۞وَٱلۡمُحۡصَنَٰتُ مِنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡۖ كِتَٰبَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡۚ وَأُحِلَّ لَكُم مَّا وَرَآءَ ذَٰلِكُمۡ أَن تَبۡتَغُواْ بِأَمۡوَٰلِكُم مُّحۡصِنِينَ غَيۡرَ مُسَٰفِحِينَۚ فَمَا ٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهِۦ مِنۡهُنَّ فََٔاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا تَرَٰضَيۡتُم بِهِۦ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡفَرِيضَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا 24
Ati wipe wọn se ni eewọ fun yin fifẹ awọn ti wọn ti ni ọkọ ninu awọn obirin, ayaafi eyiti ẹ ba kapa lori rẹ pẹlu kiko ni ẹru ni oju ogun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, yoo maa lẹtọ fun yin biba wọn se asepọ pẹlu mimọ awọn apo ibimọ wọn pẹlu sise nkan osu, Ọlọhun Ọba Allah se nkan naa ni ọranyan fun yin niti ọranyan, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah waa se ohun ti o ba yatọ si nkan naa ninu awọn obirin, ki ẹ wa didaabobo ẹmin ara yin ati didin ojukokoro rẹ ku pẹlu awọn owo yin pẹlu ohun ti o lẹtọ laini gbero agbere, ẹniti o ba jẹ igbadun pẹlu wọn pẹlu fifẹ wọn, ki ẹ wa fun wọn ni awọn owo ori wọn eyiti Ọlọhun Ọba Allah se ni ọranyan ti o jẹ dandan le yin lori, ati wipe ko si ẹsẹ fun yin nibi ohun ti iyọnu yin ba wa lori rẹ lẹyin fifi ote le owo ori eyiti o jẹ dandan, nibi sise alekun lori rẹ tabi sise amojukuro nibi apakan rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Onimimọ pẹlu awọn ẹda Rẹ, nkankan ko si nii pamọ fun ninu wọn, O si jẹ ọjọgbọn nibi didari Rẹ ati sise ofin Rẹ.
وَمَن لَّمۡ يَسۡتَطِعۡ مِنكُمۡ طَوۡلًا أَن يَنكِحَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ فَمِن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن فَتَيَٰتِكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِكُمۚ بَعۡضُكُم مِّنۢ بَعۡضٖۚ فَٱنكِحُوهُنَّ بِإِذۡنِ أَهۡلِهِنَّ وَءَاتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِ مُحۡصَنَٰتٍ غَيۡرَ مُسَٰفِحَٰتٖ وَلَا مُتَّخِذَٰتِ أَخۡدَانٖۚ فَإِذَآ أُحۡصِنَّ فَإِنۡ أَتَيۡنَ بِفَٰحِشَةٖ فَعَلَيۡهِنَّ نِصۡفُ مَا عَلَى ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ مِنَ ٱلۡعَذَابِۚ ذَٰلِكَ لِمَنۡ خَشِيَ ٱلۡعَنَتَ مِنكُمۡۚ وَأَن تَصۡبِرُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 25
Ati wipe ẹniti ko ba kapa ninu yin - ẹyin ọkunrin - nitori owo rẹ ti o kere lati fẹ awọn ọmọluwabi ninu awọn obirin, o lẹtọ fun un lati fẹ awọn ẹrubirin awọn ti wọn wa labẹ ikapani ẹlomiran ti o yatọ si yin, ti wọn ba jẹ olugbagbọ ododo lobirin nibi ohun ti o han si yin, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni O nimọ julọ pẹlu paapaa nini igbagbọ yin ati awọn kọkọ awọn isesi yin ati wipe ẹyin ati awọn ri bakanna nibi ẹsin ati ijọmọniyan, ẹ mase gbe ọkan kuro nibi