أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يُدۡعَوۡنَ إِلَىٰ كِتَٰبِ ٱللَّهِ لِيَحۡكُمَ بَيۡنَهُمۡ ثُمَّ يَتَوَلَّىٰ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ وَهُم مُّعۡرِضُونَ 23
Se o ko wa bojuwo - irẹ Anọbi - isesi awọn Yahuudi ni, awọn ti Ọlọhun Ọba Allah fun ni ipin kan ninu imọ pẹlu Taoraata, ati ohun ti o tọka si ijẹ Anọbi rẹ, ti wọn npe wọn lọ si bi pipada si ibi tira Ọlọhun Ọba Allah tii se Taoraata, ki o le ba se dajọ laarin wọn nibi nkan ti wọn nse iyapa ẹnu nibẹ, lẹyin igba naa ni ikọ kan yoo pẹyinda ninu awọn onimimọ wọn ati awọn olori wọn, ni ẹniti o gunri kuro nibi idajọ rẹ nigbati ko se deede awọn ifẹ inu wọn, ati wipe eyiti o dara fun wọn ju - ti wọn si nlero titẹle wọn sii - niki wọn jẹ ẹniti yoo yara ju ninu awọn eniyan lọsi bi mimu ẹjọ lọ si ọdọ rẹ.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۖ وَغَرَّهُمۡ فِي دِينِهِم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ 24
Ipẹyinda naa kuro nibi ododo ati igunri kuro nibẹ, nitoripe awọn jẹ ẹniti o ma nsọ ọrọ ti ko ri bẹẹ wipe: dajudaju ina ko le fi ọwọ ba wọn ni Ọjọ Igbende ayaafi ọjọ kekere, lẹyin igba naa ni wọn yoo waa wọ Ọgba Idẹra, ni ero naa ba tan wọn jẹ, eyiti wọn hun fun ara wọn ninu awọn ọrọ irọ ati awọn ibajẹ, ni wọn ba se ayakoko-nnaki si Ọlọhun Ọba Allah ati ẹsin Rẹ.
فَكَيۡفَ إِذَا جَمَعۡنَٰهُمۡ لِيَوۡمٖ لَّا رَيۡبَ فِيهِ وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 25
Bawo ni isesi wọn yoo se ri ati abamọ wọn? ! Yoo pada jẹ ohun ti o de ogongo ninu aburu nigbati A ba ko wọn jọ fun sise isiro isẹ ni ọjọ kan ti ko si iyemeji nibẹ, ohun naa ni Ọjọ Igbende ati wipe wọn yoo fun ẹmin kọọkan ni ẹsan ohun ti o ba se, lori odiwọn ohun ti o ba ni ẹtọ si laini se abosi kankan pẹlu sise adinku awọn daada rẹ, tabi sise alekun awọn aida rẹ.
قُلِ ٱللَّهُمَّ مَٰلِكَ ٱلۡمُلۡكِ تُؤۡتِي ٱلۡمُلۡكَ مَن تَشَآءُ وَتَنزِعُ ٱلۡمُلۡكَ مِمَّن تَشَآءُ وَتُعِزُّ مَن تَشَآءُ وَتُذِلُّ مَن تَشَآءُۖ بِيَدِكَ ٱلۡخَيۡرُۖ إِنَّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 26
Sọ - irẹ Ojisẹ - ni ẹniti o nse ẹyin fun Ọlọhun Ọba rẹ, ti o si ngbe tobi wipe: Irẹ Ọlọhun Ọba Allah, Iwọ ni Ẹniti O ni ikapa gbogbo ọla ni aye ati ni ọrun, O si ma nfun ẹniti o ba wu Ọ ninu awọn ẹda Rẹ ni ọla, O si ma njagba kuro ni ọwọ ẹniti o ba wu Ọ, O si ma nfun ẹniti o ba wu Ọ ni iyi ninu wọn, O si ma nyẹpẹrẹ ẹniti o ba wu Ọ, ati wipe gbogbo nkan naa wa pẹlu oye Rẹ ati deede Rẹ, ati wipe ọwọ Rẹ nikan ni gbogbo oore wa, ati Iwọ ni Alagbara lori gbogbo nkan.
تُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَتُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِۖ وَتُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَتُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّۖ وَتَرۡزُقُ مَن تَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ 27
Ati wipe ninu awọn afihan agbara Rẹ ni wipe dajudaju Iwọ ma nti oru bọ inu ọsan, ti yoo waa mu asiko ọsan gun, O si tun ma nfi ọsan bọ inu oru, ti yoo si mu asiko oru gun, O si tun ma nmu alaaye jade kuro nibi oku; gẹgẹ bi mimu olugbagbọ ododo jade lati ara alaigbagbọ, ati ọgbin lati ara horo, ati wipe O tun ma nmu oku jade lati ara alaaye; gẹgẹ bi alaigbagbọ lati ara olugbagbọ ododo, ati ẹyin lati ara abo adirẹ, ati wipe O ma nse arisiki fun ẹniti o ba wu Ọ, ni arisiki ti o fẹ laini isiro tabi onka.
لَّا يَتَّخِذِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَلَيۡسَ مِنَ ٱللَّهِ فِي شَيۡءٍ إِلَّآ أَن تَتَّقُواْ مِنۡهُمۡ تُقَىٰةٗۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ 28
Ẹ mase mu - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn alaigbagbọ ni awọn aayo, ti ẹ o nifẹ wọn, ti ẹ o si maa se aransr fun wọn, yatọ si awọn olugbagbọ ododo, ẹniti o ba se nkan naa, paapaa o ti bọ kuro ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba Allah naa si ti yọwọ kuro ni ọdọ rẹ, ayaafi ti ẹ ba wa ni abẹ isejọba wọn, ti ẹ wa npaya fun lori awọn ẹmin yin, ko si inira kankan nibi ki ẹ paya suta wọn, pẹlu sise afihan ẹlẹ ninu ọrọ sisọ ati rirọ nibi isẹ sise, pẹlu pe ki ẹ pa ibawọnsọta mọ fun wọn, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah nkilọ ẹmin ara Rẹ fun yin, ki ẹ ya paya Rẹ, ki ẹ si mase sẹri si ibinu Rẹ, pẹlu mima mu awọn iyapa wa, ati wipe ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan ni ibupadasi awọn ẹrusin ni Ọjọ Igbende, lati le ba san wọn ni ẹsan lori awọn isẹ wọn.
قُلۡ إِن تُخۡفُواْ مَا فِي صُدُورِكُمۡ أَوۡ تُبۡدُوهُ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 29
Sọ - irẹ Anọbi - wipe ti ẹ ba fi ohun ti o wa ninu igbaya yin pamọ, ninu awọn nkan ti Ọlọhun Ọba Allah kọ fun yin nibẹ, gẹgẹ bi mimu awọn alaigbagbọ ni aayo, tabi ti ẹyin ba fi nkan naa han, Ọlọhun Ọba Allah mọọ, ko si si nkankan ti yoo pamọ fun Un, ati wipe O mọ ohun ti o nbẹ ninu awọn sanmọ ati inu ilẹ, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Alagbara lori gbogbo nkan, ti nkankan ko si le ko agara ba A.
Dajudaju ifini se kongẹ ati ifini mọna ma nwa lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ati wipe imọ - biotiwulẹ ki o pọ to, ti ẹniti o ni si de ogongo ninu eyiti o ga ninu ipo - ti kongẹ Ọlọhun Ọba Allah ko ba wa pẹlu rẹ, ọmọniyan ko nii se anfaani pẹlu rẹ.
Dajudaju ọla ti Ọlahun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) nii se, Oun ni Olufuni ati Olukọfunni, Olufuni ni iyi ati Oluyẹpẹrẹ ẹni, ọwọ Rẹ ni gbogbo oore wa, ati wipe ọdọ Rẹ ni gbogbo alamọri yoo pada si, wọn ko nii bi ẹnikankan leere yatọ siI.
Ewu ti nbẹ nibi mimu awọn alaigbagbọ ni aayo, nibi ti Ọlọhun Ọba Allah ti se adehun iya fun ẹniti o ba se bẹẹ pẹlu yiyọwọ kuro ni ọdọ wọn, ati pẹlu sise isiro ni Ọjọ Igbende.