وَقَالُواْ لِجُلُودِهِمۡ لِمَ شَهِدتُّمۡ عَلَيۡنَاۖ قَالُوٓاْ أَنطَقَنَا ٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَنطَقَ كُلَّ شَيۡءٖۚ وَهُوَ خَلَقَكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ 21
Awọn keferi sọ fun awọn ara wọn: kilode ti ẹ fi njẹri le wa lori nipa ohun ti a se ni ile aye?! Awọn ara wọn yoo sọrọ niti fifesi fun awọn ẹniirẹ: Allah ni O fun wa lọrọsọ eyiti o fun gbogbo nkan lọrọsọ, Oun ni o si da yin ni igba akọkọ nigbati ẹ wa ni ile aye, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o si sẹri si ni ọrun fun isiro ati ẹsan.
وَمَا كُنتُمۡ تَسۡتَتِرُونَ أَن يَشۡهَدَ عَلَيۡكُمۡ سَمۡعُكُمۡ وَلَآ أَبۡصَٰرُكُمۡ وَلَا جُلُودُكُمۡ وَلَٰكِن ظَنَنتُمۡ أَنَّ ٱللَّهَ لَا يَعۡلَمُ كَثِيرٗا مِّمَّا تَعۡمَلُونَ 22
Ati ohun ti ẹ nfi pamọ nigbati ẹ da awọn ẹsẹ ki awọn etigbọ yii maa ba jẹri le yin lori ati awọn iriran yin ati awọn awọ ara yin; nitoripe dajudaju ẹ ko nigbagbọ ninu isiro tabi iya tabi ẹsan lẹyin iku, sugbọn ẹ lero wipe dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun ko mọ ọpọ nkan ti ẹ nse, bikosepe o pamọ fun Un ni ẹ fi gba itanjẹ.
وَذَٰلِكُمۡ ظَنُّكُمُ ٱلَّذِي ظَنَنتُم بِرَبِّكُمۡ أَرۡدَىٰكُمۡ فَأَصۡبَحۡتُم مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ 23
Eleyi jẹ ero aburu ti ẹ ro ro Ọlọhun Ọba yin, O si pa yin run, ẹ wa di ẹni ofo awọn ti wọn sofo aye ati ọrun nitori eleyi.
فَإِن يَصۡبِرُواْ فَٱلنَّارُ مَثۡوٗى لَّهُمۡۖ وَإِن يَسۡتَعۡتِبُواْ فَمَا هُم مِّنَ ٱلۡمُعۡتَبِينَ 24
Ti awọn ti etigbọ wọn ati iriran ati awọ ara wọn ba se suuru, ina ni ibusẹri si fun wọn ati ibusinmin si ti wọn yoo si min si, ti wọn ba si wa gbigbe iya kuro ati iyọnu Allah si wọn, wọn ko le jẹ ẹniti ọwọ rẹ yoo tẹ iyọnu Rẹ, bẹẹni wọn ko le wọn ọgba idẹra lailai.
۞وَقَيَّضۡنَا لَهُمۡ قُرَنَآءَ فَزَيَّنُواْ لَهُم مَّا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ 25
A ti pese alasunmọ ninu awọn esu fun awọn keferi yii, ti yoo maa ba wọn rẹ, wọn wa se isẹ aburu wọn ni ile aye lọsọ fun wọn, wọn si se ohun ti wọn fi wọn role lori ninu ọrọ ti ọrun lọsọ fun wọn, o wa mu wọn gbagbe riranti rẹ ati sisẹ pẹlu rẹ, iya wa di dandan fun wọn ni awujọ awọn ijọ ti o ti siwaju wọn ninu alujannu ati eniyan, dajudaju wọn jẹ ẹni ofo nitoripe wọn sofo ẹmin wọn ati ti ara ile wọn pẹlu wiwọ ina wọn ni ọjọ igbende.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَا تَسۡمَعُواْ لِهَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ وَٱلۡغَوۡاْ فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَغۡلِبُونَ 26
Awọn keferi sọ ni ẹniti nsọ asọtẹlẹ laarin wọn nigbati wọn kagara lati fi ẹri da oju kọ ẹri: ẹ mase tẹtigbọ Alukuraani yii eyiti Muhammad nka fun yin, ki ẹ si ma tẹriba fun ohun ti o wa ninu rẹ, ẹ ma pariwo, ki ẹ si maa gbe ohun yin soke nigbati o ba nka a; o seese ki ẹ ti ibi eleyi ri aranse le lori ti yoo fi gbe kika rẹ ju silẹ ati ipepe si ibẹ, ki a le sin mi nipa rẹ.
فَلَنُذِيقَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَذَابٗا شَدِيدٗا وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَسۡوَأَ ٱلَّذِي كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 27
Paapaa a o fi iya ti o le koko tọ awọn ti o se keferi si Allah, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ lẹnu wo ni ọjọ igbende, paapaa a o san ẹsan ti o buru ju ohun ti wọn se lẹbọ ati ẹsẹ lẹsan iya fun wọn.
ذَٰلِكَ جَزَآءُ أَعۡدَآءِ ٱللَّهِ ٱلنَّارُۖ لَهُمۡ فِيهَا دَارُ ٱلۡخُلۡدِ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ بَِٔايَٰتِنَا يَجۡحَدُونَ 28
Ẹsan ti a sọ yii jẹ ẹsan awọn ọta Allah ti wọn se keferi si I, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ: ina, gbere nbẹ fun wọn nibẹ, ti ko si nii ja lailai; ni ẹsan lori jija awọn amin Allah niyan ati ainigbagbọ wọn si I pẹlu hihande rẹ ati lilagbara awijare rẹ.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ رَبَّنَآ أَرِنَا ٱلَّذَيۡنِ أَضَلَّانَا مِنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِ نَجۡعَلۡهُمَا تَحۡتَ أَقۡدَامِنَا لِيَكُونَا مِنَ ٱلۡأَسۡفَلِينَ 29
Awọn ti o se keferi si Allah, ti wọn si pe awọn ojisẹ Rẹ nirọ waa sọpe: Ọlọhun wa, fi awọn meji ti o si wa lọna ninu alujannu ati eniyan han wa: ibilisu eyiti o pilẹ keferi ati ipepe sibẹ, ati ọmọ Adamọ eyiti o fi ipilẹ tita awọn ẹjẹ silẹ lelẹ, ki a fi awọn mejeeji si abẹ gigisẹ wa ninu ina; ki wọn le wa ninu ẹni ilẹ ti iya wọn yoo lagbara ju ninu ẹni ina.
Riro ero aburu pẹlu Allah jẹ iroyin kan ninu awọn iroyin keferi.
Keferi sise ati awọn ẹsẹ jẹ okunfa ti awọn esu fi ma njẹ gaba lori ọmọniyan.
Rirankan awọn alawokọse wipe ki awọn ti awọn ntẹẹle ri iya ti o lagbar ju ni ọjọ igbende.