fifẹ ninu wọn, ki ẹ yaa maa fẹ wọn pẹlu iyọnda awọn ti o ni wọn, ati wipe ki ẹ fun wọn ni owo ori wọn laini ni adinku ninu tabi lilọ lara, eleyi yoo maa waye ti wọn ba jẹ ẹniti o ni amojukuro, ti wọn ko jẹ onisina lobirin ni gbangba, ti wọn ko si jẹ ẹniti o ni awọn ọrẹkunrin nibi sise sina pẹlu wọn ni kọkọ, ti wọn ba ti waa ni ọkọ lẹyin igba naa ti wọn wọn waa mu iwa ibajẹ sina wa ijiya wọn yoo maa jẹ ilaji ijiya awọn ọmọluwabi lobirin: ẹgba aadọta, ko si si lilẹ wọn ni oko pẹlu yiyatọ si awọn ti o ti ni ọkọ ninu awọn ọmọluwabi birin nigbati wọn ba se sina, ohun ti o jẹ sisọ naa nibi sise fifẹ awọn ẹrubirin ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, ti wọn si jẹ alamojukuro ni ẹtọ, o jẹ ẹdẹ fun ẹniti ti o ba paya lori ẹmin ara rẹ kiko sinu sina sise, ati wipe ti ko ni agbara lori fifẹ awọn ọmọluwabi birin, lori wipe dajudaju sise suuru nibi fifẹ awọn ẹrubirin ni o dara ju, lati le ba gbe ijẹ ẹru jinna si awọn ọmọ, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Alaforijin fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, Onikẹ wọn si ni, ati wipe ninu ikẹ Rẹ ni sise ni ofin fun wọn, fifẹ ẹrubirin ni igbati ikagara ba wa lati fẹ awọn ọmọluwabi birin nigba pipawa sina.
يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُبَيِّنَ لَكُمۡ وَيَهۡدِيَكُمۡ سُنَنَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَيَتُوبَ عَلَيۡكُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ 26
Ọlọhun Ọba Allah, mimọ fun Un gbero pẹlu sise ofin Rẹ ti O se awọn ofun yii fun yin, lati ba se alaye fun yin awọn idanimọ ofin Rẹ ati ẹsin Rẹ ati ohun ti daadaa yin nbẹ nibẹ ni aye ati ni ọrun, ati wipe O gbero lati tọ yin sọna si oju ọna awọn Anọbi ti wọn siwaju yin, nibi sise nkan ni ẹtọ ati sise ni eewọ, ati awọn iwa wọn alapọnle ati awọn ọrọ nipa wọn ti o jẹ ẹlẹyin, ki ẹ le baa maa tẹle wọn, ati wipe O gbero lati sẹri yin pada kuro nibi yiyapa Rẹ lọsi bi titẹle, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Onimimọ nipa ohun ti daadaa awọn ẹru Rẹ nbẹ nibẹ, ni yoo fi waa se ni ofin fun wọn, O si jẹ Ọjọgbọn nibi sise ofin Rẹ ati nibi didari Rẹ ti O ndari alamọri wọn.
Jijẹ eewọ fifẹ awọn ti o ni ọkọ lobirin: awọn ọmọluwabi ni tabi awọn ẹru titi ti wọn yoo fi pari igbele wọn, eyikeyi ti okunfa igbele naa jẹ.
Dajudaju owo ori ọmọbirin yoo maa di dandan lẹyin wiwọle tii, ati lilẹtọ sise adinku apakan owo ori rẹ, ti o ba jẹ pẹlu idunnu rẹ.
Lilẹtọ fifẹ awọn ẹrubirin olugbagbọ ododo nigba aini agbara lori fifẹ awọn ọmọluwabi lobirin nigbati o ba nbẹru lori ẹmin ara rẹ kiko sinu sina sise.
Ninu awọn idi ofin sẹria ni sise alaye ọnaamọ ati anu, ati jiju awọn eniyan niwe lọsi bi awọn oju ọnaamọ eyiti yoo da wọn pada si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) .