يُبَشِّرُهُمۡ رَبُّهُم بِرَحۡمَةٖ مِّنۡهُ وَرِضۡوَٰنٖ وَجَنَّٰتٖ لَّهُمۡ فِيهَا نَعِيمٞ مُّقِيمٌ 21
Ọlọhun Ọba Allah nfun wọn niro nkan ti o dun mọ wọn ninu ninu ikẹ Rẹ ati sisọ iyọnu Rẹ di ẹtọ fun wọn, ti ko nii binu si wọn lailai ati wiwọ awọn ọgba onidẹra ti idẹkun gbere toi ko nii tan lailai wa nibẹ.
خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥٓ أَجۡرٌ عَظِيمٞ 22
Wọn yoo maa wa ninu ọgba idẹra naa ni wiwa ti ko nii ni opin gẹgẹ bi ẹsan lori isẹẹre wọn ti wọn se ni ile aye, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni ẹsan lọdọ fun ẹniti o ba tẹle asẹẹ Rẹ, ti o si jinna si ohun ti O kọ niti sise afọmọ ẹsin fun Un.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُوٓاْ ءَابَآءَكُمۡ وَإِخۡوَٰنَكُمۡ أَوۡلِيَآءَ إِنِ ٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡكُفۡرَ عَلَى ٱلۡإِيمَٰنِۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ 23
Ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ti ẹ si ntẹle ohun ti ojisẹ Rẹ muwa, ẹ ma sọ awọn baba yin ati awọn ọmọ iya yin ninu mọlẹbi ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu alasunmọ di ẹni mimọ ti ẹyin yoo mu ni alatilẹyin lati lee ma tan kọkọ awọn olugbagbọ ododo ka, tabi ki ẹ tun maa jiroro pẹlu wọn; nigbati wọn ba gbọla fun keferi ju igbagbọ fun Allah nikan soso lọ, ẹniti o ba sọ wọn di alaayo, ti wọn si wa lori jijẹ keferi, ti o si nse afihan ifẹ si wọn, o ti sẹ Ọlọhun Ọba Allah, o se abosi ara rẹ pẹlu wipe o mu ẹmin rẹ lọ si ibi iparun lati ara ẹsẹ.
قُلۡ إِن كَانَ ءَابَآؤُكُمۡ وَأَبۡنَآؤُكُمۡ وَإِخۡوَٰنُكُمۡ وَأَزۡوَٰجُكُمۡ وَعَشِيرَتُكُمۡ وَأَمۡوَٰلٌ ٱقۡتَرَفۡتُمُوهَا وَتِجَٰرَةٞ تَخۡشَوۡنَ كَسَادَهَا وَمَسَٰكِنُ تَرۡضَوۡنَهَآ أَحَبَّ إِلَيۡكُم مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَجِهَادٖ فِي سَبِيلِهِۦ فَتَرَبَّصُواْ حَتَّىٰ يَأۡتِيَ ٱللَّهُ بِأَمۡرِهِۦۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ 24
Sọ wipe - ire ojise -: ti awọn baba yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ati awọn ọmọ yin ati ọmọ iya yin ati awọn iyawo yin ati awọn alasunmọ yin ati awọn dukia yin ti ẹ ko jọ ati owo yin eyiti ẹ nifẹ si ere rẹ, ti ẹ si npaya ofo rẹ ati awọn ile yin ti ẹ nifẹ lati maa gbe, ti gbogbo eleyi ba jẹ ohun ti ẹ nifẹ si ju Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ lọ, tabi ju igbiyanju si oju ọna Rẹ lọ, ki ẹ yaa maa reti ijiya ti yoo sọkalẹ fun yin, Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi awọn ti wọn kuro ni ibi itẹle asẹ Rẹ se kongẹ isẹ ti yoo yọ ninu.
لَقَدۡ نَصَرَكُمُ ٱللَّهُ فِي مَوَاطِنَ كَثِيرَةٖ وَيَوۡمَ حُنَيۡنٍ إِذۡ أَعۡجَبَتۡكُمۡ كَثۡرَتُكُمۡ فَلَمۡ تُغۡنِ عَنكُمۡ شَيۡٔٗا وَضَاقَتۡ عَلَيۡكُمُ ٱلۡأَرۡضُ بِمَا رَحُبَتۡ ثُمَّ وَلَّيۡتُم مُّدۡبِرِينَ 25
Paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti ran yin se - ẹyin olugbagbọ ododo - lori ọta yin ninu awọn olusebọ ninu ọpọlọpọ ogun pẹlu kikere onka yin ati lilẹ imura silẹ yin nigbati ẹ gbara le Ọlọhun Ọba Allah ti ẹ si se awọn okunfa, ti ẹ ko jọ ara yin loju pẹlu pipọ yin, kii se pipọ ni o mu yin ri aranse le wọn lori, sugbọn ni ọjọ ‘hunayni’ nigbati pipọ yin jọ yin loju, ti ẹ sọ wipe: a ko le bori tori kikere wa, pipọ yin ti o jọ yin loju ko se yin lanfaani, ni awọn ọta yin fi bori yin, ni ilẹ si fi fun mọ yin bi o se gbaaye to, lẹyin naa ti ẹ pẹyin da kuro ni ọdọ awọn ọta ni ẹniti nsalọ ti a ti bori.
ثُمَّ أَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَعَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَأَنزَلَ جُنُودٗا لَّمۡ تَرَوۡهَا وَعَذَّبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡكَٰفِرِينَ 26
Lẹyin igbati ẹ sa kuro ni ọdọ ọta, Ọlọhun Ọba Allah sọ ifọkanbalẹ fun ojisẹ Rẹ, O si tun sọ kalẹ fun awọn olugbagbọ ododo, wọn wa duro sinsin fun ijagun, ỌLọhun Ọba waa sọ awọn malaika ti ẹ ko fi oju ri kalẹ, O si fi iya jẹ awọn keferi latari pipa, imulẹru ati gbigba dukia wọn, ati mimu awọn ọmọ wọn lẹru, eleyi jẹ ẹsan ti a san fun awọn eniyan wọnyi, ohun si ni ẹsan awọn keferi ti wọn jẹ olupe ojisẹ wọn nirọ, ti wọn jẹ olugunri kuro nibi nkan ti o mu wa.
Ipo ọla ti nbẹ fun awọn olugbiyanju si oju ọna Ọlọhun Ọba pọ, awọn ni ẹniti ipo wọn tobi ju ni ọdọ Ọlọhun ni ipo agbega, ti wọn ni iyi ati ipo giga, awọn ti wọn jere, ti wọn si jẹ ẹniti o la, awọn Ọlọhun Ọba wọn fun wọn niro idunnu idẹra.
Itọka ti o tobi lori jijẹ ọranyan ifẹ Ọlọhun Ọba ati ojisẹ Rẹ wa ninu awọn aayah naa, ati titi ifẹ yii siwaju ohun kihun.
Sisa ọjọ ‘hunayni’ lẹsa nkan iranti laarin awọn ọjọ ogun nitori ariwoye sise aranse nibi itẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ti o wa nibẹ, atiu sisẹlẹ ibori nigbati a ba gbọla fun ipin aye lori itẹle asẹ.
Ọla ti nbẹ fun sisọkalẹ ifọkanbalẹ, ifọkanbalẹ ojisẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ji ifọkanbalẹ awọn olugbafa ti wọn wa pẹlu rẹ pẹlu aranse, bẹẹ ni ifọkanbalẹ awọn olugbagbọ ododo jẹ ifọkanbalẹ iduro sinsin ati akin lẹyin ikanra ati ipaya.