لَّا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا كَسَبَتۡ قُلُوبُكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٞ 225
Ọlọhun Ọba Allah ko nii se isiro yin pẹlu okunfa awọn ibura eyiti o nlọ lori ahọn yin laigbero rẹ; gẹgẹ bi gbolohun ọkan ninu yin: kori bẹẹ, mo fi Ọlọhun Ọba Allah bura ati bẹẹ ni o ri, mo fi Ọlọhun Ọba Allah bura, ko si itanran ti o jẹ dandan fun yin, tabi iya nibi nkan naa, sugbọn Yoo maa se isiro yin ninu awọn eyiti ẹ ba gbero rẹ ninu awọn ibura naa, Ọlọhun Ọba Allah ni Alaforijin fun awọn gbogbo awọn ẹsẹ awọn ẹru Rẹ, Onisuuru si ni, ti ko ni kanju lati jẹ yin niya.
لِّلَّذِينَ يُؤۡلُونَ مِن نِّسَآئِهِمۡ تَرَبُّصُ أَرۡبَعَةِ أَشۡهُرٖۖ فَإِن فَآءُو فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 226
Nbẹ fun awọn ti o nbura lori fifi biba awọn obirin wọn lopọ silẹ, lati maa reti fun igbati ti ko nii kọja osu mẹẹrin, lati igbati wọn ba ti bura, ohun naa ni wọn npe ni pipa obirin ti (Al-ilaai) , ti wọn ba wa pada sibi mima ba wọn se asepọ lẹyin ibura wọn lori gbigbiw ọn ju silẹ fun osu mẹẹrin tabi ohun ti ko to bẹẹ; dajudaju Ọlọhun Ọba Allah. Alaforijin ni, ti Yoo fi ori ohun ti o sẹlẹ lọdọ wọn jin wọn, Onikẹ wọn si ni pẹlu ni bi O se se ofin mima tanran ni ọna abayọ kuro nibi ibura yii.
وَإِنۡ عَزَمُواْ ٱلطَّلَٰقَ فَإِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ 227
Ti wọn ba wa gbero kikọ silẹ pẹlu lilọ wọn lori mima ba awọn obirin wọn se asepọ ju silẹ, ati aipada sibẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti O ngbọ awọn gbolohun wọn eyiti o jẹ wipe ninu rẹ ni kikọ ara ẹni silẹ, Onimọ nipa awọn isesi wọn ati awọn iro wọn si ni, Yoo si pada san wọn lẹsan le lori.
وَٱلۡمُطَلَّقَٰتُ يَتَرَبَّصۡنَ بِأَنفُسِهِنَّ ثَلَٰثَةَ قُرُوٓءٖۚ وَلَا يَحِلُّ لَهُنَّ أَن يَكۡتُمۡنَ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِيٓ أَرۡحَامِهِنَّ إِن كُنَّ يُؤۡمِنَّ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ وَبُعُولَتُهُنَّ أَحَقُّ بِرَدِّهِنَّ فِي ذَٰلِكَ إِنۡ أَرَادُوٓاْ إِصۡلَٰحٗاۚ وَلَهُنَّ مِثۡلُ ٱلَّذِي عَلَيۡهِنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ وَلِلرِّجَالِ عَلَيۡهِنَّ دَرَجَةٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ 228
Awọn obirin ti wọn ba kọ silẹ, wọn yoo reti fun ara wọn ẹjẹ nkan osu mẹta, ti wọn ko nii lọkọ laarin rẹ, ko si lẹtọ fun wọn ki wọn fi ohun ti o wa ninu apo ibimọ wọn ninu oyun pamọ, ti wọn ba jẹ ẹniti o nsọ ododo lobirin nibi ini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati Ọjọ Ikẹyin, ati wipe awọn ọkọ wọn ti wọn kọ wọn silẹ ni wọn ni ẹtọ lati gba wọn pada, ni asiko ti wọn nse igbele fun kikọ, ti o ba jẹ wipe wọn ba gba ero pẹlu didawọn pada lati fi ara ro wọn, ati mimu ohun ti o se okunfa kikọ kuro, o si nbẹ fun awọn obirin ninu awọn ẹtọ ati awọn ohun ti o jẹ dandan, iru ohun ti o nbẹ fun awọn ọkọ wọn le wọn lori pẹlu nkan ti awọn eeyan ti mọ laarin ara wọn, o si nbẹ fun awọn ọkunrin, ipo ti o ga le wọn lori nibi jijẹ opomulero ati nini asẹ kikọ, Ọlọhun Ọba Allah ni Ọba Alagbara, ti nkankan ko le bori Rẹ, Ọjọgbọn si ni nibi awọn ofin Rẹ ati didari Rẹ.
