وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِيٓ إِلَيۡهِ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدُونِ 25
A ko gbe dide siwaju rẹ - ire ojise - ojisẹ kan ayaafi ki a ransẹ imisi si wipe ko si ẹni ijọsin fun ti ododo ayaafi Emi, ki ẹ yaa ma sin Mi ni Emi nikan, ki ẹ si maa mu ẹbọ pẹlu Mi.
وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۚ بَلۡ عِبَادٞ مُّكۡرَمُونَ 26
Awọn ẹlẹbọ sọpe: Ọlọhun Allah fi awọn Malaika se ọmọbinrin, mimọ Ọba mimọ yii, O si mọ kanga kuro nibi irọọ ti wọn nsọ yii, bikosepe awọn Malaika jẹ ẹrusin Allah, ẹni apọnle lati ọdọ Rẹ, ẹni asunmọ si I.
لَا يَسۡبِقُونَهُۥ بِٱلۡقَوۡلِ وَهُم بِأَمۡرِهِۦ يَعۡمَلُونَ 27
Wọn kii gbawaju Ọlọhun wọn nibi ọrọ sisọ, wọn kii sọrọ titi yoo fi pa wọn lasẹ, wọn ma nsisẹ lati ibi asẹ Rẹ, wọn kii yapa asẹ Rẹ.
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَلَا يَشۡفَعُونَ إِلَّا لِمَنِ ٱرۡتَضَىٰ وَهُم مِّنۡ خَشۡيَتِهِۦ مُشۡفِقُونَ 28
O mọ eyiti o gbawaju ninu isẹ wọn ati eyiti o tẹle e, wọn kii beere fun isipẹ ayaafi pẹlu iyọnda Rẹ fun ẹniti Ọlọhu Allah ba fẹ gba ipẹ rẹ, wọn si jẹ ẹniti o ma npaya Rẹ, mimọ ọ Rẹ ni ẹniti o nsọra, wọn kii yapa nibi asẹ tabi ikọ fun ni.
۞وَمَن يَقُلۡ مِنۡهُمۡ إِنِّيٓ إِلَٰهٞ مِّن دُونِهِۦ فَذَٰلِكَ نَجۡزِيهِ جَهَنَّمَۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلظَّٰلِمِينَ 29
Ẹniti o ba sọ ninu awọn Malaika niti gbigbe ọrọ yẹwo: dajudaju emi jẹ ẹniti o yẹ ki a sin yatọ si Allah, dajudaju awa yoo san lẹsan lori gbolohun rẹ pẹlu iya jahanamọ ni ọjọ igbende ti yoo maa wa nibẹ lọ gbere, iru ẹsan yii ni a o san fun awọn alabosi nitori sise keferi ati sise ẹbọ fun Allah wọn.
أَوَ لَمۡ يَرَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ كَانَتَا رَتۡقٗا فَفَتَقۡنَٰهُمَاۖ وَجَعَلۡنَا مِنَ ٱلۡمَآءِ كُلَّ شَيۡءٍ حَيٍّۚ أَفَلَا يُؤۡمِنُونَ 30
Se awọn ti wọn se keferi si Allah wipe dajudaju sanmọ ati ilẹ mejeeji lẹ pọ ni, ko si alafo ni aarin mejeeji ti ojo wa nsọ kalẹ nibẹ, ni awa se onpinya laarin mejeeji, a si se gbogbo nkan gẹgẹ bi ẹranko ati awọn irugbin ninu omin eyiti o nsọkalẹ lati sanmọ si ilẹ, se wọn ko woye si eleyi ni, ki wọn wa nigbagbọ ninu Allah nikan soso?!
وَجَعَلۡنَا فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِهِمۡ وَجَعَلۡنَا فِيهَا فِجَاجٗا سُبُلٗا لَّعَلَّهُمۡ يَهۡتَدُونَ 31
A da oke si inu ilẹ ni ohun ti o rinlẹ, ti ko fi ni maa min mọ awọn ti nbẹ ni ori ilẹ, a si se awọn oju opo ati awọn ọna ti o gbaaye sibẹ, ki wọn le baa mọ ọna nibi irin ajo wọn lọ sibi awọn erongba wọn.
وَجَعَلۡنَا ٱلسَّمَآءَ سَقۡفٗا مَّحۡفُوظٗاۖ وَهُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِهَا مُعۡرِضُونَ 32
A si se sanmọ ni aja ni ohun ti a daabobo kuro nibi jijabọ ti ko ni opo, ti o si tun jẹ ohun ti a daabobo kuro nibi jiji ọrọ gbọ ati awọn ẹlẹbọ kuro nibi ohun ti nbẹ ni sanmọ ninu awọn amin - gẹgẹ bi oorun ati osupa - ni ẹniti o ngunri, ti wọn ko woye.
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ فِي فَلَكٖ يَسۡبَحُونَ 33
Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ni ẹniti o da oru fun isinmin, O si da ọsan fun kiko nkan ijẹ imu jọ, O si da oorun ki o le jẹ amin lori ọsan ati osupa ki o jẹ amin lori oru, oorun ati osupa mejeeji nlọ ni oju opo rẹ ti a sa lẹsa fun un, ko nii yẹ kuro nibẹ bẹẹni ko nii fi.
وَمَا جَعَلۡنَا لِبَشَرٖ مِّن قَبۡلِكَ ٱلۡخُلۡدَۖ أَفَإِيْن مِّتَّ فَهُمُ ٱلۡخَٰلِدُونَ 34
A ko se fun ẹnikẹni ninu abara siwaju rẹ isẹku ninu isẹmin aye yii? - ire ojise -, ti asiko rẹ ba tan ninu isẹmin aye yii, ti o si ku, se awọn wọnyi yoo sẹku lẹyin rẹ ni?! Ko le ri bẹẹ.
كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۗ وَنَبۡلُوكُم بِٱلشَّرِّ وَٱلۡخَيۡرِ فِتۡنَةٗۖ وَإِلَيۡنَا تُرۡجَعُونَ 35
Gbogbo ẹmin ti o jẹ olugbagbọ tabi keferi ni yoo tọ iku wo ni ile aye, a o si dan yin wo - ẹyin eniyan - ninu isẹmin aye pẹlu awọn nkan ilabọrun ati idẹkun ati iya lẹyin iku yin si ọdọ Wa, kii se ọdọ ẹlomiran ni ẹyin yoo sẹri si, a o si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin.
Mimọ Ọlọhun Allah kuro nibi ọmọ.
Ipo awọn Malaika lọdọ Ọlọhun nipe dajudaju wọn jẹ ẹru ti Ọlọhun Allah da fun itẹle asẹ Rẹ, a ko le royin wọn pẹlu jijẹ akọ tabi abo, wọn kan jẹ ẹru alapọnle.
Wọn da sanmọ ati ilẹ ni ibamun si isesi ipelenpele, paapa wọn da mejeeji ni ohun ti o lẹ papọ mọ ara wọn, lẹyin naa ni wọn se onpinya laarin wọn.
Adanwo gẹgẹ bi o se jẹ pẹlu aburu naa ni o wa pẹlu rere.