لَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلَنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَنزَلۡنَا مَعَهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡمِيزَانَ لِيَقُومَ ٱلنَّاسُ بِٱلۡقِسۡطِۖ وَأَنزَلۡنَا ٱلۡحَدِيدَ فِيهِ بَأۡسٞ شَدِيدٞ وَمَنَٰفِعُ لِلنَّاسِ وَلِيَعۡلَمَ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥ وَرُسُلَهُۥ بِٱلۡغَيۡبِۚ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٞ 25
Paapaa a ti ran awọn ojisẹ wa pẹlu awọn ẹri ti o fi oju han ati awọn awọn awijare ti o gbọngbọn, a si sọ awọn ti ra kalẹ pẹlu wọn, a si tun sọ awọn osunwọn kalẹ pẹlu wọn; ki awọn eniyan le wa pẹlu deedee, a si sọ irin kalẹ nibẹ ti agbara ti o le koko wa nibẹ, nibẹ ni wọn ti nse nkan ija, anfaani fun awọn eniyan nibi ohun ti wọn se ati isẹ ọwọ wọn wa nibẹ ati ki Allah le fi imọ han awọn ẹru ninu awọn ti yoo se aranse fun Un ni kọkọ ninu awọn olujọsin fun Un, dajudaju Allah jẹ alagbara oniyi ti nkankan ko le bori Rẹ, ko si kagara nipa ohunkihun.
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحٗا وَإِبۡرَٰهِيمَ وَجَعَلۡنَا فِي ذُرِّيَّتِهِمَا ٱلنُّبُوَّةَ وَٱلۡكِتَٰبَۖ فَمِنۡهُم مُّهۡتَدٖۖ وَكَثِيرٞ مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ 26
Paapaa a si ran Nuha ati Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun nisẹ, a si fi awọn ijẹ anọbi si inu awọn arọmọdọmọ wọn ati awọn tira ti A sọkalẹ, olumọna lọsi oju ọna ti o duro tọ wa ninu awọn arọmọdọmọ wọn, ti o jẹ ẹni kongẹ bẹẹni ọpọ ninu wọn jade kuro nibi itẹle ti Allah.
ثُمَّ قَفَّيۡنَا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم بِرُسُلِنَا وَقَفَّيۡنَا بِعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡإِنجِيلَۖ وَجَعَلۡنَا فِي قُلُوبِ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ رَأۡفَةٗ وَرَحۡمَةٗۚ وَرَهۡبَانِيَّةً ٱبۡتَدَعُوهَا مَا كَتَبۡنَٰهَا عَلَيۡهِمۡ إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ رِضۡوَٰنِ ٱللَّهِ فَمَا رَعَوۡهَا حَقَّ رِعَايَتِهَاۖ فََٔاتَيۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنۡهُمۡ أَجۡرَهُمۡۖ وَكَثِيرٞ مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ 27
Lẹyin naa a fi awọn ojisẹ Wa tẹle wọn, A si gbe wọn dide ni ẹniti o ntẹle ara wọn ninu awọn ijọ wọn, A si fi Isa ọmọ Maryam tẹle wọn, bẹẹni A fun ni Injiila, A si fi aanu ati ikẹ si inu ọkan awọn ti wọn nigbagbọ si i, ti wọn si tẹle e, wọn wa di olufẹran ara wọn onikẹ si ara wọn, wọn si pilẹ ikọja aala ninu ẹsin wọn, wọn wa gbe apakan ohun ti Allah se lẹtọ fun wọn nibi ifẹra ẹni ati igbadun ju silẹ, bẹẹni a ko beere eleyi ni ọdọ wọn, bikosepe awọn ni wọn sọ di ọranyan lori ara wọn ni ipilẹ lati ọdọ wọn ninu ẹsẹ, ohun ti a fẹ lọdọ wọn ni iyọnu Allah sugbọn wọn ko se e, A si fun awọn ti wọn nigbagbọ ninu wọn ni ẹsan wọn, ọpọ ninu wọn jade kuro nibi itẹle ti Allah pẹlu pipe ohun ti ojisẹ Rẹ tii se Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun mu wa fun wọn nirọ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَءَامِنُواْ بِرَسُولِهِۦ يُؤۡتِكُمۡ كِفۡلَيۡنِ مِن رَّحۡمَتِهِۦ وَيَجۡعَل لَّكُمۡ نُورٗا تَمۡشُونَ بِهِۦ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 28
Mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse ohun ti wọn se lofin fun wọn, ẹ paya Allah pẹlu ki ẹ maa se ohun ti o pa lasẹ ati ijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si nigbagbọ si ojisẹ Rẹ, yoo fun yin ni ipin meji ninu ẹsan ati ẹsan lori igbagbọ yin si Muhammad ti ikẹ ati ọlanbẹ fun ati igbagbọ yin si awọn ojisẹ ti o siwaju, yoo si se imọlẹ ti ẹ o maa fi mọna ninu isẹmin aye yin fun yin, ti ẹ o fi maa ri maa ri imọlẹ lọ si oju ọna ni ọjọ igbende, yoo si se amojukuro awọn ẹsẹ yin, yoo basiri rẹ, ko si nii gbayin mu pẹlu rẹ, Allah ti mimọ nbẹ fun jẹ oluforijin ni fun awọn ẹru Rẹ, onikẹ si wọn.
لِّئَلَّا يَعۡلَمَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ أَلَّا يَقۡدِرُونَ عَلَىٰ شَيۡءٖ مِّن فَضۡلِ ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلۡفَضۡلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ 29
Paapaa a si ti se alaye ọla Wa ti o tobi fun yin pẹlu ohun ti A pese fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - gẹgẹ bi adipele ẹsan; ki awọn ti a fun ni tira siwaju gẹgẹbbi yahuudi ati nasaara le mọ wipe awọn ko nikapa lori ohunkihun ninu ọla Allah ti wọn yoo fi wa maa ta ẹniti o ba wu wọn lọrẹ, ti wọn yoo si maa kọ ọ fun ẹniti o ba wu wọn, ati ki wọn le ba mọ wipe dajudaju ọla naa wa ni ọwọ Allah ti mimọ nbẹ fun, O ma nfun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ, Allah si jẹ ọlọla ti o tobi eyiti o ma nsẹsa rẹ fun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ.
Ododo jẹ ohun ti ko gbọdọ ma ni agbara ti yoo daabobo o, ti yoo si maa fan ka.
Sise alaye ipo deedee ninu awọn ofin sanmọ.
Isopọ mọlẹbi pẹlu awọn ẹni igbagbọ ati atunse ko le rọrọ kankan fun ọmọniyan nigbati ko ba jẹ olugbagbọ ododo.
Sise alaye jijẹ eewọ sise adadaaalẹ ninu ẹsin.