حَٰفِظُواْ عَلَى ٱلصَّلَوَٰتِ وَٱلصَّلَوٰةِ ٱلۡوُسۡطَىٰ وَقُومُواْ لِلَّهِ قَٰنِتِينَ 238
Ẹ maa sọ awọn irun pẹlu mima muwa ni pipe, gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba Allah ti pasẹ Rẹ, ki ẹ si sọ aarin-gbungbun, laarin awọn irun, ohun naa ni irun ‘Asri, ki ẹ si maa duro fun Ọlọhun Ọba Allah nibi irun yin, ni olutẹle ati olupaya.
فَإِنۡ خِفۡتُمۡ فَرِجَالًا أَوۡ رُكۡبَانٗاۖ فَإِذَآ أَمِنتُمۡ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَمَا عَلَّمَكُم مَّا لَمۡ تَكُونُواْ تَعۡلَمُونَ 239
Ti ẹ ba nbẹru ọta kan ati oun ti o jọọ, ti ẹ ko wa lagbara lati muwa ni pipe, ki ẹ ya maa ki irun ni ẹniti o nrin lori awọn ẹsẹ yin, tabi ni ẹniti o gun rakunmi, ati ẹsin, ati awọn nkan ti o jọọ, tabi lori eyikeyi iroyin ti a ba kapa, ti ibẹru ba wa kuro fun yin, ki ẹ ya maa ranti Ọlọhun Ọba Allah pelu gbogbo iranti, ninu rẹ naa ni riranti Rẹ ninu irun lori pipe rẹ ati pipari rẹ gege bi O se fi mo yin oun ti ẹ ko mọ ninu imọlẹ ati imọna.
وَٱلَّذِينَ يُتَوَفَّوۡنَ مِنكُمۡ وَيَذَرُونَ أَزۡوَٰجٗا وَصِيَّةٗ لِّأَزۡوَٰجِهِم مَّتَٰعًا إِلَى ٱلۡحَوۡلِ غَيۡرَ إِخۡرَاجٖۚ فَإِنۡ خَرَجۡنَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِي مَا فَعَلۡنَ فِيٓ أَنفُسِهِنَّ مِن مَّعۡرُوفٖۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 240
Awọn ti wọn ku ninu yin, ti wọn si fi awọn iyawo si ẹyin wọn, o di dandan fun wọn lati sọ asọtẹlẹ fun wọn, pe ki wọn fun wọn ni igbadun pẹlu ile gbigbe, ati ninawo lapapọ ti o pe, awọn ti yoo jogun yin ko gbọdọ yọ wọn kuro lati le ba jẹwọn nipa lori ohun ti o sẹlẹ si wọn, ati lati pipe adehun oku, ti wọn ba wa jade siwaju ki ọdun too pe, ni ohun ti o ti ẹmi wọn wa, ko si ẹsẹ fun yin, ko si si fun awọn naa nibi ohun ti wọn se fun ẹmi ara wọn nibi sise ọsọ ati sise ara loge, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah, Alagbara ni, ti ko si ẹniti yoo bori Rẹ, Ọjọgbọn si ni, nibi didari Rẹ ati ofin Rẹ ati ipebubu Rẹ. Eleyi, ati wipe paapaa olutumọ Alukuraani ti lọ si ibi wipe dajudaju idajọ aayah yii, ohun ti wọn ti parẹ ni pẹlu gbolohun Rẹ ti ọla Rẹ ga (وَٱلَّذِينَ يُتَوَفَّوۡنَ مِنكُمۡ وَيَذَرُونَ أَزۡوَٰجٗا يَتَرَبَّصۡنَ بِأَنفُسِهِنَّ أَرۡبَعَةَ أَشۡهُرٖ وَعَشۡرٗاۖ) (awọn ti ọkọ wọn ku ninu yin, ti wọn si fi awọn obirin silẹ, wọn yoo fi ara wọn lelẹ fun osu mẹẹrin ati ọjọ mẹwa) Al-Bakọra: 234.
