مَا لَكُمۡ لَا تَنَاصَرُونَ 25
Wọn yoo maa sọ niti eebu fun wọn: e wo lo se yin ti apakan yin ko ran apakan se gẹgẹ bi ẹ se ma nranra yin lọwọ ni ile aye, ti ẹ si nlero wipe awọn oosa yin yoo ran yin lọwọ?
بَلۡ هُمُ ٱلۡيَوۡمَ مُسۡتَسۡلِمُونَ 26
Bikosepe awọn ti di ẹni idari sibi asẹ Allah ni ẹni yẹpẹrẹ loni, apakan wọn ko le ran apakan se nitori kikagara wọn ati kikere ete wọn.
وَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ 27
Apakan wọn kọju si apakan ti wọn si nbu ara wọn, ti wọn si nja nigbati iburaẹni ati ibanija ko le se anfaani mọ.
قَالُوٓاْ إِنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَأۡتُونَنَا عَنِ ٱلۡيَمِينِ 28
Awọn olutẹle yoo wa sọ fun awọn ti wọn tẹle: dajudaju ẹyin - agbalagba inu wa - ẹ nwa ba wa ni ojupọnna ẹsin ati ododo, ẹ wa nse keferi ati ẹbọ si Allah lọsọ fun wa ati igunle awọn ẹsẹ, bẹẹni ẹ si nle wa kuro nibi ododo eyiti awọn ojisẹ lati ọdọ Allah mu wa fun wa.
قَالُواْ بَل لَّمۡ تَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ 29
Awọn ti wọn ntẹẹle yoo sọ fun awọn olukọse: ọrọ ko ri - bi ẹ se nlero - bikosepe ẹ wa lori keferi, ẹ ko jẹ olugbagbọ ododo, ẹ si jẹ alatako.
وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيۡكُم مِّن سُلۡطَٰنِۢۖ بَلۡ كُنتُمۡ قَوۡمٗا طَٰغِينَ 30
Awa kii se ẹniti o jẹni nipa ijẹgaba tabi bori fun yin ẹyin olukọse ti a o wa fi mu yin wọ inu keferi ati ẹbọ ati dida awọn ẹsẹ bikojẹpe ẹ jẹ ijọ ti o nkọja ẹnu aala nibi keferi ati anu.
فَحَقَّ عَلَيۡنَا قَوۡلُ رَبِّنَآۖ إِنَّا لَذَآئِقُونَ 31
Ti adehun iya Allah fi waa jẹ dandan le awa ati ẹyin lori nibi gbolohun Rẹ (لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكَ وَمِمَّن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ أَجۡمَعِينَ) (emi yoo fi ọ kun inu ina jahannamọ ati ẹniti o ba tẹ le ọ lapapọ) (oju ewe: 85) lati igba yii ni awa yoo ti jẹ olutọọ wo - ko si ibuyẹ - ohun ti Ọlọhun Ọba wa se ni adehun rẹ.
فَأَغۡوَيۡنَٰكُمۡ إِنَّا كُنَّا غَٰوِينَ 32
A pe yin sibi anu ati keferi dajudaju awa ti jẹ olusina kuro ni oju ọna imọna.
فَإِنَّهُمۡ يَوۡمَئِذٖ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ 33
Dajudaju alawokọse ati awọn ti wọn ntẹẹle, wọn yoo papọ nibi iya ni ọjọ igbende.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ 34
Dajudaju bi a se si awọn ti a fun ni iya tọ wo, ni a o se pẹlu awọn ẹlẹsẹ ti o yatọ si wọn.
إِنَّهُمۡ كَانُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ يَسۡتَكۡبِرُونَ 35
Dajudaju awọn ẹlẹbọ wọnyi ti wọn ba sọ fun wọn ni ile aye wipe: ko si ọba kan ayaafi Allah, lati le se ohun ti o ko sinu ati gbe ohun ti o yatọ si ju silẹ, wọn tako jijẹpe fun un ati titẹriba fun un niti isegberaga kuro nibi ododo ati jijara ẹni loju le lori.
وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُوٓاْ ءَالِهَتِنَا لِشَاعِرٖ مَّجۡنُونِۢ 36
Wọn wa nsọ ni ẹniti o nwi awijare fun keferi wọn: se a o gbe ijọsin fun awọn Ọlọhun Ọba wa ju silẹ ni nitori ọrọ kọrin kọrin were?! ẹniti wọn gba lero pẹlu gbolohun yii ni ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
بَلۡ جَآءَ بِٱلۡحَقِّ وَصَدَّقَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 37
Wọn ti gbe titobi fun adapa irọ, ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun kii se were bẹẹni kii se akọrin, bikosepe o wa pẹlu Alukuraani ti npepe lọ si ibi ọkan soso Allah ati itẹle ojisẹ Rẹ, wọn si npe awọn ojisẹ lododo nibi ohun ti wọn mu wa lati ọdọ Allah gẹgẹ bi mimọ Ọlọhun Ọba lọkan ati fifi isẹrisi rinlẹ, wọn ko si yapa wọn nibi nkankan.
