وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَدۡنَىٰ دُونَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَكۡبَرِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ 21
Paapaa a o fi iya jẹ awọn opurọ ti wọn kuro nibi itẹle asẹ Ọlọhun Ọba wọn pẹlu idaamun ati wahala ni ile aye siwaju iya ti o tobi ti a pees fun wọn ni ọrun ti wọn ko ba ronu piwada; o seese ki wọn sẹri lọsi ibi itẹle asẹ Ọlọhun Ọba wọn.
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِۦ ثُمَّ أَعۡرَضَ عَنۡهَآۚ إِنَّا مِنَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ مُنتَقِمُونَ 22
Ko si ẹniti o se abosi to ẹniti wọn se isiti awọn amin Allah fun, ti ko si gba isiti naa, ti o si ẹri kuro nibẹ niti aini akakun rẹ, dajudaju awa jẹ olugbẹsan ti ko si iyemeji lara awọn ẹlẹsẹ - lori gigunle aimoore ati ẹsẹ awọn ti o gunri kuro nibi awọn amin Allah -.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَلَا تَكُن فِي مِرۡيَةٖ مِّن لِّقَآئِهِۦۖ وَجَعَلۡنَٰهُ هُدٗى لِّبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 23
Paapaa a ti fun Musa ni taoreeta, ma se wa ninu - irẹ ojisẹ - iyemeji nibi pipade rẹ musa nibi alẹ irin oru ati igoke, a si se iwe naa ti a sọkalẹ fun Musa ni olutọni sọna fun awọn ọmọ isirẹli kuro nibi anu.
وَجَعَلۡنَا مِنۡهُمۡ أَئِمَّةٗ يَهۡدُونَ بِأَمۡرِنَا لَمَّا صَبَرُواْۖ وَكَانُواْ بَِٔايَٰتِنَا يُوقِنُونَ 24
A si se awọn asiwaju ti awọn eniyan yoo maa tẹle nibi ododo ninu awọn ọmọ isirẹli, ti wọn yoo maa juwe fun wọn lọsi ibi ododo pẹlu iyọnda Wa fun wọn, ati fifunwọn lagba lori rẹ, nigbati wọn ba se ifarada lori itẹle awọn asẹ Allah ati ijina si awọn nkan ti O kọ ati lori suta ni oju ọna ipepe, wọn si jẹ ẹniti o gba awọn amin Allah ti a sọkalẹ fun ojisẹ wọn lododo ni igbalododo ti o pe.
إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفۡصِلُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ 25
Dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - ni Yoo se aseyanju laarin wọn ni ọjọ igbende nibi ohun ti wọn se iyemeji si ni ile aye, bayi ni olootọ yoo hande kuro nibi olubilẹjẹ, Yoo si san ẹnikọọkan lẹsan ohun ti o ba tọ si.
أَوَ لَمۡ يَهۡدِ لَهُمۡ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ يَمۡشُونَ فِي مَسَٰكِنِهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٍۚ أَفَلَا يَسۡمَعُونَ 26
Se awọn wọnyi fọju ni ti ko fi han si wọn iye awọn ti A ti pa run siwaju wọn ninu awọn ijọ ti o re kọja?! Se bi awọn ni wọn ti nrin ninu awọn ibugbe wọn ti wọn ngbe siwaju ki a to pa wọn run, wọn ko si wa gba isiti pẹlu isesi wọn, dajudaju ariwoye ti a le fi se itọka lori ododo awọn ojisẹ wọn ti wọn wọn wa lati ọdọ Allah nbẹ nibi isẹlẹ ti o sẹlẹ si awọn ijọ gẹgẹ bi iparun nitori aimoore wọn ati awọn ẹsẹ wọn, se awọn opurọ wọnyi ko wa gbọ awọn amin Allah ni gbigbọ gbigba ati igba isiti ni?!
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا نَسُوقُ ٱلۡمَآءَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡجُرُزِ فَنُخۡرِجُ بِهِۦ زَرۡعٗا تَأۡكُلُ مِنۡهُ أَنۡعَٰمُهُمۡ وَأَنفُسُهُمۡۚ أَفَلَا يُبۡصِرُونَ 27
Se awọn opurọ wọnyi ko wa ri igbende ni wipe awa ni a nransẹ omin oju si ilẹ ti o ti sa, ti ko si irugbin nibẹ, ti a si ntibi omin naa mu irugbin jade, ti rakunmi wọn ati maalu wọn ati aguntan wọn yoo maa jẹ nibẹ, ti awọn naa si njẹ nibẹ?! Se wọn ko ri eleyi ni, wọn ko si lepa ba wipe ẹniti o mu irugbin jade ni ilẹ ti o ti sa ni agbara lati ji awọn oju dide?!
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡفَتۡحُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 28
Awọn ti wọn npe ijinde nirọ yii yoo maa sọ ni ẹniti o nkanju iya: igba wo ni idajọ ti ẹ nlero yii wipe yoo se onpinya laarin wa ati ẹyin ni ọjọ igbende, ti ibusẹri wa yoo si jasi ina, ti ibusẹri ti yin yoo si jẹ ọgba idẹra?!
قُلۡ يَوۡمَ ٱلۡفَتۡحِ لَا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِيمَٰنُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ 29
Sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: adehun jẹ ọjọ igbende, ohun ni ọjọ onpinya laarin awọn ẹru ni igbati igba lododo awọn ti o se keferi si Allah ni ile aye lẹyin riri ọjọ igbende ko le se wọn ni anfaani, wọn ko si nii le lọ wọn lara ti wọn yoo fi waa ronu piwada lọsi ọdọ Ọlọhun Ọba wọn, ti wọn yoo si sẹri si ọdọ Rẹ.
فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ وَٱنتَظِرۡ إِنَّهُم مُّنتَظِرُونَ 30
Ki o ya gunri - irẹ ojisẹ - kuro ni ọdọ awọn eniyan wọnyi lẹyin itẹsiwaju nibi ọna anu wọn, ki o si maa reti ohun ti yoo sẹlẹ si wọn, dajudaju wọn nreti iya ti wọn se ni adehun fun wọn.
Ijiya keferi ni ile aye jẹ okunfa ironu piwada rẹ.
Fifi rinle ipade laarin anọbi wa ẹniti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati musa ẹniti ọla nbẹ fun ni alẹ irin ajo oru ati igoke sanmọ.
Suuru ati amọdaju jẹ iroyin awọn ẹni isaaju ninu ẹsin.