وَرَٰوَدَتۡهُ ٱلَّتِي هُوَ فِي بَيۡتِهَا عَن نَّفۡسِهِۦ وَغَلَّقَتِ ٱلۡأَبۡوَٰبَ وَقَالَتۡ هَيۡتَ لَكَۚ قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ رَبِّيٓ أَحۡسَنَ مَثۡوَايَۖ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّٰلِمُونَ 23
Obinrin ọba nwa pẹlu pẹlẹpẹlẹ ati lilo ete sise ibajẹ lọdọ yusuf ẹniti ọla nbẹ fun, o si mọọmọ ti gbogbo ilẹkun ni oun nikan, o si sọ fun wipe: sunmọ ibiyi ki o wa ba mi, yusuf wa sọ wipe: mo fi Allah wa isọ kuro nibi ohun ti o npe mi si, dajudaju alowo mi se daadaa si mi nibi ibugbe mi pẹlu rẹ, emi ko ni janba rẹ, ti mo ba jamba rẹ, mo ti di alabosi, bẹẹ si ni awọn alabosi ko nii jere.
وَلَقَدۡ هَمَّتۡ بِهِۦۖ وَهَمَّ بِهَا لَوۡلَآ أَن رَّءَا بُرۡهَٰنَ رَبِّهِۦۚ كَذَٰلِكَ لِنَصۡرِفَ عَنۡهُ ٱلسُّوٓءَ وَٱلۡفَحۡشَآءَۚ إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُخۡلَصِينَ 24
Paapaa ẹmin rẹ ti se oju kokoro sibi sise ibajẹ eleyi si ti ru wuyẹ ninu ọkan tirẹ bakanna, ti kii ba se wipe o ri ninu awọn amin Ọlọhun Ọba Allah ohun ti o kaa ro, ti o si mu jinna si i, paapaa a mu ri eleyi ki a le mu aburu kuro fun un ati ki a le mu jinna si agbere ati jamba, dajudaju yusuf wa ninu ẹru wa ti a sa lẹsa fun isẹ ojisẹ ati jijẹ anọbi.
وَٱسۡتَبَقَا ٱلۡبَابَ وَقَدَّتۡ قَمِيصَهُۥ مِن دُبُرٖ وَأَلۡفَيَا سَيِّدَهَا لَدَا ٱلۡبَابِۚ قَالَتۡ مَا جَزَآءُ مَنۡ أَرَادَ بِأَهۡلِكَ سُوٓءًا إِلَّآ أَن يُسۡجَنَ أَوۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ 25
Awọn mejeeji gba waju de ẹnu ọla: yusuf fẹ la ẹmin ara rẹ, oun si nkọ ọ fun lati jade, o wa gba asọ rẹ mu lati kọ fun lati mase jade, bayi ni o fa asọ rẹ ya lati ẹyin, awọn mejeeji wa ri ọkọ rẹ ni ẹnu ọna, obinrin ọba si sọ fun ọba niti oludete, ko si iya kankan fun ẹniti o ba gberi iyawo rẹ -irẹ ọba- sise ibajẹ ju ẹwọn lọ tabi ki wọn jẹ niya ti o nira.
قَالَ هِيَ رَٰوَدَتۡنِي عَن نَّفۡسِيۚ وَشَهِدَ شَاهِدٞ مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن قُبُلٖ فَصَدَقَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ 26
Yuusuf ti ọla nbẹ fun sọ wipe: oun ni o beere fun ibajẹ ni ọdọ mi, emi ko gbero rẹ ni ọdọ rẹ, Ọlọhun Ọba wa jẹ ki ọmọ kekere ninu awọn ara ile rẹ sọrọ ni ori itẹ, o si jẹri pẹlu gbolohun rẹ wipe: ti asọ yusuf ba ya lati iwaju rẹ, eleyi ni isunmọ lori jijẹ ododo obinrin naa; toripe oun ni o nkọ ọ fun ki o ma se ibajẹ pẹlu rẹ, ti oun si jẹ opurọ.
وَإِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ فَكَذَبَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 27
Sugbọn ti asọ rẹ ba ya lati ẹyin eleyi ni o sun mọ lori ododo arakunrin naa; nitori wipe obinrin ni o ngbero gba a sugbọn ti arakunrin na nsaa fun un, oun waa ni opurọ binrin.
فَلَمَّا رَءَا قَمِيصَهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ قَالَ إِنَّهُۥ مِن كَيۡدِكُنَّۖ إِنَّ كَيۡدَكُنَّ عَظِيمٞ 28
Nigbati ọba ri wipe asọ yusuf ya lati ẹyin, o wa da loju wipe yusuf ni olootọ ni o wa sọ wipe: dajudaju piparọ mọni eyiti o ju si i jẹ akojọ ninu ete yin - ẹyin obinrin - dajudaju ete yin jẹ ete ti o lagbara.
يُوسُفُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَاۚ وَٱسۡتَغۡفِرِي لِذَنۢبِكِۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ ٱلۡخَاطِِٔينَ 29
O wa sọ fun yusuf: irẹ yusuf, gboju kuro nibi oju ewe yii, mase sọ fun ẹnikẹni, irẹ arabinrin ki o si wa aforijin nibi ẹsẹ rẹ, dajudaju o ti jẹ ọkan ninu awọn ẹlẹsẹ nitori gbigba ero gba yusuf.
۞وَقَالَ نِسۡوَةٞ فِي ٱلۡمَدِينَةِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ تُرَٰوِدُ فَتَىٰهَا عَن نَّفۡسِهِۦۖ قَدۡ شَغَفَهَا حُبًّاۖ إِنَّا لَنَرَىٰهَا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ 30
Iro rẹ si fan ka ni inu ilu, awọn eniyan kan ninu awọn obinrin sọ ni ojupọnna ikorira: obinrin ọba wa npe ẹru rẹ si ọdọ ara rẹ, paapaa ifẹ rẹ ma ti bo ọkan rẹ gan (itumọ rẹ ni wipe: eepo rẹ) dajudaju a ri latara gbigba ero gba a ati ifẹ ti o ni si i - ti o si jẹ ẹru rẹ - ni ọna anu ti o han.
Aburu ijamba oluse daadaa lori ara ile tabi dukia rẹ, ọrọ ti Yuusuf sọ ninu awọn okunfa ti o fi kọ ibajẹ naa.
Sise alaye idaabobo awọn anọbi Ọlọhun ati isọ Ọlọhun fun wọn lati mase se aburu ati ibajẹ.
Jijẹ ọranyan titi ibajẹ danu ati sisa pẹlu jijawọ kuro nibẹ.
Sise lofin mimaa lo awọn nkan ti o ba sun mọ ninu awọn idajọ.