أَلَمۡ نَخۡلُقكُّم مِّن مَّآءٖ مَّهِينٖ 20
Se a ko da yin - ẹyin eniyan - lati inu omin yẹpẹrẹ ti o kere, ohun si ni omin lọgbọ.
فَجَعَلۡنَٰهُ فِي قَرَارٖ مَّكِينٍ 21
A si fi omin yẹpẹrẹ naa si aaye aabo kan ohun ni apo ibi obinrin.
إِلَىٰ قَدَرٖ مَّعۡلُومٖ 22
Di asiko kan ti a mọ, ohun si ni asiko oyun.
فَقَدَرۡنَا فَنِعۡمَ ٱلۡقَٰدِرُونَ 23
A si pebubu iroyin ọmọ bibi ati odinwọn rẹ ati awọ rẹ ati ohun miran, pipataki fun ẹniti o lagbara gbogbo eleyi tii se Awa.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 24
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn olupe agbara Allah nirọ.
أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ كِفَاتًا 25
Se a ko se ilẹ ni ohun ti yoo gbe gbogbo eniyan mi lapapọ ni.
أَحۡيَآءٗ وَأَمۡوَٰتٗا 26
Ti yoo gbe awọn alaaye wọn pẹlu gbigbe lori rẹ ati lilo o mi ati awọn oku wọn pẹlu sinsin wọn sibẹ.
وَجَعَلۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ شَٰمِخَٰتٖ وَأَسۡقَيۡنَٰكُم مَّآءٗ فُرَاتٗا 27
A si se awọn oke ti o fi ẹsẹ rinlẹ sibẹ, ti yoo kọ fun un kuro nibi gbigban ni ohun ti o ga, a si fun yin mu ni omin ti o dun -ẹyin eniyan-, ẹniti o da eleyi kii se olukaga nipa jinde yin.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 28
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn olupe idẹkun Allah ti o wa lori wọn nirọ.
ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ 29
Wọn yoo si sọ fun awọn olupe ohun ti awọn ojisẹ wọn mu wa nirọ: ẹ rin lọ si ibi iya ti ẹ pe nirọ - ẹyin olupurọ -.
ٱنطَلِقُوٓاْ إِلَىٰ ظِلّٖ ذِي ثَلَٰثِ شُعَبٖ 30
Ẹ rin lọsi ibi ooji lati ibi eefin ina ti o pin si mẹta ni pinpin.
لَّا ظَلِيلٖ وَلَا يُغۡنِي مِنَ ٱللَّهَبِ 31
Ko si titutu ooji nibẹ, ko si le kọ fun ni kuro nibi ahọn ina ati igbona rẹ ki o ma bọ si yin lara.
إِنَّهَا تَرۡمِي بِشَرَرٖ كَٱلۡقَصۡرِ 32
Dajudaju ina yoo maa ju ẹtapẹrẹ rẹ, gbogbo ẹtapẹrẹ naa da gẹgẹ bi orule nibi titobi rẹ.
كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٞ صُفۡرٞ 33
Ẹta pẹrẹpẹrẹ naa ti o nju da gẹgẹ bi rakunmi dudu nibi dudu ati titobi rẹ.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 34
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa ti awọn olupe iya Allah nirọ.
هَٰذَا يَوۡمُ لَا يَنطِقُونَ 35
Wọn ko nii sọrọ kankan ni ọjọ yii.
وَلَا يُؤۡذَنُ لَهُمۡ فَيَعۡتَذِرُونَ 36
Wọn ko si ni yọnda fun wọn lati wa awijare lọ si ọdọ Ọlọhun wọn nibi keferi wọn ati awọn asise wọn ti wọn yoo wa fi wa awijare lọ si ọdọ Rẹ.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 37
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa yoo jẹ ti awọn olupe iro ọjọ yii nirọ.
هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِۖ جَمَعۡنَٰكُمۡ وَٱلۡأَوَّلِينَ 38
Ọjọ yii ni onpinya laarin awọn ẹda, a o ko yin jọ ati awọn ijọ ti o siwaju si ori yerupẹ kan soso.
فَإِن كَانَ لَكُمۡ كَيۡدٞ فَكِيدُونِ 39
Ti ọgbọn kan bawa fun yin lati le da fun lila kuro nibi iya Allah, ki ẹ ya daa si Mi.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 40
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn olupe ọjọ onpinya nirọ.
إِنَّ ٱلۡمُتَّقِينَ فِي ظِلَٰلٖ وَعُيُونٖ 41
Dajudaju awọn olupaya Ọlọhun wọn pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ yoo wa ni iboji awọn igi ọgba idẹra ti o ni ewe ati awọn omin isẹlẹru ti o dun, ti o si nsan.
وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشۡتَهُونَ 42
Ati awọn ipapanu ninu ohun ti wọn nifẹ si jijẹ rẹ.
كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيَٓٔۢا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 43
Wọn yoo si sọ fun wọn: ẹ maa jẹ ninu ohun ti o mọ, ẹ si maa mu ohun mimu ti o fi ọkan balẹ ti ko si ruru nibẹ; nitori ohun ti ẹ si ni ile aye ninu awọn isẹ rere.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 44
Dajudaju awa yoo sẹsan fun awọn oluse daadaa nibi isẹ wọn, iru ẹsan yii ti a san yin.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 45
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn olupe ohun ti Allah se ni adehun fun awọn olubẹru.
كُلُواْ وَتَمَتَّعُواْ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجۡرِمُونَ 46
Wọn yoo si sọ fun awọn opurọ: ẹ maa jẹ ki ẹ si maa gbadun pẹlu awọn igbadun isẹmin aye ni asiko diẹ ni ile aye, dajudaju ẹ jẹ ẹlẹsẹ pẹlu sise keferi yin si Allah ati pipe awọn ojisẹ Rẹ nirọ.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 47
Iparun ati ẹsẹ ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn olupe ẹsan wọn nirọ ni ọjọ ẹsan.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرۡكَعُواْ لَا يَرۡكَعُونَ 48
Ti wọn ba sọ fun awọn opurọ wọnyi: ẹ kirun fun Allah, ẹ ko nii kirun fun Un.
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ 49
Iparun ati iya ati ofo ni ọjọ naa jẹ ti awọn opurọ ti wọn npe ohun ti awọn ojisẹ mu wa ni ọdọ Allah nirọ.
فَبِأَيِّ حَدِيثِۢ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ 50
Ti wọn ko ba nigbagbọ si Alukuraani ti a sọkalẹ ni ọdọ Ọlọhun wọn, e wo ninu ọrọ miran ni wọn yoo nigbagbọ si?!
Amojuto Allah fun ọmọniyan ni inu iya rẹ.
Gbigbaaye ilẹ fun awọn ti wọn nbẹ lori rẹ ninu awọn alaaye ati fun awọn oku ti o wa nibẹ.
Ewu pipe awọn aayah Allah nirọ ati adehun iya ti o le koko fun ẹniti o ba se eleyi.