ذَٰلِكَ ٱلَّذِي يُبَشِّرُ ٱللَّهُ عِبَادَهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِۗ قُل لَّآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًا إِلَّا ٱلۡمَوَدَّةَ فِي ٱلۡقُرۡبَىٰۗ وَمَن يَقۡتَرِفۡ حَسَنَةٗ نَّزِدۡ لَهُۥ فِيهَا حُسۡنًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ شَكُورٌ 23
Iro idunnu ti o tobi yii eyiti Allah fun awọn ti o nigbagbọ si Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si nse awọn isẹẹre lati ọdọ ojisẹ Rẹ, sọ - irẹ ojisẹ -: nko wa ẹsan lọdọ yin lori mimu ododo dopin ayaafi ẹsan kan soso ti anfaani rẹ yoo si sẹri pada wa ba yin, ohun si ni ki ẹ nifẹ mi nitori asunmọ mi si yin, ẹniti o ba se daadaa kan, wọn yoo se adipele ẹsan fun un; daadaa kan se deedee mẹwa iru rẹ lẹsan, dajudaju Allah jẹ alaforijin ẹsẹ ẹiti o ba sẹri lọsi ọdọ Rẹ ninu awọn ẹru Rẹ, Ọba Olumọriri awọn isẹẹre eyiti wọn ba se lati wa oju rere Rẹ.
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗاۖ فَإِن يَشَإِ ٱللَّهُ يَخۡتِمۡ عَلَىٰ قَلۡبِكَۗ وَيَمۡحُ ٱللَّهُ ٱلۡبَٰطِلَ وَيُحِقُّ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 24
Ninu erongba awọn ẹlẹbọ nipe dajudaju Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun hun Alukuraani yii, o si se afiti rẹ si ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, Allah sọ ni ẹniti o nfesi fun wọn: ti o ba ba ẹmin rẹ sọrọ lati hun irọ emi ko ba fi edidi di ọkan rẹ, bẹẹni emi ko ba pa ibajẹ ti o hun rẹ, maa si sẹ ododo ku, sugbọn nigbati ọrọ ko ri bẹẹ nitori imisi wa lati ọdọ Ọlọhun rẹ ti jẹ itọka lori jijẹ ododo anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, dajudaju O jẹ onimimọ nipa ohun ti o wa ninu ọkan awọn ẹru Rẹ, nkankan ko si pamọ fun Un nibẹ.
وَهُوَ ٱلَّذِي يَقۡبَلُ ٱلتَّوۡبَةَ عَنۡ عِبَادِهِۦ وَيَعۡفُواْ عَنِ ٱلسَّئَِّاتِ وَيَعۡلَمُ مَا تَفۡعَلُونَ 25
Oun ti mimọ nbẹ fun ni o gba ironu piwada awọn ẹru Rẹ kuro nibi keferi ati awọn ẹsẹ nigbati wọn ba sẹri lọ si ọdọ Rẹ, O si ma nse amojukuro awọn asise wọn eyiti wọn se, O si mọ ohun ti ẹ nse, nkankan ninu awọn isẹ yin ko pamọ fun Un, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَيَسۡتَجِيبُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضۡلِهِۦۚ وَٱلۡكَٰفِرُونَ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞ 26
O ma njẹpe awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, ti wọn si nse awọn isẹẹre, O si ma nse alekun ninu ọla Rẹ fun ẹniti ko ba bi leere, iya ti o lagbara nreti awọn ti o se keferi si Allah ati ojisẹ Rẹ ni ọjọ igbende.
۞وَلَوۡ بَسَطَ ٱللَّهُ ٱلرِّزۡقَ لِعِبَادِهِۦ لَبَغَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَٰكِن يُنَزِّلُ بِقَدَرٖ مَّا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرُۢ بَصِيرٞ 27
Ti Allah ba gbaaye arisiki fun gbogbo awọn ẹru Rẹ, wọn ko ba kọja ẹnu aala lorilẹ pẹlu abosi sise sugbọn Oun ti mimọ nbẹ fun ma nsọ arisiki kalẹ pẹlu odiwọn ohun ti o ba fẹ ki o gbaaye tabi ki o fun, Oun si ni olufunni niro ati oluri awọn isesi awọn ẹru Rẹ, O ma nfunni nitori ọgbọn kan, O si ma nkọ fun ni nitori ọgbọn miran.
وَهُوَ ٱلَّذِي يُنَزِّلُ ٱلۡغَيۡثَ مِنۢ بَعۡدِ مَا قَنَطُواْ وَيَنشُرُ رَحۡمَتَهُۥۚ وَهُوَ ٱلۡوَلِيُّ ٱلۡحَمِيدُ 28
Oun ni ẹniti o nsọ ojo kalẹ fun awọn ẹru Rẹ lẹyin igbati wọn ti jakan kuro nibi sisọkalẹ rẹ, O ma nfan ojo yii ti irugbin yoo si jade ninu rẹ, Oun ni ẹniti o la ọrọ awọn ẹru RẸ bọrun, ẹniti a si gbọdọ maa dupẹ fun lori gbogbo isesi.
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ خَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَثَّ فِيهِمَا مِن دَآبَّةٖۚ وَهُوَ عَلَىٰ جَمۡعِهِمۡ إِذَا يَشَآءُ قَدِيرٞ 29
Ninu awọn amin Allah ti o tọka si Agbara Rẹ ati ijọkan soso Rẹ ni isẹda gbogbo sanmọ ati isẹda gbogbo ilẹ ati ohun ti o fanka sinu mejeeji ninu awọn ẹda ti o jẹ eemọ, Oun si ni alagbara lori kiko wọn jọ fun akojọ ati ẹsan ti igbati O ba fẹ, eleyi ko le ko agara ba A gẹgẹ bi isẹda wọn ni igba akọkọ ko ko agara ba A.
وَمَآ أَصَٰبَكُم مِّن مُّصِيبَةٖ فَبِمَا كَسَبَتۡ أَيۡدِيكُمۡ وَيَعۡفُواْ عَن كَثِيرٖ 30
Eyiti o ba kan yin - ẹyin eniyan - ninu awọn adanwo lara yin tabi awọn dukia yin jẹ nibi ohun ti ẹ fi ọwọ ara yin da ninu awọn ẹsẹ, Allah se amojukuro ọpọ ninu rẹ fun yin, ti kii gba yin mu pẹlu rẹ.
وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ 31
Ẹyin ko jẹ ẹniti o lagbara lori lila ni ọdọ Ọlọhun yin lati salọ nigbati O ba gberio iya fun yin, bẹẹni ko si alatilẹyin ti yoo gba ọrọ yinyatọ si I fun yin, bbẹni ko si alaranse ti yoo mu iya naa kuro fun yin ti o ba gbero rẹ pẹlu yin.
Olupepe si ọdọ Allah ko gbọdọ wa ẹsan ni ọdọ awọn eniyan.
Gbigbaaye nibi arisiki tabi fifun un mọni wa labẹ ọgbọn Ọlọhun, paapaa o le pamọ fun ọpọ awọn eniyan.
Awọn ẹsẹ ati awọn asise wa ninu okunfa awọn adanwo.