فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُواْ ٱقۡتُلُوهُ أَوۡ حَرِّقُوهُ فَأَنجَىٰهُ ٱللَّهُ مِنَ ٱلنَّارِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 24
Esi ijọ Ibrahim fun un ko jẹ nkankan ju - lẹyin igbati o ti pa wọn lasẹ ki wọn sin Allah nikan soso, ki wọn si gbe ijọsin ohun ti o yatọ si I ju silẹ ninu awọn oosa - ati ki wọn sọpe: ẹ pa a tabi kẹ ju u sinu ina, ki o le jẹ aranse fun awọn ọlọhun yin, Allah si la a kuro nibi ina, dajudaju nibi lila a kuro ninu ina lẹyin igbati wọn ju u sibẹ jẹ awọn ariwoye fun ijọ ti o nigbagbọ; nitoripe awọn ni yoo se anfaani pẹlu oye.
وَقَالَ إِنَّمَا ٱتَّخَذۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡثَٰنٗا مَّوَدَّةَ بَيۡنِكُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ ثُمَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكۡفُرُ بَعۡضُكُم بِبَعۡضٖ وَيَلۡعَنُ بَعۡضُكُم بَعۡضٗا وَمَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّٰصِرِينَ 25
Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun sọ fun awọn ijọ rẹ: dajudaju ẹ mu awọn oosa ni ọlọhun ti ẹ nsin nitori imọra ẹni ati ifẹran ara ẹni lori ijọsin rẹ ni isẹmin aye sugbọn ni ọjọ igbende ifẹran ara ẹni yii yoo ja laarin yin, bayi ni apakan yoo bọpa kuro ni ọdọ apakeji nigbati ifoju kan iya ba sẹlẹ, bayi ni apakan yoo si maa sẹbi le apa keji, ibusẹri si yin ti ẹ npada bọ si ni ina, ko si si awọn alaranse ti yoo kọ fun yin kuro nibi iya Allah, ko si ninu awọn oosa yin ti ẹ njọsin fun yatọ si Allah, bẹẹni ko si ni ọdọ ẹniti o yatọ si i.
۞فََٔامَنَ لَهُۥ لُوطٞۘ وَقَالَ إِنِّي مُهَاجِرٌ إِلَىٰ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 26
Luuth ẹniti ọla nbẹ fun nigbagbọ si I, Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun si sọpe: dajudaju emi jẹ oluse irin ajo lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba mi lati lọ si ilẹ saamu onibukun, dajudaju Oun jẹ alagbara ti ẹnikan ko le bori, bẹẹni ti ẹniti o se irin ajo lọ si ọdọ rẹ ko le yẹpẹrẹ, O si jẹ ọjọgbọn nibi ipebubu ati idari Rẹ.
وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَجَعَلۡنَا فِي ذُرِّيَّتِهِ ٱلنُّبُوَّةَ وَٱلۡكِتَٰبَ وَءَاتَيۡنَٰهُ أَجۡرَهُۥ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 27
A si fun Ibrahim ni Ishaaq ati ọmọ rẹ Ya'quub, a si se awọn ọmọ rẹ ni anọbi, bẹẹ naa ni awọn iwe ti o sọkalẹ lati ọdọ Allah, a si fun ni ẹsan suuru rẹ lori ododo ni ile aye pẹlu didara awọn ọmọ rẹ ati iroyin rere, bẹẹ naa ni ti o ba di ọjọ ikẹyin, a o san lẹsan awọn ẹni rere ohun ti wọn fun ni ile aye ko nii dinku nibi ohun ti wọn pese fun ni ẹsan apọnle lọrun.
وَلُوطًا إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ إِنَّكُمۡ لَتَأۡتُونَ ٱلۡفَٰحِشَةَ مَا سَبَقَكُم بِهَا مِنۡ أَحَدٖ مِّنَ ٱلۡعَٰلَمِينَ 28
Tun ranti - irẹ ojisẹ - Luuth nigbati ọ sọ fun awọn ijọ rẹ: dajudaju ẹ da ẹsẹ ti ko dara, ti ẹnikankan ti o siwaju yin ni agbanla aye ko tii mu iru rẹ wa siwaju yin, ẹyin ni akọkọ ẹniti o bẹrẹ ẹsẹ naa eyiti adamọ daadaa tako.
أَئِنَّكُمۡ لَتَأۡتُونَ ٱلرِّجَالَ وَتَقۡطَعُونَ ٱلسَّبِيلَ وَتَأۡتُونَ فِي نَادِيكُمُ ٱلۡمُنكَرَۖ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُواْ ٱئۡتِنَا بِعَذَابِ ٱللَّهِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 29
Se ẹyin yoo maa ba ọkunrin lopọ ni ibara idi rẹ lati jẹ igbadun yin ni, ti ẹ o si tun ma ja ọna mọ awọn oluse irin ajo ti wọn ko fi nii le re kọja ni ọdọ yin nitori ipaya ohun ti ẹ nse ni ibajẹ, ti ẹ si nmu awọn isẹ ikorira wa ni awọn aaye yin gẹgẹ bi ibọra silẹ ni hoho ati ifisuta se ẹniti o ba re kọja yin niti gbolohun tabi isẹ? Ko si esi awọn ijọ rẹ fun lẹyin kikọ fun wọn nibi awọn isẹ buruku yii ayaafi ki wọn sọ fun un pe: mi iya Allah eyiti o fi nda ẹru ba wa waa ba wa ti o ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti o npe ara rẹ.
قَالَ رَبِّ ٱنصُرۡنِي عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُفۡسِدِينَ 30
Luuth ẹniti ọla nbẹ fun sọ ni ẹniti o npe Ọlọhun Ọba rẹ lẹyin ori kunkun awọn ijọ rẹ ati wiwa sisọkalẹ iya le wọn lori niti fifuyẹ rẹ: ran mi se lori awọn ijọ olubilẹjẹ lori ilẹ lori keferi ati awọn ẹsẹ ti ko dara ti wọn fan kiri.
Ikọbi ara si Allah lori awọn ẹru Rẹ rere nibi lila wọn kuro nibi ete awọn ọta wọn.
Ọla ti nbẹ fun sise irin ajo lọsi ọdọ Allah.
Titobi ipo anọbi Ibrahim ati awọn ara ile rẹ lọ ọdọ Allah ti O ga.
Lọlọra apakan ẹsan ni ile aye ko tumọ si didinku ẹsan ti ọrun.
Aburu mima se ibajẹ ni awọn aaye ti o gbajumọ.