أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ مِنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ مِنۢ بَعۡدِ مُوسَىٰٓ إِذۡ قَالُواْ لِنَبِيّٖ لَّهُمُ ٱبۡعَثۡ لَنَا مَلِكٗا نُّقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ قَالَ هَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِتَالُ أَلَّا تُقَٰتِلُواْۖ قَالُواْ وَمَا لَنَآ أَلَّا نُقَٰتِلَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَقَدۡ أُخۡرِجۡنَا مِن دِيَٰرِنَا وَأَبۡنَآئِنَاۖ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقِتَالُ تَوَلَّوۡاْ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّٰلِمِينَ 246
Se imọ rẹ ko de - irẹ Anọbi - ibi iro awọn abiyi ninu awọn bani Israheel, lẹyin asiko Muusa (ki ọla maa jẹ tirẹ) nigbati wọn sọ fun Anọbi wọn: gbe ọba kan dide fun wa, ti a o maa jagun pẹlu rẹ si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ni Anọbi wọn wa sọ fun wọn: o maa se se fun yin, ti Ọlọhun Ọba Allah ba se ogun jija ni ọranyan fun yin, ki ẹ ma jagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah! Wọn sọ ni ẹniti o nkorira aba rẹ si wọn, kinni ohun ti o le kọ fun wa nibi jijagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah pẹlu bibẹ ohun ti o le fa nkan naa laarin wa? To si jẹ wipe paapaa, awọn ọta wa ti yọ wa jade kuro ninu awọn ilu wa, ti wọn si ko awọn ọmọ wa ni ẹru, ti a o wa jagun lati le ba da ilu wa pada, ati lati le ba gba awọn ẹru wa silẹ, nigbati Ọlọhun Ọba Allah se ogun jija ni ọranyan fun wọn, wọn gunri, nigbati wọn ko pe ohun ti wọn se ni adehun ayaafi diẹ ninu wọn, Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti O m awọn alabosi, ti wọn gunri kuro nibi asẹ Rẹ, awọn ti wọn tu adehun Rẹ, ati wipe Yoo si pada san wọn lẹsan lori nkan naa.
وَقَالَ لَهُمۡ نَبِيُّهُمۡ إِنَّ ٱللَّهَ قَدۡ بَعَثَ لَكُمۡ طَالُوتَ مَلِكٗاۚ قَالُوٓاْ أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُ ٱلۡمُلۡكُ عَلَيۡنَا وَنَحۡنُ أَحَقُّ بِٱلۡمُلۡكِ مِنۡهُ وَلَمۡ يُؤۡتَ سَعَةٗ مِّنَ ٱلۡمَالِۚ قَالَ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰهُ عَلَيۡكُمۡ وَزَادَهُۥ بَسۡطَةٗ فِي ٱلۡعِلۡمِ وَٱلۡجِسۡمِۖ وَٱللَّهُ يُؤۡتِي مُلۡكَهُۥ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ 247
Anọbi wọn wa sọ fun wọn: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti gbe dide fun yin ni paapaa Tọluuta ni ọba le yin lori, ki ẹ le ba jagun ni abẹ asia rẹ, awọn abiyi wọn wa sọ ni ẹniti o korira yiyan yii, ti wọn ko si gba wọle wipe: bawo ni ọla yoo se wa fun un lori wa, awa ni a ni ẹtọ si ọla juu lọ; nitoripe ko si ninu awọn ọmọ ọba, wọn ko si fun ni owo ti o pọ, ti yoo fi se iranwọ lori ọla naa? ! Anọbi wọn sọ fun wọn wipe: dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, sa ẹsa rẹ leyin lori, O si se alekun fun un lori yin gbigbooro ninu imọ ati agbara ninu ara, Ọlọhun Ọba Allah ma nfun ẹniti o ba wu U ni ọla Rẹ pẹlu oye ati ikẹ Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti O gbooro ni ọla, ti O si ma nfun ẹniti o ba wu U, Oun ni Onimọ pẹli ẹniti o lẹtọ sii ninu awọn ẹda Rẹ.
وَقَالَ لَهُمۡ نَبِيُّهُمۡ إِنَّ ءَايَةَ مُلۡكِهِۦٓ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلتَّابُوتُ فِيهِ سَكِينَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَبَقِيَّةٞ مِّمَّا تَرَكَ ءَالُ مُوسَىٰ وَءَالُ هَٰرُونَ تَحۡمِلُهُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ 248
Anọbi wọn sọ fun wọn wipe: dajudaju amin jijẹ ododo sisaa lẹsa ni ọba leyin lori; ni ki Ọlọhun Ọba Allah da pada fun yin ‘At-Tabuut’ – o jẹ apoti kan, ti awọn bani Israheel ma ngbe tobi, to wọn gbaa lọwọ wọn- o nbẹ nibẹ ifọkanbalẹ ti yoo maa kẹgbẹ rẹ, o si nbẹ nibẹ awọn asẹkubọ ninu ohun ti awọn eniyan Muusa ati Haruuna fi silẹ, gẹgẹ bi ọpa ati apakan ninu awọn ọpọn, dajudaju o nbẹ ninu nkan naa, amin ti o fi han fun yin, ti ẹ ba jẹ olugbagbọ ododo ni tootọ.
Titani ji lọ si ibi eyiti o se pataki ninu awọn iroyin adari, eyiti yoo fun anfaani lati dari awọn ẹniyan; ohun naa ni imọ nipa ohun ti o fẹ dari rẹ ati nini agbara le lori.
Sise itọsọna fun ẹniti yoo gba idari awọn eniyan si ibi ki o ma gba itanjẹ pẹlu awọn gbolohun wọn titi yoo fi dan wọn wo, ti yoo si gbe awọn isẹ wọn yẹwo lẹyin awọn ọrọ wọn.
Dajudaju ohun ti a o maa woye si eyiti o seese ki o han ni aarin awọn eniyan nibi gbigbe awọn miran si ori osunwọn ati didajọ wọn, o seese ki o ma jẹ ohun ni awọn osunwọn ti o ni alaafia ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, bikose wipe mimọ fun Un, O ma nsẹsa ẹniti O ba wu U ninu awọn ẹda Rẹ pẹlu oye Rẹ ati imọ Rẹ.