فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۗ وَيَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡيَتَٰمَىٰۖ قُلۡ إِصۡلَاحٞ لَّهُمۡ خَيۡرٞۖ وَإِن تُخَالِطُوهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ ٱلۡمُفۡسِدَ مِنَ ٱلۡمُصۡلِحِۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَأَعۡنَتَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 220
O se nkan naa ofin ki ẹ lee ba maa ronu si ohun ti yoo se yin ni anfaani ni aye ati ni Ọjọ Ikẹyin. Awọn ijọ rẹ yoo bi ọ leere - irẹ Anọbi - nipa mima dide si mimojuto awọn ọmọ orukan: bawo ni wọn yoo se maa se nibi bibawọn lo papọ? Ati wipe se wọn yoo maa da awọn dukia wọn papọ pẹlu ti wọn ni nibi ninawo ati fifun ni ounjẹ ati ibugbe? Sọ ni ẹniti ndawọn lohun wipe: gbigbọla yin fun wọn pẹlu sise atunse awọn dukia wọn laini ni aarọ abi adapọ ninu owo wọn ni o loore fun yin ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹsan rẹ si tobi julọ, ohun ni o si loore fun wọn nibi awọn dukia wọn; nibi ohun ti nbẹ nibi sisọ awọn dukia wọn fun wọn, ti ẹ ba wa kẹgbẹ wọn nibi dida owo wọn pọ mọ owo yin nibi jijẹ-mimu ati ibugbe, ati awọn ohun ti o jẹ nkan naa, ko si inira nibẹ, toripe awọn ni ọmọ iya yin ninu ẹsin, ati wipe awọn iya apakan wọn ma nran apakan wọn lọwọ, apakan wọn si ma nduro lati mojuto alamọri apakan, Ọlọhun Ọba Allah mọ ẹniti o ngbero ibajẹ ninu awọn alamojuto pẹlu kikẹgbẹ awọn ọmọ orukan ninu ẹniti o gbero daradara, ti O ba fẹ inira fun yin ni, nibi alamọri ọmọ orukan, ko ba ko inira ba yin lori rẹ, sugbọn Oun mimọ fun Un, ti ọla Rẹ si ga, se ibalopọ pẹlu wọn ni irọrun fun yin; toripe ofin rẹ, wọn mọ pa lori irọrun, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Alagbara ni, ti nkankan ko si le bo ori Rẹ, Ọjọgbọn si nibi sise ẹda Rẹ, ati didari Rẹ ati sise ofin Rẹ.
وَلَا تَنكِحُواْ ٱلۡمُشۡرِكَٰتِ حَتَّىٰ يُؤۡمِنَّۚ وَلَأَمَةٞ مُّؤۡمِنَةٌ خَيۡرٞ مِّن مُّشۡرِكَةٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَتۡكُمۡۗ وَلَا تُنكِحُواْ ٱلۡمُشۡرِكِينَ حَتَّىٰ يُؤۡمِنُواْۚ وَلَعَبۡدٞ مُّؤۡمِنٌ خَيۡرٞ مِّن مُّشۡرِكٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَكُمۡۗ أُوْلَٰٓئِكَ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلنَّارِۖ وَٱللَّهُ يَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱلۡجَنَّةِ وَٱلۡمَغۡفِرَةِ بِإِذۡنِهِۦۖ وَيُبَيِّنُ ءَايَٰتِهِۦ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ 221
Ẹ mase maa fẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ti wọn se ẹbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah l’obinrin titi wọn yoo fi ni igbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah ni Oun nikan, ti wọn yoo si wọ inu ẹsun Islam, ati wipe dajudaju obinrin ti o jẹ ẹru, ti o si ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati Ojisẹ Rẹ ní oore ju obinrin ti o jẹ ọmọluwabi ti o nse awọn oosa lọ koda bi ẹwaa rẹ ba jọyin loju ati owo rẹ, ẹ mase fi awọn obinrin Musulumi se aya fun awọn ọkunrin ọsẹbọ, ati wipe ẹru ti nbẹ loko ẹru, ti o si ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ni oore ju ọmọluwabi ti o jẹ ọsẹbọ lọ koda bi o ba wu yin, awọn wọnyi ti wọn royin pẹlu sise ẹbọ - ni awọn ọkunrin ati awọn obinrin - ni wọn npepe pẹlu awọn gbolohun wọn ati awọn isẹ wọn lọ si ibi ohun ti jẹ atọkun lọsi bi wiwọ ina, Ọlọhun Ọba Allah si npe yin lọsi ibi awọn isẹ oloore eyiti yoo se atọkun lọ si bi wiwọ Ọgba Idẹra ati riri aforijin nibi awọn ẹsẹ pẹlu iyọnda Rẹ ati ọla Rẹ, O si nse alaye awọn aayah Rẹ fun awọn eniyan ki wọn le ba jẹ ẹniti yoo woye pẹlu ohun ti O ntọka si, ti wọn yoo si sisẹ pẹlu Rẹ.
وَيَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡمَحِيضِۖ قُلۡ هُوَ أَذٗى فَٱعۡتَزِلُواْ ٱلنِّسَآءَ فِي ٱلۡمَحِيضِ وَلَا تَقۡرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطۡهُرۡنَۖ فَإِذَا تَطَهَّرۡنَ فَأۡتُوهُنَّ مِنۡ حَيۡثُ أَمَرَكُمُ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلتَّوَّٰبِينَ وَيُحِبُّ ٱلۡمُتَطَهِّرِينَ 222
Awọn ijọ rẹ yoo wa bi ọ leere irẹ Anọbi - nipa ẹjẹ nkan osu (ohun naa ni ẹjẹ adamọ kan, ti o ma njade lati inu ile ibimọ obirin ni awọn asiko kan ti o jẹ ẹsa) ? Sọ ni ẹniti nda wọn lohun wipe: ẹjẹ nkan osu, suta ni o jẹ fun ọkunrin ati obirin, ki ẹ wa jinna si biba obirin se asepọ ni asiko rẹ, ẹ si ma sun mọ wọn lati ba wọn se asepọ, titi ti ẹjẹ yoo fi da ni ọdọ wọn, ti wọn yoo si mọra kuro nibẹ pẹlu wiwẹ, ti o ba waa da, ti wọn si ti mọ ara kuro nibẹ, ki ẹ waa ma ba wọn se asepọ lori ojupọnna ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ fun yin, nigbati wọn ba jẹ ẹniti o mọ lati iwaju wọn, Ọlọhun Ọba Allah nifẹ awọn ti wọn ba pọ ni ironu piwada kuro nibi awọn ẹsẹ, ati awọn ti wọn ba de ogongo ninu imọra kuro ninu awọn ẹgbin.
نِسَآؤُكُمۡ حَرۡثٞ لَّكُمۡ فَأۡتُواْ حَرۡثَكُمۡ أَنَّىٰ شِئۡتُمۡۖ وَقَدِّمُواْ لِأَنفُسِكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُم مُّلَٰقُوهُۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 223
Awọn iyawo yin, aaye nkan ọgbin ni fun yin, ti wọn yoo ma bi awọn ọmọ fun yin; gẹgẹ bi ilẹ eyiti o ma nmu awọn eso jade, ki ẹ waa ma wa si ibi aaye nkan ọgbin naa - ohun naa ni iwaju - ni ọna ti o ba wu yin, ati bi ẹ ba se fẹ nigbati o ba jẹ wipe iwaju ni, ki ẹ si maa ti nkan siwaju fun ara yin pẹlu sise awọn isẹ oloore, ninu rẹ ni ki ọkunrin maa ba iyawo rẹ se asepọ pẹlu aniyan lati sun mọ Ọlọhun Ọba Allah, ati lati maa rankan awọn ọmọ ti o dara, ki ẹ si paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mima mu awọn asẹ rẹ wa si imusẹ, ati jijinna si awọn ohun ti o kọ, ninu rẹ ni ohun ti O se ni ofin fun yin ninu alamọri awọn obirin, ki ẹ si lọ ma pe dajudaju ẹyin, ẹniti yoo pade Rẹ ni yin ni Ọjọ Igbende ni ẹniti yoo duro niwaju Rẹ, atipe Yoo si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin, wa maa fun ni iro idunnu - irẹ Anọbi - awọn olugbagbọ ododo, pẹlu ohun ti yoo maa dumọ wọn ninu nigbati wọn ba pade Ọlọhun Ọba wọn ninu idẹra ti yoo maa lọ gbere ati wiwo oju Rẹ ti o jẹ alapọnle.
وَلَا تَجۡعَلُواْ ٱللَّهَ عُرۡضَةٗ لِّأَيۡمَٰنِكُمۡ أَن تَبَرُّواْ وَتَتَّقُواْ وَتُصۡلِحُواْ بَيۡنَ ٱلنَّاسِۚ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٞ 224
Ẹ ma se se mima bura pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ni awijare ti yoo kọ mima sisẹ oore ati mima paya Ọlọhun Ọba, ati mima se atunse laarin awọn eniyan, bikose wipe, ti ẹ ba bura lori fifi daradara silẹ; ki ẹ yaa se daadaa naa, ki ẹ si mu itanran wa nipa awọn ibura yin, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah, Ẹniti O gbọ awọn gbolohun yin ni, O si ni imọ pẹlu awọn isẹ yin, Yoo si pada san yin lẹsan le lori.
Sise fifẹ ara ẹni ni eewọ laarin Musulumi ati awọn Musulumi ati awọn ọsẹbọ, nkan naa jẹ nititori jijinna laarin ẹbọ ati igbagbọ.
Awọn aayah naa ntọka si sise nini alasẹ ni majẹmu nigbati a fẹ ta koko yigi; toripe Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga ba awọn alasẹ sọrọ nigbati o kọ fun wọn nipa mima fi obirin fun awọn ọsẹbọ.
Ṣhẹria seni loju kokoro lori imọra ti a le fi oju ri kuro nibi awọn ẹgbin ati awọn idọti, ati imọra ti a ko le fi oju ri kuro nibi ẹbọ ati awọn ẹsẹ.
Sise awọn Muumini ni oju lọyin nibi ki wiwoye rẹ si awọn isẹẹrẹ -to fi debi awọn nkan ti o ro papọ mọ igbadun - ki o jẹ iwoyesi ile ikẹyin ni yoo fi maa ti siwaju fun ẹmin rẹ eyiti yoo se anfaani fun nibẹ.