كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِتَالُ وَهُوَ كُرۡهٞ لَّكُمۡۖ وَعَسَىٰٓ أَن تَكۡرَهُواْ شَيۡٔٗا وَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۖ وَعَسَىٰٓ أَن تُحِبُّواْ شَيۡٔٗا وَهُوَ شَرّٞ لَّكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ 216
Wọn se ni ọranyan fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - mima jagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, o si jẹ oun ti ẹmin kọ pẹlu adamọ rẹ; nitori oun ti o nbẹ nibẹ ninu nina owo ati ẹmin, o si seese ki ẹyin maa korira nkankan, ti o si jẹ wipe nibi oun ti o sẹlẹ, oore ati anfaani ni fun yin; gẹgẹ bi jijagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah pẹlu ẹsan rẹ ti o tobi, aranse nbe nibe lori awọn ọta ati gbigbe gbolohun Ọlọhun Ọba Allah ga, o si seese ki ẹyin nifẹ nkankan, ti o si jẹ wipe aburu ati aida ni yoo jẹ leyin lori; gẹgẹ bi fifaseyin nibi jijagun, toripe dajudaju o nbẹ nibẹ iyẹpere ati ki ọta bori eniyan, Ọlọhun Ọba Allah si Mọọ ni imọ ti o pe, eyiti o loore ninu alamọri ati aburu rẹ, ẹyin ko si mọ nkan naa, ẹ dahun si asẹ Ọlọhun Ọba Allah, toripe oore nbẹ nibẹ fun yin.
يَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ قِتَالٖ فِيهِۖ قُلۡ قِتَالٞ فِيهِ كَبِيرٞۚ وَصَدٌّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَكُفۡرُۢ بِهِۦ وَٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَإِخۡرَاجُ أَهۡلِهِۦ مِنۡهُ أَكۡبَرُ عِندَ ٱللَّهِۚ وَٱلۡفِتۡنَةُ أَكۡبَرُ مِنَ ٱلۡقَتۡلِۗ وَلَا يَزَالُونَ يُقَٰتِلُونَكُمۡ حَتَّىٰ يَرُدُّوكُمۡ عَن دِينِكُمۡ إِنِ ٱسۡتَطَٰعُواْۚ وَمَن يَرۡتَدِدۡ مِنكُمۡ عَن دِينِهِۦ فَيَمُتۡ وَهُوَ كَافِرٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 217
Awọn eniyan yoo bi ọ leere - iwọ Anọbi - nipa idajọ ogun jija ninu awọn osu ọwọ naa, Dhil Ka’da, Dhil Hijja, Muharram, ati Rajab, sọ ni ẹniti nda wọn lohun wipe: jijagun nnu awọn osu yii, jẹ ohun ti o tobi ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ti ọkan si kọọ, gẹgẹ bi o se jẹ wipe dajudaju ohun ti awọn ọsẹbọ nse ninu kikọdi oju ọna Ọlọhun Ọba Allah jẹ ohun ti o buru bakanna, ati kikọ fun awọn olugbagbọ ododo nibi Mọsalaasi Abeewọ naa, ati mimu eeyan Mọsalaasi Abeewọ naa jade kuro nibẹ, o tobi ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ju jijagun lọ ninu osu ọwọ naa ati sise ẹbọ eyiti wọn wa nibẹ tobi ju pipaayan lọ. Awọn ọsẹbọ ko nii yẹ kuro lori abosi wọn ni ẹniti yoo maa bayin ja - ẹyin olugbagbọ ododo - titi wọn yoo fi sẹri yin pada kuro nibi ẹsin yin, ẹsin ti o jẹ ododo lọsi ibi ẹsin wọn ti o jẹ irọ, ti wọn ba kapa ọna lati se bẹẹ, ẹniti o ba waa pada ninu yin kuro nibi ẹsin rẹ, ti o wa ku ni ẹniti o wa lori aini igbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah, paapaa isẹ ti o dara ti bajẹ, ibiti yoo pada si ni Ọjọ Ikẹyin ni wiwọ ina ati wiwa nibẹ lailai.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ يَرۡجُونَ رَحۡمَتَ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 218
Dajudaju awọn ti wọn gba Ọlọhun Ọba Allah gbọ ati awọn ojisẹ Rẹ, ati awọn ti wọn fi awọn ilu wọn silẹ ni ẹniti o nse irin-ajo lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ti wọn si njagun ki o le ba jẹ wipe gbolohun Ọlọhun Ọba Allah ni eyiti yoo ga, awọn naa ni ẹniti yoo maa rankan ikẹ Ọlọhun Ọba Allah ati aforijin Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah ni alaforijin ẹsẹ awọn ẹru Rẹ, Onikẹẹ wọn si niI.
