مَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يُمَتَّعُونَ 207
Kinni idẹkun ti wọn wa lori ni ile aye se fun wọn ni anfaani?! Idẹkun naa si ti ja, bẹẹ ni ko wulo kankan.
وَمَآ أَهۡلَكۡنَا مِن قَرۡيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنذِرُونَ 208
A kii pa ijọ kan run ninu awọn ijọ ayaafi lẹyin ikilọ pẹlu riran awọn ojisẹ ati sisọ awọn tira kalẹ.
ذِكۡرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَٰلِمِينَ 209
Niti isiti ati iranti fun wọn, awa kii se alabosi nibi fifi iya jẹ wọn lẹyin wiwa awijare le wọn lori lati ibẹi rirana ati ojisẹ ati sisọ awọn tira kalẹ.
وَمَا تَنَزَّلَتۡ بِهِ ٱلشَّيَٰطِينُ 210
Awọn esu ko sọkalẹ mọ Alukuraani loi ọkan ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
وَمَا يَنۢبَغِي لَهُمۡ وَمَا يَسۡتَطِيعُونَ 211
Bẹẹni ko tọ ki wọn sọkalẹ lori ọkan rẹ, koda wọn ko lagbara eleyi.
إِنَّهُمۡ عَنِ ٱلسَّمۡعِ لَمَعۡزُولُونَ 212
Wọn ko lagbara rẹ nitori wipe wọn jẹ ẹniti a yẹti kuro ni aaye rẹ lati sanmọ, bawo ni wọn se le de ibẹ, ti wọn yoo wa fi sọkalẹ pẹlu rẹ?!
فَلَا تَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَكُونَ مِنَ ٱلۡمُعَذَّبِينَ 213
Mase sin olujọsin fun miran pẹlu Allah, ti yoo maa kẹgbẹ pẹlu Rẹ, ti o fi wa di ẹni ijiya lati ara eleyi.
وَأَنذِرۡ عَشِيرَتَكَ ٱلۡأَقۡرَبِينَ 214
Ki o si maa se ikilọ - irẹ ojisẹ - fun ẹniti o sun mọ ju, lẹyin naa ni ẹniti o ba tun sun ju ninu ijọ rẹ, ki iya Allah maa ba kan wọn ti wọn ba sẹku lori ẹbọ.
وَٱخۡفِضۡ جَنَاحَكَ لِمَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 215
Rọ ẹgbẹ rẹ niti isẹ ati ọrọ fun ẹniti o ba tẹle ọ ninu awọn olugbagbọ ododo niti ikẹ fun wọn ati pẹlẹpẹlẹ.
فَإِنۡ عَصَوۡكَ فَقُلۡ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تَعۡمَلُونَ 216
Ti wọn ba sẹ ọ, ti wọn ko si jẹpe ohun ti o pa wọn lasẹ nibi imọ Ọlọhun Ọba Allah lọkan ati titẹle E; ki o sọ fun wọn wipe: dajudaju emi bọpa bọsẹ kuro nibi ohun ti ẹ nse lẹbọ ati ẹsẹ.
وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلرَّحِيمِ 217
Gbarale alagbara eyiti o ma ngbẹsan lara awọn ọta Rẹ nibi ọrọ rẹ lapapọ, ẹniti o jẹ onikẹ fun ẹniti o ba ronu piwada lọsi ọdọ Rẹ.
ٱلَّذِي يَرَىٰكَ حِينَ تَقُومُ 218
Ẹniti o nri ọ mimọ Rẹ nigbati o ba dide fun irun.
وَتَقَلُّبَكَ فِي ٱلسَّٰجِدِينَ 219
O si nri ọ mimọ Rẹ lilọ bibọ rẹ lati isesi kan si isesi miran ninu awọn ti nkirun; nkankan ko pamọ fun Un ninu ohun ti o nse tabi ninu ẹlomiran ti o yatọ si ọ nse.
إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 220
Dajudaju Oun ni olugbọ ohun ti o nke ninu Alukuraani ati iranti nibi irun rẹ, O si jẹ onimimọ si ero ọkan rẹ.
Nigbati wọn pinnu wipe awọn esu yoo sọkalẹ mọ Alukuraani; ati wipe dajudaju Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun jẹ kọrin kọrin, Ọlọhun Allah da ọrọ pada si wọn lẹnu lori ero wọn, O si sọ wipe:
هَلۡ أُنَبِّئُكُمۡ عَلَىٰ مَن تَنَزَّلُ ٱلشَّيَٰطِينُ 221
Se ki nfun yin niro ẹniti awọn esu sọkalẹ le lori, awọn ti ẹ lero pe wọn sọkalẹ mọ Alukuraani?
تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٖ 222
Awọn esu sọkalẹ lori gbogbo parọ parọ, ẹlẹsẹ pipọ ati alasise ninu awọn alagbegba.
يُلۡقُونَ ٱلسَّمۡعَ وَأَكۡثَرُهُمۡ كَٰذِبُونَ 223
Awọn esu ma nji ọrọ gbọ lati ọdọ awọn ijọ ti o ga ju, wọn yoo si maa ju si awọn ẹni ti wọn ninu awọn alagbegba, bẹẹni ọpọ awọn alagbegba jẹ parọ parọ, ti wọn ba sọ ododo nibi gbolohun kan, wọn yoo parọ ọgọrun mọ ọ.
وَٱلشُّعَرَآءُ يَتَّبِعُهُمُ ٱلۡغَاوُۥنَ 224
Bẹẹni awọn kọrin kọrin ti ẹ lero wipe Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun wa ninu wọn, ẹniti o ntẹle wọn ni awọn ti o ti yẹ kuro ni oju ọna ọnaamọ ati iduro sinsin, wọn yoo maa gba orin ti wọn nsọ wa.
أَلَمۡ تَرَ أَنَّهُمۡ فِي كُلِّ وَادٖ يَهِيمُونَ 225
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - dajudaju ninu ohun ti o han nibi isina wọn nipe wọn ma ndaamun ninu gbogbo agbanrin ti wọn ba ti nyin yan ni awọn asiko kan ati nibi eebu ni asiko miran ati ohun ti o yatọ si mejeeji ni awọn asiko kọọkan.
وَأَنَّهُمۡ يَقُولُونَ مَا لَا يَفۡعَلُونَ 226
Ati wipe dajudaju wọn jẹ parọ-parọ; wọn yoo maa sọpe: a se eleyi, bẹẹni wọn ko si se e.
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَذَكَرُواْ ٱللَّهَ كَثِيرٗا وَٱنتَصَرُواْ مِنۢ بَعۡدِ مَا ظُلِمُواْۗ وَسَيَعۡلَمُ ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ أَيَّ مُنقَلَبٖ يَنقَلِبُونَ 227
Ayaafi awọn ti o nigbagbọ ninu awọn olorin, ti wọn si nse isẹẹre ti o pọ, ti wọn si nranti Allah ni iranti ti o pọ, ti wọn si ri aranse lori ọta wọn lẹyin igba ti wọn ti se abosi wọn gẹgẹ bi Hasan ọmọ Saabi ki iyọnu Allah maa bẹ fun un, awọn ti wọn se abosi lati ibi sise ẹbọ si Allah ati kikọja ẹnu aala si awọn ẹru Rẹ yoo pada mọ ibusẹri si eyiti wọn yoo sẹri si, bẹẹni wọn yoo si sẹri si aaye ti o tobi ati isiro winin winnin.
Fifi deedee rinlẹ fun Allah ati lile abosi jinna si I.
Fifọ Alukuraani mọ kuro nibi sisunmọ esu si i.
Pataki rirọ ati pẹlẹpẹlẹ fun awọn olupepe si ọdọ Allah.
Orin, daadaa dara bẹẹni aburu rẹ naa si buru.