۞يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ وَمَن يَتَّبِعۡ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِ فَإِنَّهُۥ يَأۡمُرُ بِٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِۚ وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ مَا زَكَىٰ مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ أَبَدٗا وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يُزَكِّي مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٞ 21
Ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo ninu Allah ti wọn si nse ofin Rẹ, ẹ mase tẹle ojupọnna esu nibi sise ibajẹ ni ọsọ, ẹniti o ba tẹle awọn ojupọnna rẹ, dajudaju yoo pa a lasẹ ibajẹ awọn isẹ awọn ọrọ ati ohun ti ofin tako, ti kii ba se ọla Allah le yin lori - ẹyin olugbagbọ ododo - ẹnikankan ninu yin ki ba ti mọ lati ibi ironu piwada ti ẹ ba sẹri, sugbọn Ọlọhun Allah ni o ma nse afọmọ ẹniti o ba wu U pẹlu gbigba ironu piwada rẹ, Allah si jẹ olugbọ awọn ọrọ yin, Onimimọ si awọn isẹ yin, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, yoo si san yin lẹsan le lori.
وَلَا يَأۡتَلِ أُوْلُواْ ٱلۡفَضۡلِ مِنكُمۡ وَٱلسَّعَةِ أَن يُؤۡتُوٓاْ أُوْلِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينَ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ وَلۡيَعۡفُواْ وَلۡيَصۡفَحُوٓاْۗ أَلَا تُحِبُّونَ أَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٌ 22
Ki awọn ti lọla ninu ẹsin ati awọn ti o gbaaye ni arisiki mase bura lori gbigbe itọrẹ fun awọn alasunmọ wọn ti wọn ni bukaata ju silẹ - nitori osi ti wọn bẹ nibẹ ninu awọn oluse irin ajo si oju ọna Allah - nitori ẹsẹ eyiti wọn gun le, ki wọn yaa se amojukuro fun wọn, ki wọn si mu ọkan kuro, se ẹ ko nifẹ si ki Allah fi ori jin yin nibi ẹsẹ yin ni, nigbati ẹyin naa ba si se amoju kuro fun wọn, ti ẹ si mu ọkan kuro?! Ọlọhun Allah jẹ oluforijin ẹniti o ba sẹri ninu awọn ẹru Rẹ, Olukẹ si ni O jẹ si wọn, ki awọn ẹru Rẹ naa si maa kọse Rẹ. Ayah yii sọkalẹ nipa Abu bakr olododo ki iyọnu Allah maa ba a nigbati o buro lori gbigbe inawo iranlọwọ ju silẹ fun ‘mistọhi’ nitori wipe o wa pẹlu awọn ti o parọ agbere.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَرۡمُونَ ٱلۡمُحۡصَنَٰتِ ٱلۡغَٰفِلَٰتِ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ لُعِنُواْ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ 23
Dajudaju awọn ti wọn nparọ agbere mọ awọn alamumọra alaimọkan nipa ibajẹ eyiti awọn olugbagbọ ododo lobinrin ko nimọ nipa rẹ, wọn yoo maa gbe wọn jinna kuro nibi ikẹ Allah ni aye ati lọrun, bẹẹni iya ti o tobi nbẹ fun wọn lọrun.
يَوۡمَ تَشۡهَدُ عَلَيۡهِمۡ أَلۡسِنَتُهُمۡ وَأَيۡدِيهِمۡ وَأَرۡجُلُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 24
Iya yii yoo maa bẹ fun wọn ni ọjọ igbende nigbati ahọn wọn yoo maa jẹri le wọn lori ohun ti wọn fi sọ ninu ibajẹ, awọn ọwọ wọn naa yoo si maa jẹri le wọn lori ati awọn ẹsẹ wọn pẹlu ohun ti wọn fi se.
يَوۡمَئِذٖ يُوَفِّيهِمُ ٱللَّهُ دِينَهُمُ ٱلۡحَقَّ وَيَعۡلَمُونَ أَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ ٱلۡمُبِينُ 25
Ni ọjọ yii Allah yoo pe ẹsan wọn fun wọn niti deede, wọn yoo waa mọ wipe dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun jẹ ododo, ati wipe gbogbo ohun ti wọn ba wa lati ọdọ Rẹ niro tabi adehun daadaa tabi adehun iya, ododo ti o fi oju han ni ti ko si iyemeji nibẹ.
ٱلۡخَبِيثَٰتُ لِلۡخَبِيثِينَ وَٱلۡخَبِيثُونَ لِلۡخَبِيثَٰتِۖ وَٱلطَّيِّبَٰتُ لِلطَّيِّبِينَ وَٱلطَّيِّبُونَ لِلطَّيِّبَٰتِۚ أُوْلَٰٓئِكَ مُبَرَّءُونَ مِمَّا يَقُولُونَۖ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ 26
Gbogbo onibajẹ lọkunrin tabi lobinrin tabi awọn ọrọ tabi awọn isẹ yoo se deede ati kongẹ ohun ti o ba jẹ ibajẹ, gbogbo ohun ti o si dara nibi eleyi yoo se deede ati kongẹ ohun ti o dara, awọn wọnyi ni ẹni daadaa lọkunrin ati lobinrin, ti wọn si jẹ alaimọwọ mọsẹ nipa ohun ti awọn obilẹjẹ lakọ ati obilẹjẹ labo nsọ nipa wọn, aforijin Allah nbẹ fun wọn ti yoo fi se amojukuro fun awọn asise wọn, arisiki alapọnle naa si wa fun wọn eyitii se alujannah.
Nigbati yiyọju wo ihoho jẹ okunfa kiko ina adun eyiti yoo mu ni lọ si ibi gigunle agbere ti a darukọ ni ibẹrẹ suurah naa, Ọlọhun Allah pasẹ gbigba iyọnda ki a to wọ awọn ile; ki o le jẹ idaabobo fun oju nibi yiyọju si awọn ihoho, O waa sọpe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَدۡخُلُواْ بُيُوتًا غَيۡرَ بُيُوتِكُمۡ حَتَّىٰ تَسۡتَأۡنِسُواْ وَتُسَلِّمُواْ عَلَىٰٓ أَهۡلِهَاۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ 27
Ẹyin olugbagbọ ninu Allah, ti wọn si ofin Rẹ, ẹ ko gbọdọ wọ ile kan ti kii se ile yin titi ẹ o fi gba iyọnda lọdọ awọn ti ngbe inu ile naa ki ẹ to wọle sibẹ, ki ẹ si tun salamọ pẹlu ki ẹ sọ wipe alaafia ati iyọnda: alaafia fun yin, se ki nwọle? Eleyi ni iyọnda ti wọn pa yin lasẹ rẹ, o si loore fun yin ju ki ẹ wọle lojiji lọ, ki ẹ le baa jẹ ẹniti yoo maa se iranti ohun ti a pa yin lasẹ rẹ, ki ẹ le baa maa muse nisẹ.
Awọn itanjẹ esu ati royiroyi rẹ ma npe ni lọsi ibi gigunle ẹsẹ, ki olugbagbọ ododo yaa sọra fun un.
Sise kongẹ ironu piwada ati isẹẹre jẹ lati ọdọ Allah kii se lati ọdọ ẹru.
Sise amojukuro ati imọkan kuro fun alasise jẹ okunfa aforijin ẹsẹ.
Pipa irọ agbere mọ awọn alamumọra wa ninu awọn ẹsẹ nla.
Sise igbayọnda lofin ki o le daabobo oju ati ki o le jẹ isọ fun ọwọ ile.