۞يَسَۡٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡخَمۡرِ وَٱلۡمَيۡسِرِۖ قُلۡ فِيهِمَآ إِثۡمٞ كَبِيرٞ وَمَنَٰفِعُ لِلنَّاسِ وَإِثۡمُهُمَآ أَكۡبَرُ مِن نَّفۡعِهِمَاۗ وَيَسَۡٔلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَۖ قُلِ ٱلۡعَفۡوَۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَتَفَكَّرُونَ 219
Awọn ijọ yoo wa bi ọ leere - irẹ Anọbi - nipa ohun ti (ohun naa gbogbo ohun ti o ba ti bo laakaye mọlẹ, ti o si mulọ) ; wọn yoo bi ọ leere nipa idajọ mimuu, titaa ati riraa? Wọn si bi ọ leere nipa idajọ tẹtẹ tita (ohun naa ni ohun ti wọn ma ngba ninu owo, ni oju ọna ifiga-gbaga, eyiti o wa nibẹ fifi nkan di nkan lati ọdọ igun mejeeji ti o kẹgbẹ ninu ifiga-gbaga) ? Maa sọ bi ẹniti ndawọn lohun wipe, o nbẹ nibi mejeeji inira ati ibajẹ ẹsin ati ti aye eyiti o pọ; nibi lilọ ti laakaye yoo lọ ati owo ati bibọ sinu ọta sise ati ikorira ara ẹni, o si nbẹ nibi mejeeji awọn anfaani ti o kere gẹgẹ bi pipa owo lati ara rẹ, ati wipe inira awọn mejeeji ati ẹsẹ ti yoo sẹlẹ tobi ju anfaani awọn mejeeji lọ, ohun ti o ba jẹ wipe inira rẹ pọ ju anfani rẹ lọ, dajudaju ẹniti o ba ni laakaye yoo jinna sii, ẹ ko waa ri alaye yii lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, o nbẹ nibẹ ifaara sise ọti ni eewọ. Awọn ijọ rẹ yoo si bi ọ leere - irẹ Anọbi - nipa odiwọn ti wọn yoo maa na ninu owo wọn, ni ojupọnna sise asegbọrẹ ati oore atinuse asekun? Sọ ni ẹniti ndawọn lohun wipe: ẹ maa na ninu awọn owo yin, eyiti o ba le silẹ nibi bukaata yin (ti o si jẹ wipe paapaa, eleyi ni akọkọ asẹ lẹyin igba naa ni Ọlọhun Ọba Allah waa se ‘Saka’ yiyọ ni dandan ninu awọn dukia eyiti a sa lẹsa ati awọn ipin kan ti a se adayanri) pẹlu iru alaye yii eyiti ti ko ni iruju ninu, ni Ọlọhun Ọba Allah fi nse alaye fun yin, awọn ofin Sẹria, ki ẹ le baa jẹ ẹniti yoo ronu.
Sise aimọkan pẹlu awọn igbẹyin awọn alamọri le sọ ọmọniyan ni paapaa di ẹniti yoo maa korira ohun ti yoo se ni anfaani, ti yoo si maa nifẹ ohun ti yoo ko inira baa, o wa di dandan fun ọmọniyan lati maa beere lọwọ Ọlọhun Ọba Allah, imọna lọsi oju ọnaamọ.
Islam wa gbigbe awọn nkan Abeewọ tobi ati kikọ mima kọja ẹnu aala le lori ninu eyiti o tobi nibẹ, ni mima kọdi awọn eniyan kuro nibi oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga.
Awọn alaigbagbọ ko nii yẹ lailai ni ẹniti yoo maa ja Islam logun ati awọn ti nse Islam, titi wọn yoo mu wọn jade kuro ninu ẹsin wọn, Ọlọhun Ọba Allah yoo si sọ ete awọn alaigbagbọ di ohun ti o lẹ.
Nini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga ati sise irin-ajo lọ si ọdọ Rẹ, ati jijagun lọsi oju ọna Rẹ ni eyiti o tobi ninu awọn atẹgun eyiti ọwọ ọmọniyan yoo fi tẹ ikẹ Ọlọhun Ọba Allah ati aforijin Rẹ.
Ṣhẹria se gbogbo ohun ti inira ti ga ju ba nbẹ nibẹ ni eewọ, koda bi awọn anfaani kan ba nbẹ nibẹ; ni iwoyesi ohun ti o dara fun awọn ẹru.