تُؤۡتِيٓ أُكُلَهَا كُلَّ حِينِۢ بِإِذۡنِ رَبِّهَاۗ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَالَ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ 25
Ti o nfun igi yii ti o dara ni eso rẹ ti o dara ni gbogbo asiko pẹlu asẹ Ọlọhun Ọba rẹ, Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun ma nfi apejuwe lelẹ fun awọn eniyan ki wọn le ronu.
وَمَثَلُ كَلِمَةٍ خَبِيثَةٖ كَشَجَرَةٍ خَبِيثَةٍ ٱجۡتُثَّتۡ مِن فَوۡقِ ٱلۡأَرۡضِ مَا لَهَا مِن قَرَارٖ 26
Apejuwe gbolohun ẹbọ ti ko dara da gẹgẹ bi igi ti ko dara, ohun naa ni igi ‘hadhọlu’, wọn tu ipilẹ rẹ, ko fi ọsọ rinlẹ ni ori ilẹ, bẹẹ ni ko ga de sanmọ, yoo ku, bẹẹ ni atẹgun yoo si fẹ lọ, gbolohun keferi ibusẹri si rẹ ni titan, ko si le mu isẹẹre fun ẹniti ti o se goke lọọ ba Ọlọhun Ọba rẹ.
يُثَبِّتُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱلۡقَوۡلِ ٱلثَّابِتِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۖ وَيُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلظَّٰلِمِينَۚ وَيَفۡعَلُ ٱللَّهُ مَا يَشَآءُ 27
Ọlọhun Ọba Allah ma nfi awọn olugbagbọ ododo rinlẹ pẹlu gbolohun ijọkan soso ti o rinlẹ niti igbagbọ ti o pe ni isẹmin aye titi wọn yoo fi ku lori igbagbọ ati ni agede meji inu saare ni igba ibeere, yoo si tun fi wọn rinlẹ ni ọjọ igbende, Ọlọhun Ọba Allah yoo fi awọn alabosi silẹ si inu isina nitori sise ẹbọ si Allah ati sise keferi si I kuro ni ọna ti o tọ ati ọgbọn, Ọlọhun Ọba Allah ma nse ohun ti O wu U fifi silẹ ninu isisna ẹniti O ba fẹ fi silẹ ninu isisna lati ara deedee Rẹ, O si ma nmu mọ ọna ẹniti o ba wu U lati fi mọna latara ọla Rẹ, olujẹni nipa kankan ko si fun Un.
۞أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ بَدَّلُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ كُفۡرٗا وَأَحَلُّواْ قَوۡمَهُمۡ دَارَ ٱلۡبَوَارِ 28
Paapaa mo ti ri isesi awọn ti o se keferi si Allah ati ojisẹ Rẹ ninu awọn kuraysi nigbati wọn npaarọ idẹkun Ọlọhun Ọba ti o nbẹ ni ori wọn ninu ifọkanbalẹ ni ayika naa ati gbigbe Muhammad dide laarin wọn, wọn npaarọ eleyi: sise keferi si idẹkun rẹ nigbati wọn pe ohun ti o muwa nirọ lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, wọn si nfi ẹniti o ba tẹle wọn nibi keferi ninu awọn ijọ wọn si ile iparun.
جَهَنَّمَ يَصۡلَوۡنَهَاۖ وَبِئۡسَ ٱلۡقَرَارُ 29
Ile iparun ni jahannamọ ti wọn yoo wọ, wọn yoo maa fi ara kin ooru ibẹ, ibiti wọn dari si yii jẹ ibudarisi aburu.
وَجَعَلُواْ لِلَّهِ أَندَادٗا لِّيُضِلُّواْ عَن سَبِيلِهِۦۗ قُلۡ تَمَتَّعُواْ فَإِنَّ مَصِيرَكُمۡ إِلَى ٱلنَّارِ 30
Awọn ẹlẹbọ mu apejuwe tabi afijọ fun Allah lati le sọ ẹniti o tẹle wọn nu kuro ni oju ọna Allah lẹyin kigbati awọn ti sọnu kuro nibẹ, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: ẹ maa gbadun igbadun ti ẹ wa nibẹ ati fifan awọn iruju ninu isẹmin aye yii ka, dajudaju ibusẹri si yin ni ọjọ igbende jẹ ina, ẹ ko ni ibusẹri si miran yatọ si i.
قُل لِّعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُنفِقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا بَيۡعٞ فِيهِ وَلَا خِلَٰلٌ 31
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn olugbagbọ ododo: ẹyin olugbagbọ ododo, ẹ maa kirun ni ojupọnna pipe, ki ẹ si maa na ninu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se fun yin, awọn inawo ọranyan ati eyiti a nifẹ sin ni kọkọ lati bẹru kuro nibi sisarimi, ati ni gbangba ki ẹlomiran ti o yatọ si yin le kọse yin siwaju ki ọjọ kan too de ti ko nii si pasi paarọ nibẹ tabi afidi eyiti afidi kuro nibi iya Allah, ko si nii si ibasọrẹ ti ọrẹ kan yoo fi le sipẹ fun ọrẹ rẹ.
ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجَ بِهِۦ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ رِزۡقٗا لَّكُمۡۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡفُلۡكَ لِتَجۡرِيَ فِي ٱلۡبَحۡرِ بِأَمۡرِهِۦۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡهَٰرَ 32
Ọlọhun Ọba Allah eyiti o sẹda sanmọ, O si tun sẹda ilẹ laisi apejuwe kan siwaju, O tun sọ omin ojo kalẹ ni sanmọ, O nmu oniranran irugbin jade lati ibi omin ti o sọkalẹ ki o le jẹ arisiki fun yin - ẹyin eniyan -, o nrọ ọkọ oju omin fun yin ki o le maa rin ni ori omin ni ibamun si odiwọn rẹ, O si tun rọ omin fun yin ki ẹ le maa mu nibẹ, ati ki ẹ le maa fun awọn ẹran ati irugbin yin mu.
وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ دَآئِبَيۡنِۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ 33
O tun rọ oorun, osupa fun yin ti mejeeji nlọ ni tẹlentẹle, O tu rọ oru ati ọsan fun yin ti wọn npaarọ awọn wọn, oru wa fun oorun yin ati isimin yin, ọsan si wa fun idasasa yin ati wahala yin.
Fifi gbolohun keferi jọ igi ‘hadhọla’ ti o parẹ mọ ilẹ, o jẹ ohun ti ko le ga, ko si le bi ohun ti o dara, ko si le bẹ gbere.
Isopọ ti nbẹ laarin pipani lasẹ irun ati zaka pẹlu riranti ọjọ ikẹyin, o jẹ ifuramọ wipe dajudaju awọn mejeeji jẹ nkan ti eniyan fi le la ni ọjọ naa.
Kika apakan idẹkun ti o tobi jẹ itọka si titobi keferi apakan awọn ọmọ adamọ ati jijẹ idẹkun Rẹ ti mimọ nbẹ fun niyan.