مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ رِجَالٞ صَدَقُواْ مَا عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ عَلَيۡهِۖ فَمِنۡهُم مَّن قَضَىٰ نَحۡبَهُۥ وَمِنۡهُم مَّن يَنتَظِرُۖ وَمَا بَدَّلُواْ تَبۡدِيلٗا 23
Awọn ọkunrin olododo pẹlu Allah nbẹ ninu awọn olugbagbọ ododo, ti wọn npe ohun ti wọn se ni adehun pẹlu Rẹ gẹgẹ bi iduro sinsin ati suuru lori igbiyanju si oju ọna Allah, o wa ninu wọn ẹniti o ku tabi wọn pa a si oju ọna Allah, o si wa ninu wọn ẹniti nreti kiku si oju ọna Rẹ, bẹẹni awọn olugbagbọ ododo yii ko yi ohun ti wọn ba Allah se ni adehun, iru ohun ti awọn sọbẹ selu se nibi adehun ti wọn.
لِّيَجۡزِيَ ٱللَّهُ ٱلصَّٰدِقِينَ بِصِدۡقِهِمۡ وَيُعَذِّبَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ إِن شَآءَ أَوۡ يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا 24
Ki Allah le sẹsan fun awọn sootọ sootọ ti wọn pe adehun ti wọn se pẹlu Allah ododo wọn ati pipe adehun wọn, ki o si le fi iya jẹ awọn sọbẹ selu oluja adehun ti O ba fẹ pẹlu ki O mu iku ba wọn siwaju ironu piwada kuro nibi keferi wọn tabi ki o gba ironu piwada wọn pẹlu ki o fi wọn se kongẹ aforijin, bẹẹni Allah si sẹ oluforijinni fun ẹniti o ba ronu piwada kuro nibi awọn ẹsẹ rẹ, o si jẹ onikẹ si i.
وَرَدَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِغَيۡظِهِمۡ لَمۡ يَنَالُواْ خَيۡرٗاۚ وَكَفَى ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلۡقِتَالَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزٗا 25
Allah da Quraysh ati gatfaanu ati awọn ti o wa pẹlu wọn pada pẹlu ibanujẹ wọn ati ironu wọn nitori bibọ nkan ti wọn gbero, wọn ko gbere pẹlu ohun ti wọn gbero nipa kiku finfin awọn olugbagbọ ododo, allah si to fun awọn olugbagbọ ododo ni olubajagun pẹlu wọn; pẹlu atẹgun riran ati siọ awọn Malaika kalẹ Rẹ, Allah jẹ alagbara, Oniyi ti ẹnikankan ko le bori Rẹ ayaafi ki O bori tabi ki O yẹpẹrẹ ẹni naa.
وَأَنزَلَ ٱلَّذِينَ ظَٰهَرُوهُم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن صَيَاصِيهِمۡ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَ فَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ وَتَأۡسِرُونَ فَرِيقٗا 26
Allah tun sọ awọn ti o ran wọn lọwọ kalẹ gẹgẹ bi yahuudi nibi idaabobo wọn eyiti wọn fi ndaabobo ara wọn kuro nibi ọta wọn, o si ju ipaya si wọn ninu ẹmin, ẹ pa apakan ninu wọn -ẹyin olugbagbọ ododo- bẹẹ si ni ẹ mu apakan lẹru ninu wọn.
وَأَوۡرَثَكُمۡ أَرۡضَهُمۡ وَدِيَٰرَهُمۡ وَأَمۡوَٰلَهُمۡ وَأَرۡضٗا لَّمۡ تَطَُٔوهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٗا 27
Allah fun yin nikapa lori ilẹ wọn ati awọn irugbin ati igi ọpẹ ti o wa nibẹ lẹyin iparun wọn, o si fun yin nikapa lori awọn ibugbe wọn ati awọn dukia wọn miran, bakanna o fun yin nikapa lori ilẹ kaeybar eyiti ẹ ko tii fi ẹsẹ tẹ rara, sugbọn ẹyin yoo pada fi ẹsẹ tẹ ẹ, eleyi jẹ adehun ati iro idunnu fun awọn olugbagbọ ododo, bẹẹni Allah jẹ alagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko ka A lagara.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّأَزۡوَٰجِكَ إِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا فَتَعَالَيۡنَ أُمَتِّعۡكُنَّ وَأُسَرِّحۡكُنَّ سَرَاحٗا جَمِيلٗا 28
Irẹ anọbi sọ fun awọn iyawo rẹ ti wọn ba nfẹ igbaaye si nibi inawo, ti ko si si ohun ti o fi gba wọn laaye lọdọ rẹ: ti ẹ ba ngbero isẹmin aye ati ohun ti nbẹ nibẹ lọsọ, ki ẹ wa si ọdọ mi, emi yoo fun yin ni igbadun ni igbadun awọn iyawo ti a kọ ti ma nri, emi yoo si kọ yin ni kikọ ti ko si inira nibẹ tabi suta.
وَإِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَ فَإِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡمُحۡسِنَٰتِ مِنكُنَّ أَجۡرًا عَظِيمٗا 29
Ti ẹ ba si nfẹ iyọnu Allah ati iyọnu ojisẹ rẹ, ti ẹ tun nfẹ ọgba idẹra ni ile ikẹyin, ki ẹya se suuru lori isesi yin dajudaju Allah ti se adehun fun ẹniti o ba se suuru ti o dara ati ẹsan ti o tobi fun ẹniti o ba mu ibalopọ rere.
يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ مَن يَأۡتِ مِنكُنَّ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖ يُضَٰعَفۡ لَهَا ٱلۡعَذَابُ ضِعۡفَيۡنِۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا 30
Ẹyin obinrin anọbi, ẹniti o ba da ẹsẹ ti o fi oju han, wọn yoo se adipele iya fun un ni ọjọ igbende ni ipele meji nitori ipo rẹ ati aaye rẹ ati lati daabobo abala anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, bẹẹni ise adipile yii jẹ ohun ti o rọrun fun Allah.
Fifọmọ lati ọdọ Allah fun awọn ọmọlẹyin ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, o si jẹ iyi ti o tobi fun wọn.
Aanu Allah ati aranse Rẹ fun awọn ẹru Rẹ nibiti wọn ko ti lero nigbati wọn ba paya Allah.
Biburu igbẹyin idalẹ fun awọn yahuudi ti o nran awọn ijọ lọwọ.
Sisẹsa iyọnu Allah ati ojisẹ Rẹ jẹ ẹri lori lilagbar igbagbọ wọn.