ٱلطَّلَٰقُ مَرَّتَانِۖ فَإِمۡسَاكُۢ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ تَسۡرِيحُۢ بِإِحۡسَٰنٖۗ وَلَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَأۡخُذُواْ مِمَّآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ شَيًۡٔا إِلَّآ أَن يَخَافَآ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَا فِيمَا ٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَعۡتَدُوهَاۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 229
Kikọ ara ẹni silẹ eyiti ọkọ ni anfaani lati gba iyawo rẹ pada jẹ meji, pẹlu wipe ki o kọọ, lẹyin igba naa ni yoo tun wa gbaa pada, lẹyin igba naa yoo tun wa kọọ, yoo si tun waa gba pada, lẹyin kikọ ara ẹni meji naa, ninu ki o gbaa sọwọ si abẹ sisọ rẹ pẹlu ibalopọ ti o dara, tabi ki o si kọọ ni ẹẹkẹta pẹlu sise daadaa sii ati fifun ni awọn ẹtọ rẹ, ko lẹtọ fun yin - ẹyin ọkọ - ki ẹ gba nkankan ninu ohun ti ẹ ti fun awọn iyawo yin ninu owo ori, ayaafi ti o ba jẹ wipe obirin jẹ ẹniti o korira ọkọ rẹ, nitori iwa rẹ tabi isẹda rẹ, ti awọn tọkọ-taya naa ba lero pẹlu ikorira yii, aini le pe oun ti o jẹ dandan fun awọn mejeeji ninu awọn ẹtọ, ki wọn yaa dari alamọri awọn mejeeji si ẹniti o ba ni asepọ mọlẹbi pẹlu wọn tabi eyi ti o yatọ sii, ti awọn alasẹ ba nbẹru aini le pe ẹtọ jijẹ tọkọ-taya laarin awọn mejeeji, ko si ẹsẹ fun awọn mejeeji nibi ki obirin beere fun kikọ ara rẹ pẹlu owo ti yoo fun ọkọ rẹ dipo kikọ rẹ. Awọn idajọ ofin Ṣhẹria naa ni eyiti o nse opinya laarin ẹtọ ati eewọ, ẹ mase kọja rẹ, ẹniti o ba kọja ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah laarin ẹtọ ati eewọ, awọn ni awọn ti wọn bo ẹmi ara wọn si pẹlu sisẹri rẹ si ibi aaye iparun ati sisẹri rẹ si ibinu Ọlọhun Ọba Allah ati iya Rẹ.
فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا تَحِلُّ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدُ حَتَّىٰ تَنكِحَ زَوۡجًا غَيۡرَهُۥۗ فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَآ أَن يَتَرَاجَعَآ إِن ظَنَّآ أَن يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۗ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ يُبَيِّنُهَا لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ 230
Ti ọkọ rẹ ba wa kọọ, ni kikọ ẹlẹẹkẹta, ko ni ẹtọ fun un lati fẹẹ pada ni tuntun, titi ti yoo fi fẹ ọkunrin miran ti o yatọ sii ni fifẹ ti o ni alaafia, niti irankan ti kii se ero sisọ di ẹtọ, ti yoo si ba se asepọ nibi igbeyawo yii, ti ọkọ ẹlẹẹkeji ba wa kọọ tabi ti o ba ku fun un, ko si ẹsẹ fun obirin ati ọkọ rẹ alakọkọ, ki wọn gba ara wọn pada pẹlu itakoko yigi ati owo ori, ti mejeeji jẹ tuntun, ti o ba jẹ wipe o bori ero awọn mejeeji, pe dajudaju awọn mejeeji yoo maa se ohun ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn ofin Ṣẹria, awọn ni awọn ofin Ṣẹria, ti Ọlọhun Ọba Allah nse alaye rẹ fun awọn eniyan ti wọn mọ awọn idajọ Rẹ ati awọn ẹnu aala Rẹ, toripe dajudaju awọn ni awọn ti yoo se anfaani pẹlu rẹ.
Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga se alaye awọn ofin igbeyawo ati kikọ ara ẹni silẹ ni alaye kan ti o kun, titi ti awọn eniyan yoo fi mọ awọn aala ẹtọ ati eewọ, ti wọn ko fi nii kọja rẹ.
Ọlọhun Ọba Allah gbe ọrọ nipa iyawo sise tobi, O si se mima se amusere pẹlu awọn gbolohun nibẹ ni eewọ, o si se ni dandan, o si fa igi le mima se amusere pẹlu ọpọlọpọ kikọ ati gbigba pada, o si fi aala sii pẹlu kikọ ati gbigba ni ẹẹmeji, lẹyin igbanaa ni yoo wa di eewọ fun un, ayaafi ki o fẹ ọkọ miran ti o yatọ sii, lẹyin igba naa ni yoo wa kọọ abi ki o ku sibe.
Ibalopọ tọkọ-taya gbọdọ jẹ pẹlu daadaa, ti nkan naa ba wa nira lati se, ko si aburu nibi kikọ ara ẹni, ko si si aburu fun ẹni kankan ninu ọkọ ati iyawo lati beere fun un.