إِنِّي وَجَدتُّ ٱمۡرَأَةٗ تَمۡلِكُهُمۡ وَأُوتِيَتۡ مِن كُلِّ شَيۡءٖ وَلَهَا عَرۡشٌ عَظِيمٞ 23
Dajudaju mo ri obirin kan ti o nse ijọba wọn, wọn si fun obirin naa ni gbogbo nkan ninu awọn okunfa agbara ati ọla, o si ni ibusun ti o tobi ti o ndari alamọri ọrọ awọn ijọ rẹ nibẹ.
وَجَدتُّهَا وَقَوۡمَهَا يَسۡجُدُونَ لِلشَّمۡسِ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَصَدَّهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ فَهُمۡ لَا يَهۡتَدُونَ 24
Mo ri obirin naa, bẹẹ ni mo si tun awọn ijọ rẹ ti wọn nfi ori balẹ fun oorun yatọ si Allah ti mimọ nbẹ fun ti o si ga ju lọ, bẹẹni esu si se isẹ ẹbọ ti wọn wa lori rẹ lọsọ fun wọn ati awọn ẹsẹ, o wa yi wọn kuro ni oju ọna ododo, ti wọn ko le mọna lọsi ibẹ.
أَلَّاۤ يَسۡجُدُواْۤ لِلَّهِ ٱلَّذِي يُخۡرِجُ ٱلۡخَبۡءَ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَيَعۡلَمُ مَا تُخۡفُونَ وَمَا تُعۡلِنُونَ 25
Esu sọ isẹ ẹbọ wọn ati awọn ẹsẹ wọn di daradara; ki wọn maa ba fi ori balẹ fun Allah nikan soso eyiti o nmu ojo ti O bolasiri sinu sanmọ jade ati awọn irugbin ni inu ilẹ, O si mọ ohun ti ẹ nfi pa mọ ninu isẹ ati eyiti ẹ nse afihan rẹ, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ.
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡعَظِيمِ۩ 26
Allah ti ko si ẹni ijọsin fun ni tootọ yatọ si I, Oun ni Ọba Alaga ti o tobi ju.
۞قَالَ سَنَنظُرُ أَصَدَقۡتَ أَمۡ كُنتَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 27
Sulayman ti ọla nbẹ fun sọ fun Hudihuda: a o woye boya ododo ni o sọ pẹlu ohun ti o pe mọ ara rẹ tabi o wa ninu awọn opurọ.
ٱذۡهَب بِّكِتَٰبِي هَٰذَا فَأَلۡقِهۡ إِلَيۡهِمۡ ثُمَّ تَوَلَّ عَنۡهُمۡ فَٱنظُرۡ مَاذَا يَرۡجِعُونَ 28
Sulayman si kọ iwe kan, o si fun Hudihuda, o wa sọ fun pe: mu iwe mi yii, ki o ju si awọn ara sabahi, ki o si fun wọn; ki o wa jinna si wọn ni ẹgbẹ kan, ti o ti maa gbọ ohun ti wọn nsọ nipa rẹ.
قَالَتۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَؤُاْ إِنِّيٓ أُلۡقِيَ إِلَيَّ كِتَٰبٞ كَرِيمٌ 29
Ọba si gba iwe naa, o wa sọpe: ẹyin ẹni iyi, dajudaju wọn ju iwe alapọnle ti o gbọngbọn kan si mi.
إِنَّهُۥ مِن سُلَيۡمَٰنَ وَإِنَّهُۥ بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ 30
Ounti o wa ninu iwe naa ti wọn fi ransẹ lati ọdọ Sulayman, ti o bẹrẹ pẹlu “pẹlu orukọ Allah, Ajọkẹ Aye Asakẹ Ọrun”:
أَلَّا تَعۡلُواْ عَلَيَّ وَأۡتُونِي مُسۡلِمِينَ 31
Se ẹ ko ni se igberaga, ki ẹ wa ni ẹni itẹriba, olujupa jusẹ silẹ fun ohun ti mo npe yin si ninu ijọkan soso Allah ati gbigbe ohun ti ẹ wa lori rẹ ninu ẹbọ ju silẹ nibi mima sin oorun pẹlu rẹ.
قَالَتۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَؤُاْ أَفۡتُونِي فِيٓ أَمۡرِي مَا كُنتُ قَاطِعَةً أَمۡرًا حَتَّىٰ تَشۡهَدُونِ 32
Ọba sọpe: ẹyion ẹni iyi ati asiwaju; ẹ se alaye ojupọnna ti o dọgba nibi alamọri mi yii fun mi, wọn kii se idajọ kan titi ti ẹ o fi wa pẹlu mi, ti ẹ o fi se afihan iero yin nipa rẹ.
قَالُواْ نَحۡنُ أُوْلُواْ قُوَّةٖ وَأُوْلُواْ بَأۡسٖ شَدِيدٖ وَٱلۡأَمۡرُ إِلَيۡكِ فَٱنظُرِي مَاذَا تَأۡمُرِينَ 33
Awọn ẹni iyi ninu ijọ rẹ sọ fun pe: awa jẹ alagbara ti o tobi ati oni nkan ija ti o lagbara loju ogun sugbọn ero ti o ba ro ni, ki o ronu si ohun ti iwọ yoo pa wa ni asẹ rẹ, awa jẹ ẹniti o lagbara lati le mu u sẹ.
قَالَتۡ إِنَّ ٱلۡمُلُوكَ إِذَا دَخَلُواْ قَرۡيَةً أَفۡسَدُوهَا وَجَعَلُوٓاْ أَعِزَّةَ أَهۡلِهَآ أَذِلَّةٗۚ وَكَذَٰلِكَ يَفۡعَلُونَ 34
Ọba sọpe: dajudaju awọn ọba ti wọn ba wọ abule kan ninu ilu, wọn yoo ba a jẹ pẹlu ohun ti wọn yoo se nibẹ gẹgẹ bi pipani, jijagba ati imuni lagidi, wọn si ma nsọ adari ibẹ ati ẹni iyi ibẹ di ẹni yẹpẹrẹ lẹyin igba ti wọn ti jẹ ẹni iyi ati alaabo gẹgẹ bẹẹ ni awọn ọba se ma nse ni gbogbo igba ti wọn ba jẹ gaba lori abule kan; lati gbin ibẹru ati ipaya si inu awọn ẹmin.
وَإِنِّي مُرۡسِلَةٌ إِلَيۡهِم بِهَدِيَّةٖ فَنَاظِرَةُۢ بِمَ يَرۡجِعُ ٱلۡمُرۡسَلُونَ 35
Atipe dajudaju wọn fi ẹbun ran mi si oniwe naa ati awọn rẹ, ki o si woye si ohun ti awọn ojisẹ naa yoo mu wa lẹyin igba ti o ba fi ọrẹ naa ransẹ si wọn.
Kikorira Hudihuda si awọn ijọ sabahi lori ẹbọ ti wọn nse ati keferi jẹ itọka si igbagbọ adayeba ti nbẹ ni ọdọ awọn ẹda.
Mimọ amọdaju si ẹniti a nfura si ati riri ẹri ti o fi ẹsẹ rinlẹ lori awijare rẹ.
Sise lofin titu asiri iro awọn ọta.
Ninu ẹkọ ifiwe ransẹ ni bibẹrẹ rẹ pẹlu ‘Bis'millaahi’.
Sise afihan iyi olugbagbọ ododo niwaju onibajẹ jẹ ohun ti a fẹ.