إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ 23
Sugbọn ẹniti o ba gunri ninu wọn kuro nibi igbagbọ ti o wa se keferi si Allah ati ojisẹ Rẹ.
فَيُعَذِّبُهُ ٱللَّهُ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَكۡبَرَ 24
Allah yoo fi iya jẹ ẹ ni ọjọ igbende ni iya ti o tobi ju pẹlu ki o fi wọn ina jahannamọ gbere nibẹ.
إِنَّ إِلَيۡنَآ إِيَابَهُمۡ 25
Dajudaju isẹri wọn lẹyin iku wọn jẹ ọdọ Wa nikan.
ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا حِسَابَهُم 26
Lẹyin naa isiro wọn lori awọn isẹ wọn jẹ lọdọ wa nikan, ko si eleyi fun ọ tabi fun ẹlomiran ti o yatọ si.
سورة (MAKIYYAH)
Alaye igbẹyin awọn alagbeere, ati ọgbọn ti o wa nibi adanwo, ati irani leti nipa ọjọ ikẹhin.
وَٱلۡفَجۡرِ 1
Allah ti mimọ nbẹ fun fi idaji bura.
وَلَيَالٍ عَشۡرٖ 2
O si fi awọn oru ọjọ mẹwa akọkọ inu osu kejila oju ọrun bura.
وَٱلشَّفۡعِ وَٱلۡوَتۡرِ 3
O si fi tọkọtaya ati idawa nibi gbogbo nkan bura.
وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَسۡرِ 4
O si fi oru nigbati o ba de bura, ti o si tẹsiwaju, ti o pẹyin da, esi awọn ibura yii, paapaa julọ wọn yoo san yin lẹsan lori awọn isẹ yin.
هَلۡ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٞ لِّذِي حِجۡرٍ 5
Njẹ ibura wa fun onilaakaye nibi eyiti a sọ yii?!
أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ 6
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - bi Ọlọhun rẹ se se pẹlu Haadi tii se ijọ Huudu nigbati wọn pe ojisẹ Rẹ nirọ?!
إِرَمَ ذَاتِ ٱلۡعِمَادِ 7
Idile Haadi eyiti wọn se afiti rẹ si baba baba rẹ tii se Hirọmu alagbara.
ٱلَّتِي لَمۡ يُخۡلَقۡ مِثۡلُهَا فِي ٱلۡبِلَٰدِ 8
Eyiti Allah ko da apejuwe rẹ ni ilu naa.
وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُواْ ٱلصَّخۡرَ بِٱلۡوَادِ 9
Se o ko si ri bi Ọlọhun rẹ se se pẹlu Thamuudu ijọ Sọlihu, awọn ti wọn da apata ni oke lu, wọn si se awọn ile nibẹ pẹlu awọn yara.
وَفِرۡعَوۡنَ ذِي ٱلۡأَوۡتَادِ 10
Se o ko ri bi Ọlọhun rẹ se se pẹlu fir'aona eyiti o nfi awọn eekan ti o ni jẹ awọn eniyan niya?
ٱلَّذِينَ طَغَوۡاْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ 11
Gbogbo awọn wọnyi kọja ẹnu aala nibi agbara ati abosi, gbogbo ikọja ẹnu aala rẹ ni ilu rẹ.
فَأَكۡثَرُواْ فِيهَا ٱلۡفَسَادَ 12
Wọn si se ọpọ ibajẹ sibẹ pẹlu fifan keferi ati awọn ẹsẹ ka.
فَصَبَّ عَلَيۡهِمۡ رَبُّكَ سَوۡطَ عَذَابٍ 13
Allah si fun wọn ni iya ti o le koko tọ wo, O si pa wọn finfin lorilẹ.
إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلۡمِرۡصَادِ 14
Dajudaju Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - nmojuto awọn isẹ eniyan, o si nsọ ọ; ki o le san ẹniti o ba se daadaa lẹsan ọgba idẹra ati ẹniti o ba se aburu ni ina.
Nigbati awọn ijọ ti Allah mu iparun jẹ ẹniti o wọn se idẹkun agbara ati idaabobo fun, O salaye wipe sise idẹkun eleyi fun ni kii se itọka lori iyọnu Allah le wọn lori, O wa sọpe:
فَأَمَّا ٱلۡإِنسَٰنُ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكۡرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَكۡرَمَنِ 15
Sugbọn ọmọniyan ninu isesi rẹ nipe ti Ọlọhun rẹ ba dan wọn ti o si pọn le, ki o si se idẹkun owo ati awọn ọmọ ati iyi fun un, yoo lero wipe eleyi jẹ apọnle fun oun ni ọdọ Allah, yoo wa sọpe: Ọlọhun mi pọn mi le nitoripe mo lẹtọ si apọnle Rẹ.
وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيۡهِ رِزۡقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَهَٰنَنِ 16
Sugbọn ti O ba dan an wo, ti O si fun lẹ arisiki mọ ọ, dajudaju yoo lero wipe eleyi jẹ iyẹpẹrẹ rẹ lati ọdọ Ọlọhun rẹ, yoo wa sọpe: Ọlọhun mi yẹpẹrẹ mi.
كَلَّاۖ بَل لَّا تُكۡرِمُونَ ٱلۡيَتِيمَ 17
Ko ri bẹẹ, ọrọ ko ri bi ọmọniyan se ya aworan rẹ nipa wipe idẹkun jẹ itọka lori iyọnu Allah si ẹru Rẹ atipe dajudaju idaamun jẹ itọka lori iyẹpẹrẹ ẹru lọdọ Ọlọhun rẹ, bikosepe ohun ti o sẹlẹ ni pe ẹ ko se apọnle ọmọ orukan ninu ohun ti Allah se fun, ti O fun yin ni arisiki.
وَلَا تَحَٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ 18
Apakan yin ko si ta apakan nidi lati fun alaini ni ounjẹ eyiti ko ri nkan ti yoo jẹ.
وَتَأۡكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكۡلٗا لَّمّٗا 19
Ẹ si njẹ awọn ẹtọ awọn ọlẹ ninu awọn obinrin ati awọn ọmọ orukan ni jijẹ gidigidi laiwoye si lilẹtọ rẹ.
وَتُحِبُّونَ ٱلۡمَالَ حُبّٗا جَمّٗا 20
Ẹ si nifẹ si owo ni ifẹ ti o pọ, ni ẹ fi se ahun si nina si oju ọna Allah ni oju kokoro le lori.
كَلَّآۖ إِذَا دُكَّتِ ٱلۡأَرۡضُ دَكّٗا دَكّٗا 21
Ko tọ ki eleyi jẹ isẹ yin, ki ẹ ran nigbati wọn ba gbọn ilẹ niti gbigbọn ti o le koko, ti wọn si min in.
وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلۡمَلَكُ صَفّٗا صَفّٗا 22
Ti Ọlọhun rẹ si de - irẹ ojisẹ - lati se opinya laarin awọn ẹru Rẹ, ti awọn Malaaika naa si de ni tito lọwọọwọ.
Ọla ti nbẹ fun ọjọ mẹwa ose kejila lori awọn ọjọ ọdun.
Ririnlẹ wiwa Allah ti o ga ni ọjọ igbende ni ibamun si bi o se lẹtọ si i; laisi afijọ tabi afiwe tabi ifakunnu.
Olugbagbọ ododo ti wọn ba dan wo yoo se suuru, ti wọn ba si fun ni nkan yoo dupẹ.