وَإِذَآ أَذَقۡنَا ٱلنَّاسَ رَحۡمَةٗ مِّنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُمۡ إِذَا لَهُم مَّكۡرٞ فِيٓ ءَايَاتِنَاۚ قُلِ ٱللَّهُ أَسۡرَعُ مَكۡرًاۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكۡتُبُونَ مَا تَمۡكُرُونَ 21
Nigbati a fi idẹkun wa tọ awọn ẹlẹbọ wo, bii ojo ati itura lẹyin ọda ati ile koko ti o ti kan wọn, igba naa ni wọn yoo wa maa se yẹyẹ tabi pe awọn amin wa nirọ, sọ - irẹ ojisẹ - fun ọlọsẹbọ yii: Ọlọhun Ọba ni o ni eto ti o yara ju, Oun ni O si yara lati fi iya dẹ yin lẹkẹ, dajudaju awọn malaika onisọ nkọ ete ti ẹ nda silẹ, nkankan ko pamọ fun wọn ninu rẹ, bawo ni yoo se waa pamọ fun ẹniti o da wọn gan an, Ọlọhun Ọba Allah yoo san yin lẹsan lori ete yin.
هُوَ ٱلَّذِي يُسَيِّرُكُمۡ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا كُنتُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَجَرَيۡنَ بِهِم بِرِيحٖ طَيِّبَةٖ وَفَرِحُواْ بِهَا جَآءَتۡهَا رِيحٌ عَاصِفٞ وَجَآءَهُمُ ٱلۡمَوۡجُ مِن كُلِّ مَكَانٖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ أُحِيطَ بِهِمۡ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ لَئِنۡ أَنجَيۡتَنَا مِنۡ هَٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّٰكِرِينَ 22
Ọlọhun Ọba Allah ni ẹniti o mu yin rin - ẹyin eniyan - pẹlu gigisẹ yin lori ilẹ ati lori nkan igun yin, Oun ni O si tun mu yin rin lori omin ninu ọkọ oju omin titi ti o ja si wipe igbati ẹ ba wa ninu ọkọ oju omin lori omin, ti atẹgun ti o dara ba wa fẹ si yin, inu awọn ti wọn gun ọkọ oju omin naa yoo dun si atẹgun ti o dara yii, nigbati wọn ba wa lori idunnu yii, atẹgun ti o le yoo si tun wa ba wọn, bẹẹ ni agbara omin nla yoo tun waa ba wọn ni gbogbo ọna, iparun yoo wa bori ninu ọkan wọn; wọn yoo waa maa pe Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ni ẹniti ko nii mu nkankan miran mọ, ni ẹniti yoo maa sọ bayi wipe: ti Ọlọhun Ọba Allah ba lawa nibi wahala iparun yii, awa yoo jẹ ẹniti yoo dupẹ fun Un lori idẹkun ti O se fun wa.
فَلَمَّآ أَنجَىٰهُمۡ إِذَا هُمۡ يَبۡغُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۗ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَا بَغۡيُكُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۖ مَّتَٰعَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ ثُمَّ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُكُمۡ فَنُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 23
Nigbati O jẹ ipe wọn, ti o si la wọn kuro nibi idaamun yii, ni wọn ba tun ba ilẹ jẹ pẹlu sise keferi ati dida ẹsẹ keekeeke ati nla, ẹ taji - ẹyin eniyan - dajudaju igbẹyin tẹnbẹlẹkun yin, ti ko dara lori ara yin ni yoo sẹri si, tẹnbẹlẹkun yin ko le ko inira ba Allah, ẹyin ni ẹ o maa gbadun rẹ ni ile aye ti yoo tan, lẹyin eleyi ọdọ Wa ni isẹri si yin ni ọjọ igbende, a o fun yin ni iro nkan ti ẹ nse nisẹ ni ẹsẹ, a o si san yin lẹsan le lori.
إِنَّمَا مَثَلُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَآءٍ أَنزَلۡنَٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخۡتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلۡأَرۡضِ مِمَّا يَأۡكُلُ ٱلنَّاسُ وَٱلۡأَنۡعَٰمُ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَخَذَتِ ٱلۡأَرۡضُ زُخۡرُفَهَا وَٱزَّيَّنَتۡ وَظَنَّ أَهۡلُهَآ أَنَّهُمۡ قَٰدِرُونَ عَلَيۡهَآ أَتَىٰهَآ أَمۡرُنَا لَيۡلًا أَوۡ نَهَارٗا فَجَعَلۡنَٰهَا حَصِيدٗا كَأَن لَّمۡ تَغۡنَ بِٱلۡأَمۡسِۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ 24
Dajudaju apejuwe isẹmin aye yii, ti ẹ ngbadun nibẹ, aipẹ yii ni yoo tan, o da gẹgẹ bi apejuwe ojo ti o ti rọ si irugbin ilẹ ninu ohun ti awọn eniyan horo rẹ ati eso rẹ, ati ohun ti awọn ẹranko njẹ ninu eweko ati ohun ti o yatọ si i, titi ti ilẹ yoo fi ni awọ eyiti yoo maa se eniyan loju kokoro, yoo si rẹwa lati ara oniranran irugbin ti o jade nibẹ, ti wọn yoo fi maa lero wipe awọn lagbara lati ko ere irugbin rẹ tabi ge e, lẹyin eyi ni akọsilẹ yoo waa de lati pa a run, a o waa sọ ọ di ohun ti a ti kere, ti nkankan ko ti maa sẹmin pẹlu awọn igi naa ati awọn irugbin naa siwaju, tabi ni asiko ti o sun mọ gẹgẹ bi a se salaye isesi aye fun yin ati yiyara tan an rẹ, bẹẹ naa ni a nsalaye awọn ẹri ati awọn awijare fun awọn ti wọn le ronu, ti wọn woye.
وَٱللَّهُ يَدۡعُوٓاْ إِلَىٰ دَارِ ٱلسَّلَٰمِ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 25
Ọlọhun Ọba Allah npe gbogbo awọn eniyan lọsi alujannah Rẹ eyi tii se ile alaafia, ti awọn eniyan yoo la kuro nibi adanwo ati ibanujẹ nibẹ, wọn si tun la kuro nibi iku, bẹẹ ni Ọlọhun Ọba Allah ni O ma nfi ẹniti o ba wu u se kongẹ ninu ẹru Rẹ lọsi ẹsin alaafia eyiti yoo muni de ile alaafia yii.
Ọlọhun Ọba Allah ni ẹniti o yara ni ete ju si awọn ti wọn ba ndete si awọn ẹru Rẹ olugbagbọ ododo.
Tẹnbẹlẹkun ọmọniyan ma nsẹri lọọ ba a, ko si nii ko inira ba ẹnikankan ju oun naa lọ.
Sise alaye paapaa ile aye nibi yiyara tan ati yiyẹ rẹ ati jidẹkun ti o wa nibẹ, ti o jẹ ohun ti o ma ntan.
Alujannah ni ibusinmi si olugbagbọ ododo; nitori idẹkun ati alaafia kuro nibi adanwo ati ibanujẹ ti o wa nibẹ.