وَكَذَٰلِكَ مَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي قَرۡيَةٖ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتۡرَفُوهَآ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٖ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّقۡتَدُونَ 23
Gẹgẹ bi awọn eniyan wọnyi se parọ, ti wọn si fi ikọse awọn baba wọn se awijare, a ko gbe dide siwaju rẹ - irẹ ojisẹ - ojisẹ kan ninu abule kan ti o nse ikilọ fun awọn ijọ rẹ ayaafi ki awọn olori wọn ati awọn agbalagba inu wọn ninu awọn ọlọrọ inu wọn sọ wipe: dajudaju awa ri awọn baba wa lori ẹsin kan ati ọna kan ati wipe dajudaju awa yoo jẹ olutẹle oripa wọn, ijọ rẹ kii se ipilẹ nibi eleyi.
۞قَٰلَ أَوَلَوۡ جِئۡتُكُم بِأَهۡدَىٰ مِمَّا وَجَدتُّمۡ عَلَيۡهِ ءَابَآءَكُمۡۖ قَالُوٓاْ إِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ 24
Ojisẹ wọn sọ fun wọn: se ẹ o maa tẹle awọn baba yin koda bi wọn mu wa ba yin ohun ti o loore oju ọna wọn lọ eyiti wọn wa lori rẹ? Wọn sọpe: dajudaju awa jẹ olutako eyiti wọn fi ran ọ iwọ ati awọn ti o siwaju rẹ ninu awọn ojisẹ.
فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ 25
A si gbẹsan lara awọn ijọ eyiti o pe awọn ojisẹ nirọ siwaju rẹ, bẹẹni a pa wọn run, woye si bawo ni igbẹyin awọn opurọ olupe ojisẹ wọn nirọ yoo se ri, paapaa igbẹyin wọn jẹ inira.
وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦٓ إِنَّنِي بَرَآءٞ مِّمَّا تَعۡبُدُونَ 26
Tun ranti - irẹ ojisẹ - nigbati Ibrahim nsọ fun baba rẹ ati awọn ijọ rẹ: dajudaju emi bọpa kuro nibi ohun ti ẹ nsin yatọ si Allah.
إِلَّا ٱلَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُۥ سَيَهۡدِينِ 27
Ayaafi Allah eyiti o da mi, dajudaju Oun ni yoo tọ mi sọna ohun ti yoo se mi ni anfaani gẹgẹ bi titẹle ẹsin Rẹ ti o duro tọ.
وَجَعَلَهَا كَلِمَةَۢ بَاقِيَةٗ فِي عَقِبِهِۦ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 28
Ibrahin si sọ gbolohun ọkan soso di (ko si ọba kan ayaafi Allah) ohun ti o sẹku si inu arọmọdọmọ rẹ ni ẹyin rẹ, ko nii yẹ ko nii gbo ninu wọn ẹniti yoo maa pe Allah ni ọkan, ti ko si nii se ẹbọ kankan pẹlu Rẹ; ni irankan ki wọn sẹri si ọdọ Allah pẹlu ironu piwada lọsi ọdọ Rẹ kuro nibi ẹbọ ati awọn ẹsẹ.
بَلۡ مَتَّعۡتُ هَٰٓؤُلَآءِ وَءَابَآءَهُمۡ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ وَرَسُولٞ مُّبِينٞ 29
Nko ko kanju mu iparun ba awọn ẹlẹbọ opurọ yii bikosepe mo fi sisẹku si ile aye se idẹkun fun wọn, mo si fi se idẹkun fun awọn baba wọn ti o siwaju wọn titi ti Alukuraani fi waa ba wọn ati ojisẹ ti o fi oju han, oun ni Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
وَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٞ وَإِنَّا بِهِۦ كَٰفِرُونَ 30
Nigbati Alukuraani yii eyiti o jẹ ododo yii wa ba wọn eyiti ko si iyemeji nibẹ, wọn sọpe: eleyi jẹ idan ti Muhammad fi bo wa loju, awa si jẹ ẹniti o ta ko o, a ko le ni igbagbọ si i.
وَقَالُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ عَلَىٰ رَجُلٖ مِّنَ ٱلۡقَرۡيَتَيۡنِ عَظِيمٍ 31
Awọn ẹlẹbọ opurọ naa sọpe: kilode ti Allah ko sọ Alukuraani yii kalẹ fun ọkan ninu awọn ọkunrin meji ti o tobi ni ilu Mẹka tabi Tahif, awọn mejeeji si ni Waliid ọmọ Hukuba ati Huruwa ọmọ Mas’uud ara sakọfi dipo ti o fi sọkalẹ fun Muhammad alaini ọmọ orukan.
أَهُمۡ يَقۡسِمُونَ رَحۡمَتَ رَبِّكَۚ نَحۡنُ قَسَمۡنَا بَيۡنَهُم مَّعِيشَتَهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَرَفَعۡنَا بَعۡضَهُمۡ فَوۡقَ بَعۡضٖ دَرَجَٰتٖ لِّيَتَّخِذَ بَعۡضُهُم بَعۡضٗا سُخۡرِيّٗاۗ وَرَحۡمَتُ رَبِّكَ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ 32
Se awọn ni wọn npin ikẹ Ọlọhun rẹ ni - irẹ ojisẹ - ti wọn se wa nfu ẹniti o wu wọn, ti wọn si nkọ fun ẹniti o wu wọn tabi Allah ni? Awa ni a npin arisiki laarin wọn ni ile aye, a si se ọlọrọ ati olosi ni inu wọn; ki apakan wọn le maa fi apakan se iyanran si apakan, ikẹ Ọlọhun rẹ fun awọn ẹru Rẹ ni ọrun loore ju ohun ti awọn wọnyi ko jọ ninu ọrọ ile aye ti yoo tan lọ.
وَلَوۡلَآ أَن يَكُونَ ٱلنَّاسُ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ لَّجَعَلۡنَا لِمَن يَكۡفُرُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ لِبُيُوتِهِمۡ سُقُفٗا مِّن فِضَّةٖ وَمَعَارِجَ عَلَيۡهَا يَظۡهَرُونَ 33
Tii kii ba sepe awọn eniyan jẹ ijọ kan soso nibi keferi, a ko ba se aga lati ibi fadaka si ile awọn ẹniti o ba se aimoore si Allah, a ko ba si se akasọ fun wọn ti wọn yoo maa gun.
Ikọse wa ninu awọn okunfa isọnu awọn ijọ ti o siwaju
Bibọpa bọsẹ kuro nibi keferi ati awọn alaimoore jẹ dandan
Pinpin arisiki jẹ ohun ti o wa ninu abẹ ọgbọn Allah
Yiyẹpẹrẹ aye ni ọdọ Allah ti o ba jasipe o se deede iyẹ ẹfọn ko ni fun keferi omi mu nibẹ.