
إِنَّهُۥ هُوَ يُبۡدِئُ وَيُعِيدُ 13
Dajudaju Oun ni O pilẹ isẹda ati iya, yoo si da mejeji pada.
وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلۡوَدُودُ 14
Oun ni oluforijin awọn ẹsẹ ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, dajudaju O si nifẹ si awọn ẹni tiRẹ ninu awọn olupaya Ọlọhun.
ذُو ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡمَجِيدُ 15
Oni aga alaarasi ti o lapọnle.
فَعَّالٞ لِّمَا يُرِيدُ 16
Oluse ohun ti O ba fẹ ninu amojukuro awọn ẹsẹ ẹniti o ba fẹ, olufiyajẹ ẹniti o ba fẹ, ẹnikankan ko le jẹ Oun ti mimọ nbẹ fun nipa.
هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡجُنُودِ 17
Njẹ o ti wa ba ọ - irẹ ojisẹ - iro awọn ọmọ ogun ti o dira lati ba ododo ja, ti wọn si di lọna?!
فِرۡعَوۡنَ وَثَمُودَ 18
Fir'aona ati samuudu tii se awọn eniyan Sọlihu ti ọla nbẹ fun.
بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي تَكۡذِيبٖ 19
Nkankan ko kọ fun igbagbọ awọn eniyan wọnyi lori wipe iro awọn ijọ ti wọn npurọ ko waa ba wọn ati iparun ti o sẹlẹ si wọn bikosepe wọn pe ohun ti ojisẹ wọn mu wa ba wọn nirọ niti titẹle awọn ifẹ inu wọn.
وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطُۢ 20
Allah si jẹ ẹniti imọ Rẹ rọkirika wọn, ti O si nmojuto, nkankan ko bọ mọ lọwọ nibẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
بَلۡ هُوَ قُرۡءَانٞ مَّجِيدٞ 21
Alukuraani kii se orin tabi ẹdin ọrọ gẹgẹ bi awọn opurọ se nsọ bikosepe o jẹ Alukuraani alapọnle.
فِي لَوۡحٖ مَّحۡفُوظِۢ 22
Ninu awọn ọpọn ti a daabobo kuro nibi ijiirọ ati iyipada ati ẹdin ati alekun.
Adanwo olugbagbọ ododo yoo maa bẹ ni ibamun si odinwọn igbagbọ rẹ.
Gbigbe ọla fun lila igbagbọ lori lila ara wa ninu awọn amin ọla ni ọjọ igbende.
Ironu piwada pẹlu awọn majẹmu rẹ ma nti ohun ti o siwaju rẹ danu.