وَلَا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ عِندَهُۥٓ إِلَّا لِمَنۡ أَذِنَ لَهُۥۚ حَتَّىٰٓ إِذَا فُزِّعَ عَن قُلُوبِهِمۡ قَالُواْ مَاذَا قَالَ رَبُّكُمۡۖ قَالُواْ ٱلۡحَقَّۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ 23
Ipẹ ko nii se anfaani lọdọ Rẹ ti mimọ nbẹ fun ayaafi fun ẹniti O ba yọnda fun, Allah ko nii yọnda nibi ipẹ ayaafi fun ẹniti O ba yọnu si; nitori titobi Rẹ ninu titobi Rẹ nipe ti O ba sọrọ ni sanmọ awọn Malaika yoo na iyẹ wọn niti itẹriba fun ọrọ Rẹ titi ipaya yoo fi kuro ni ọkan wọn, awọn malaika yoo wa sọ fun jibril: kinni Ọlọhun yin sọ? Jibril yoo wa sọpe: O sọ ododo, Oun si ni ẹniti o ga ju nibi bibẹ Rẹ ati ibori Rẹ, ẹniti o tobi ju, ti gbogbo nkan wa ni isalẹ Rẹ.
۞قُلۡ مَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ قُلِ ٱللَّهُۖ وَإِنَّآ أَوۡ إِيَّاكُمۡ لَعَلَىٰ هُدًى أَوۡ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 24
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi: taani o ran yin se lati sanmọ pẹlu sisọ ojo kalẹ, ati ni ilẹ pẹlu mimu awọn eso ati awọn irugbin ati awọn ipapanu jade ati eyiti o yatọ siyẹn? Sọ: Allah ni O nse aranse fun yin ninu rẹ ati awa tabi ẹyin - ẹyin ẹlẹbọ - ni o wa ni oju ọna tabi anu ti o han kuro ni oju ọna, ikan ninu wa ko si iyemeji ni o wa bẹẹ, ko si si iyemeji lori wipe awọn ẹni imọna ni awọn olugbagbọ ododo ati wipe awọn ẹni anu ni awọn ẹlẹbọ.
قُل لَّا تُسَۡٔلُونَ عَمَّآ أَجۡرَمۡنَا وَلَا نُسَۡٔلُ عَمَّا تَعۡمَلُونَ 25
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: wọn ko nii bi yin leere nipa ẹsẹ wa eyiti a da ni ọjọ igbende, wọn ko si nii bi wa leere nipa eyiti ẹyin se.
قُلۡ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَا رَبُّنَا ثُمَّ يَفۡتَحُ بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَهُوَ ٱلۡفَتَّاحُ ٱلۡعَلِيمُ 26
Sọ fun wọn: Ọlọhun Ọba yoo ko wa jọ ati ẹyin naa ni ọjọ igbende, lẹyin naa yoo se idajọ laarin wa ati ẹyin naa niti deede, bayi ni ẹniti o tọ yoo hande kuro nibi olubilẹjẹ, Oun si ni dajọ dajọ tii ma dajọ pẹlu deede, Onimimọ pẹlu ohun ti o dajọ le lori.
قُلۡ أَرُونِيَ ٱلَّذِينَ أَلۡحَقۡتُم بِهِۦ شُرَكَآءَۖ كَلَّاۚ بَلۡ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 27
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ: ẹ fi han mi awọn ti ẹ gbe kalẹ ni akẹgbẹ pẹlu Allah ti ẹ nse bẹbọ pẹlu Rẹ nibi ijọsin, ko ri bẹẹ, ọrọ ko ri bi ẹ se ya aworan rẹ nibi wipe O ni akẹgbẹ bikosepe Oun ni Allah alagbara ti ẹnikankan ko le bori Rẹ, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati ipebubu Rẹ ati idari eto Rẹ.
وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا كَآفَّةٗ لِّلنَّاسِ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ 28
A ko gbe ọ dide - irẹ ojisẹ - ayaafi fun awọn eniyan ni apapọ, ki o si jẹ oniro idunnu fun awọn olupaya wipe ọgba idẹra nbẹ fun wọn, bẹẹni ki o jẹ oludẹrubani fun awọn keferi ati ẹlẹsẹ nipa ina, sugbọn ọpọ awọn eniyan ko mọ eleyi, ti wọn ba mọ ọ ni wọn ko ba ti pe ọ nirọ.
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 29
Awọn ẹlẹbọ nsọrọ ni ẹniti nkanju iya eyiti wọn fi ndẹru ba wọn: nigba wo ni adehun iya yii ti ẹ ba jẹ sootọ sootọ nibi ohun ti ẹ npe wipe o jẹ ododo?
قُل لَّكُم مِّيعَادُ يَوۡمٖ لَّا تَسۡتَٔۡخِرُونَ عَنۡهُ سَاعَةٗ وَلَا تَسۡتَقۡدِمُونَ 30
Sọ - irẹ ojisẹ - fun olukanju iya wọnyi: adehun nbẹ fun yin ni ọjọ ti o ni aala; wakati kan ko le lọ lara fun yin, wọn ko si le fi wakati kan gba iwaju rẹ, ọjọ yii ni ọjọ igbende.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن نُّؤۡمِنَ بِهَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ وَلَا بِٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِۗ وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّٰلِمُونَ مَوۡقُوفُونَ عِندَ رَبِّهِمۡ يَرۡجِعُ بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٍ ٱلۡقَوۡلَ يَقُولُ ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُواْ لَوۡلَآ أَنتُمۡ لَكُنَّا مُؤۡمِنِينَ 31
Awọn ti o se keferi si Allah sọpe: a ko nii nigbagbọ si Alukuraani eyiti Muhammad nlero wipe o sọkalẹ fun oun, bẹẹni a ko nii nigbagbọ si awọn iwe sanmọ ti o siwaju, ti o ba ri ni - irẹ ojisẹ - igbati wọn ba mu awọn alabosi mọlẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ni ọjọ igbende fun isiro ti ọrọ nlọ ti o nbọ laarin ara wọn, ti ikọọkan wọn nju ojuse ati eebu si ẹlomiran, awọn olutẹle ti wọn jẹ ọlẹ yoo ma sọ fun awọn asiwaju ti o sọ wọn di ọlẹ ni ile aye: ti kii ba se wipe ẹ sọ wa nu, awa ko ba jẹ olugbagbọ si Allah ati awọn ojisẹ Rẹ.
Sise pẹlẹ pẹlu ẹniti a npe ti ko fi nii lugọ si ibi orikunkun ati igberaga.
Ẹni imọna yoo maa gberaga pẹlu imọna, tii yoo si maa gbe ga, bẹẹni ẹni anu yoo tẹri sinu rẹ, yoo si yẹpẹrẹ.
Kikari isẹ anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun fun gbogbo abara lapapọ ati alujannu bakkanna.