وَلِلۡمُطَلَّقَٰتِ مَتَٰعُۢ بِٱلۡمَعۡرُوفِۖ حَقًّا عَلَى ٱلۡمُتَّقِينَ 241
O nbẹ fun awọn ti wọn kọ silẹ ni obirin, igbadun kan ti wọn yoo fun wọn gbadun nibi asọ wiwọ, ati owo, ati ohun ti o yatọ si nkan naa, lati fi rọ awọn irori wọn eyiti o ti daru pẹlu kikọ, ni ibamun si daadaa nibi sise amojuto isesi iyawo ninu ainito tabi ọpọ, atipe idajọ yii, ẹtọ kan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ni lori awọn ti o paya Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, pẹlu mimu asẹ Rẹ wa si imusẹ ati jijina si ohun ti O kọ.
كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 242
Iru alaye naa ti o siwaju, ni Ọlọhun Ọba Allah fi nsalaye fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn aayah Rẹ eyiti o ko awọn ẹnu aala Rẹ sinu ati awọn idajọ Rẹ; ki ẹ le ba ronu sii, ki ẹ si le ba sisẹ pẹlu rẹ, ti ọwọ yin yoo fi waa tẹ oore ni aye ati ọjọ ikẹyin.
۞أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ خَرَجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَهُمۡ أُلُوفٌ حَذَرَ ٱلۡمَوۡتِ فَقَالَ لَهُمُ ٱللَّهُ مُوتُواْ ثُمَّ أَحۡيَٰهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ 243
Se imọ rẹ ko de - irẹ Anọbi - ibi iro awọn ti wọn jade ninu ile wọn, ti wọn si jẹ ẹda ti o pọ, ni ẹniti npaya iku, nitori ajalu ati ohun ti o yatọ sii, ati wipe awọn jẹ ikọ kan ninu bani Israheel, ni Ọlọhun Ọba Allah waa sọ fun wọn wipe: ẹ ku, wọn si ku, lẹyin igba naa ni Ọlọhun Ọba waa da wọn si alaaye, ki O le ba salaye fun wọn pe dajudaju gbogbo alamọri patapata ọwọ Rẹ ni o wa, mimọ fun Un, ati dajudaju awọn ko ni ikapa fun ẹmin ara wọn, anfaani kankan tabi inira, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọrẹ ni ati Ọla lori awọn eniyan, sugbọn ọpọlọpọ eniyan, wọn ko kii dupẹ fun Ọlọhun Ọba Allah lori awọn idẹra Rẹ.
وَقَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ 244
Ẹ maa ja - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ọta Ọlọhun Ọba Allah ni ogun, ni aranse fun ẹsin Rẹ ati gbigbe gbolohun Rẹ ga, ati wipe ki ẹ lọọ mọ pe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni ẹniti O ngbọ awọn gbolohun yin, ni O si mọ awọn adisọkan yin ati awọn isẹ yin, ati wipe Yoo si waa san yin lẹsan lori rẹ.
مَّن ذَا ٱلَّذِي يُقۡرِضُ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا فَيُضَٰعِفَهُۥ لَهُۥٓ أَضۡعَافٗا كَثِيرَةٗۚ وَٱللَّهُ يَقۡبِضُ وَيَبۡصُۜطُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 245
Taa ni ẹniti yoo se isẹ, ni isẹ ẹniti ndogo, ti yoo wa na owo rẹ si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah pẹlu adisọkan ti o dara, ati ẹmin ti o mọ, ki o le ba pada si ọdọ rẹ, ni awọn adipele ti o pọ, Ọlọhun Ọba Allah ma nse ifunpinpin nibi arisiki ati alaafia, ati ohun ti o yatọ sii, O si ma nse igbaaye nibi nkan naa patapata pẹlu ọgbọn Rẹ ati deede Rẹ, ọdọ Rẹ nikan ẹ yoo pada si ni Ọjọ Ikẹyin, Yoo si wa sanyin lẹsan lori awọn isẹ yin.
Sise ni ojukokoro lori mima sọ irun ati mima muwa ni ohun ti awọn origun pe ati awọn majẹmu, ti o ba wa le fun un, yoo ki lori bi o ba se rọọ lọrun ninu isesi.
Ikẹ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga pẹlu awọn ẹru Rẹ ni ohun ti o han, paapaa O ti se alaye fun wọn awọn aayah Rẹ, ni alaye ti o pe lati le ba se anfaani ninu rẹ.
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, paapaa O le dan apakan ni ori ilẹ wo, ti Yoo wa fun arisiki mọọ, O si ma ndan awọn miran wo pẹlu gbigbooro arisiki, O si nbẹ fun Un ninu nkan naa, idi ti o de ogongo.