إِنَّكُمۡ لَذَآئِقُواْ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَلِيمِ 38
Dajudaju ẹyin - ẹyin ẹlẹbọ - ẹ o tọ iya oninira naa wo ni ọjọ igbende nitori keferi yin ati pipe awọn ojisẹ nirọ.
وَمَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 39
Wọn ko san yin lẹsan - ẹyin ẹlẹbọ - ayaafi ohun ti ẹ se ni ile aye gẹgẹ bi sise keferi si Allah ati dida awọn ẹsẹ.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ 40
Sugbọn awọn ẹru Allah ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, ti Allah sa wọn lẹsa fun ijọsin Rẹ, ti wọn si se afọmọ ijọsin wọn fun Un, awọn ni ẹniti yoo la nibi iya naa.
أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ رِزۡقٞ مَّعۡلُومٞ 41
Awọn ẹru wọnyi ti wọn jẹ olusafọmọ arisiki ti Allah yoo ran wọn se nbẹ fun wọn, ti didun rẹ ati didara rẹ ati lilọ gbere rẹ jẹ ohun ti a mọ.
فَوَٰكِهُ وَهُم مُّكۡرَمُونَ 42
Arisiki yii jẹ oniranran awọn ipapanu ti o dun ju ohun ti wọn njẹ lọ, ti wọn si njẹran rẹ lọ, wọn si tun jẹ ẹni apanle kọja eleyi pẹlu gbigbe awọn ipo wọn ga ati biboju wo oju Allah ti o jẹ alapọnle. s
فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ 43
Gbogbo eleyi ni ọwọ wọn yoo tẹ ninu awọn ọgba idẹra eyiti yoo maa bẹ, ti o si rinlẹ, ti ko nii ja, ti ko si nii yẹ.
عَلَىٰ سُرُرٖ مُّتَقَٰبِلِينَ 44
Wọn yoo rọgbọku lori awọn ibusun ti o kọju si ara wọn, ti apakan wọn yoo maa wo apakan.
يُطَافُ عَلَيۡهِم بِكَأۡسٖ مِّن مَّعِينِۢ 45
Wọn yoo maa gbe awọn ife ọti yipo wọn eyiti mimọ rẹ da gẹgẹ bi oimn ti o nsan.
بَيۡضَآءَ لَذَّةٖ لِّلشَّٰرِبِينَ 46
Ti awọ rẹ funfun, ti igbadun nbẹ nibi mimu rẹ fun ẹniti o ba mu u fun adun ti o pe.
لَا فِيهَا غَوۡلٞ وَلَا هُمۡ عَنۡهَا يُنزَفُونَ 47
Koda gẹgẹ bi ọti ile aye, ko si si ohun ti o le mu laakaye lọ ninu rẹ bi ihunrira, bẹẹni ori fifọ ko nii kan ẹniti wọn ba fun mu, ara ati laakaye ẹniti o ba mu u yoo lalaafia.
وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ عِينٞ 48
Awọn obinrin alamumọra nbẹ fun ni ọgba idẹra, ti oju wọn kii lọ si ọdọ ẹniti kii se ọkọ wọn, wọn jẹ ẹni oju rẹ dara ju.
كَأَنَّهُنَّ بَيۡضٞ مَّكۡنُونٞ 49
Nibi fifunfun awọ wọn, wọn da gẹgẹ bi pipupa fẹsi fẹsi ẹyẹ funfun ti a tọju, ti ọwọ ko si tii kan an.
فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ 50
Apakan awọn ẹni ọgba idẹra yoo da oju kọ apakan, wọn yoo si maa bira wọn leere lori ohun ti o ti sẹlẹ siwaju ati ohun ti o sẹlẹ si wọn ni ile aye.
قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٞ 51
Ẹnikan ninu awọn olugbagbọ ododo yii wa sọpe: dajudaju nbẹ fun ni ile aye ara kan ti o jẹ olutako igbende.
Okunfa iya awọn keferi: isẹ ikorira; ohun ni ẹbọ ati awọn ẹsẹ.
Ninu idẹkun awọn ẹni ọgba idẹra nipe wọn yoo se idẹkun kikojọ apakan wọn pẹlu apakan, bẹẹni apakan wọn yoo si maa da oju kọ apakeji, eleyi si jẹ ninu idunnu ti o pe.