۞وَٱذۡكُرۡ أَخَا عَادٍ إِذۡ أَنذَرَ قَوۡمَهُۥ بِٱلۡأَحۡقَافِ وَقَدۡ خَلَتِ ٱلنُّذُرُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَمِنۡ خَلۡفِهِۦٓ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ 21
Tun ranti - irẹ ojisẹ - Huudu tii se ọmọ iya Haadi ninu ibi nigbati o se ikilọ fun awọn ijọ rẹ nibi sisẹlẹ iya le wọn lori, wọn si wa ni aaye wọn nibi ilẹ yeepẹ ni abala erekusu ilẹ larubawa, paapaa awọn ojisẹ ti re kọja ni ẹniti wọn nse ikilọ fun awọn ijọ wọn siwaju hudu ati ni ẹyin rẹ ni ẹniti wọn nsọ fun awọn ijọ wọn pe: ẹ ko gbọdọ sin nkankan ayaafi Allah nikan soso, ki ẹ sin nkan miran pẹlu Rẹ, dajudaju emi npaya iya le yin lori - ẹyin ijọ mi - ni ọjọ ti o tobi ohun si ni ọjọ igbende.
قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِتَأۡفِكَنَا عَنۡ ءَالِهَتِنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 22
Awọn ijọ rẹ sọ fun: se o de lati yi wa kuro nibi ijọsin awọn ọlọhun wa ni?! Eleyi ko le ri bẹẹ, mu wa fun wa nkan ti ohun nse ni adehun fun wa ninu iya, ti o ba jẹ olootọ nibi ohun ti o npe apemọra rẹ.
قَالَ إِنَّمَا ٱلۡعِلۡمُ عِندَ ٱللَّهِ وَأُبَلِّغُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦ وَلَٰكِنِّيٓ أَرَىٰكُمۡ قَوۡمٗا تَجۡهَلُونَ 23
O sọ wipe: dajudaju imọ asiko iya wa ni ọdọ Allah, emi ko nimọ nipa rẹ sugbọn emi jẹ ojisẹ ti o mu de etigbọ yin nkan ti wọn ran mi nisẹ si yin, sugbọn mo ri yin ni ijọ alaimọkan si ohun ti yoo se yin ni anfaani, ti ẹ si ngbe ju silẹ ati ohun ti yoo ko inira ba yin, ti ẹ si nlọ sibẹ.
فَلَمَّا رَأَوۡهُ عَارِضٗا مُّسۡتَقۡبِلَ أَوۡدِيَتِهِمۡ قَالُواْ هَٰذَا عَارِضٞ مُّمۡطِرُنَاۚ بَلۡ هُوَ مَا ٱسۡتَعۡجَلۡتُم بِهِۦۖ رِيحٞ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٞ 24
Nigbati iya ti wọn nkanju rẹ wa ba wọn, wọn ri ni ẹsujo ti o sẹri si abala kan ni sanmọ, ti o si da oju kọ awọn ọgbun wọn, wọn sọpe: eleyi ni ohun ti o sẹri lati fun wa ni omin ojo, Huudu sọ fun wọn pe: ọrọ ko ri bi ẹ se nlero wipe esu ti yoo rọ ojo fun yin ni, bikosepe ohun ni iya ti ẹ nkanju rẹ, ohun si ni atẹgun ti iya inira nbẹ nibẹ.
تُدَمِّرُ كُلَّ شَيۡءِۢ بِأَمۡرِ رَبِّهَا فَأَصۡبَحُواْ لَا يُرَىٰٓ إِلَّا مَسَٰكِنُهُمۡۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 25
Ti yoo maa pa gbogbo nkan run ti o ba ti re kọja lara rẹ lati ibi asẹ Allah fun iparun rẹ, gbogbo wọn wa di ẹni iparun, ẹnikan ko le ri ju awọn ile wọn ti wọn ngbebẹ lọ ti o njẹri si bibẹ wọn ninu rẹ siwaju, iru ẹsan inira yii ni a o fi sẹsan fun awọn ẹlẹsẹ olorikunkun lori keferi wọn ati ẹsẹ wọn.
وَلَقَدۡ مَكَّنَّٰهُمۡ فِيمَآ إِن مَّكَّنَّٰكُمۡ فِيهِ وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ سَمۡعٗا وَأَبۡصَٰرٗا وَأَفِۡٔدَةٗ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُمۡ سَمۡعُهُمۡ وَلَآ أَبۡصَٰرُهُمۡ وَلَآ أَفِۡٔدَتُهُم مِّن شَيۡءٍ إِذۡ كَانُواْ يَجۡحَدُونَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ 26
Paapaa a si ti fun ijọ Huud ni awọn okunfa igbalaye eyiti a ko fun yin ni iru rẹ, a si fun wọn ni etigbọ ti wọn yoo fi maa gbọ ọ ati awọn iriran ti wọn yoo fi maa ri i, ati awọn ọkan ti wọn yoo fi maa se laakaye pẹlu rẹ, sugbọn awọn etigbọ wọn ati awọn iriran ati awọn laakaye wọn ko rọ wọn lọrọ kankan, ko daabobo wọn kuro nibi iya nigbati o de, nigbati o jasipe wọn se aimoore si awọn amin Allah, ohun ti wọn nfi se yẹyẹ ninu awọn iya eyiti anọbi wọn Huudu ti ọla nbẹ fun nfi ndẹru ba wọn wa sọkalẹ si wọn.
وَلَقَدۡ أَهۡلَكۡنَا مَا حَوۡلَكُم مِّنَ ٱلۡقُرَىٰ وَصَرَّفۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 27
Paapaa a ti mu iparun ba gbogbo ohun ti o nbẹ lẹgbẹ yin - ẹyin ara ilu mẹkkah - ninu awọn abule, paapaa a mu iparun ba Haadi ati samuudu ati Luuth ati awọn ẹni madiyana, a si mu oniranran awijare ati awọn ẹri fun wọn; ni ireti ki wọn le sẹri kuro ibi keferi wọn.
فَلَوۡلَا نَصَرَهُمُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ قُرۡبَانًا ءَالِهَةَۢۖ بَلۡ ضَلُّواْ عَنۡهُمۡۚ وَذَٰلِكَ إِفۡكُهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ 28
Kilode ti awọn oosa wọn ko wa ran wọn se eyiti wọn nmu ni ọlọhun yatọ si Allah, ti wọn si nse asunmọ rẹ pẹlu ijọsin ati iduran?! Ko ran wọn se rara bikosepe o fi ara pamọ fun wọn kuro nibi ohun ti wọn nfẹ, eleyi ni irọ wọn ati adapa irọ wọn eyiti wọn fi nse iyanran ninu ẹmin wọn wipe awọn oosa yii nse anfaani fun wọn, o si nsipẹ fun wọn ni ọdọ Allah.
Imọ kọkọ ko si fun awọn ojisẹ ayaafi ti lọhun wọn ba mu oju wọn to ninu rẹ.
Gbigba itanjẹ ijọ Huud nigbati wọn lero pe iya ti o fẹ sọkalẹ jẹ ojo fun wọn, wọn ko ronu piwada siwaju ki o to ba wọn lojiji.
Agbara ijọ Haadi ju ijọ kurayshi lọ, pẹlu bẹẹ na Allah pa wọn run.
Onilaakaye ni ẹniti o gba isiti lati ara ẹlomiran, alaimọkan si ni ẹniti wọn ngba isiti lati ara rẹ.