وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَوۡلَا نُزِّلَتۡ سُورَةٞۖ فَإِذَآ أُنزِلَتۡ سُورَةٞ مُّحۡكَمَةٞ وَذُكِرَ فِيهَا ٱلۡقِتَالُ رَأَيۡتَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ نَظَرَ ٱلۡمَغۡشِيِّ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡمَوۡتِۖ فَأَوۡلَىٰ لَهُمۡ 20
Awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah sọpe - ni ẹniti o nrankan ki Allah sọ ọgba ọrọ kan ti yoo ko idajọ ogun jija sinu kalẹ fun ojisẹ Rẹ -: se Allah ko nii sọ ọgba ọrọ kan kalẹ ti iranti nipa ogun jija yoo wa nibẹ, ti Allah ba sọ ọgba ọrọ kan ti o kun fun idajọ nibi alaye rẹ ati idajọ rẹ ti o kojọ lori ọrọ ogun jija kalẹ, iwọ yoo ri - irẹ ojisẹ - awọn ti iyemeji nbẹ ninu ọkan wọn ninu awọn sọbẹ selu, wọn yoo maa woọ ni wiwo ẹniti o fẹ daku nitori lile koko ipaya ati ibẹru, Allah waa se adehun iya fun wọn wipe dajudaju iya wọn ti wa pẹlu wọn, o si sun mọ wọn nitori isẹri kuro nibi ogun jija ati ipaya rẹ.
طَاعَةٞ وَقَوۡلٞ مَّعۡرُوفٞۚ فَإِذَا عَزَمَ ٱلۡأَمۡرُ فَلَوۡ صَدَقُواْ ٱللَّهَ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ 21
Ki wọn le tẹle asẹ Allah, ki wọn si sọ gbolohun ti o dara, ti ko si ikorira nibẹ loore fun wọn, ti wọn ba se ogun jija ni ọranyan, ti igbiyanju wọn si ti pe, ti wọn ba sootọ pẹlu Allah nibi igbagbọ wọn si I ati itẹle asẹ wọn fun Un, ki bẹ jẹ oore fun wọn ju sọbẹ selu ati iyapa awọn asẹ Allah lọ.
فَهَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن تَوَلَّيۡتُمۡ أَن تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَتُقَطِّعُوٓاْ أَرۡحَامَكُمۡ 22
Ohun ti yoo bori isesi yin ti ẹ ba sẹri kuro nibi igbagbọ si Allah ati titẹle E nipa ẹ o ma se ibajẹ si ori ilẹ pẹlu sise keferi ati awọn ẹsẹ, ẹ o si maa ja awọn okun ibi; gẹgẹ bi o se jẹ isesi yin ni igba imọkan.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ فَأَصَمَّهُمۡ وَأَعۡمَىٰٓ أَبۡصَٰرَهُمۡ 23
Awọn wọnyi ni a fi ibajẹ royin ni oriilẹ ati jija okun ibi, awọn ni ẹniti Allah mu jinna si ikẹ Rẹ, O si di wọn leti nibi gbigbọ ododo ni gbigbọ gbigba ati itẹriba, O mu iriran wọn lọ kuro nibi riri iwoye.
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ ٱلۡقُرۡءَانَ أَمۡ عَلَىٰ قُلُوبٍ أَقۡفَالُهَآ 24
Awọn olugunri kuro nibi Alukuraani yii ko wa ni yiri rẹ wo, ki wọn si ronu si ohun ti o wa nibẹ ni?! Ti wọn ba ronu si, ki ba tọka wọn si bi gbogbo rere, ki ba si mu wọn jinna kuro nibi gbogbo aburu tabi awọn agadagodo nbẹ lori awọn ọkan yii ni, ti wọn ti se idajọ titi pa rẹ, ti isiti kankan ko le de inu rẹ, irannileti kankan ko si le se ni anfaani?!
إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱرۡتَدُّواْ عَلَىٰٓ أَدۡبَٰرِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلۡهُدَى ٱلشَّيۡطَٰنُ سَوَّلَ لَهُمۡ وَأَمۡلَىٰ لَهُمۡ 25
Dajudaju awọn ti wọn pẹyinda kuro nibi igbagbọ wọn si keferi ati sọbẹ selu lẹyin igbati awijare ti dide le wọn lori, ti ododo anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun si han si wọn, esu ni o se keferi ati sọbẹ selu lọsọ fun wọn, o si se nirọrun fun wọn, o si tan wọn jẹ pẹlu gigun erongba.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لِلَّذِينَ كَرِهُواْ مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ سَنُطِيعُكُمۡ فِي بَعۡضِ ٱلۡأَمۡرِۖ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ إِسۡرَارَهُمۡ 26
Isini lọna yii ti o sẹlẹ si wọn jẹ nitoripe wọn sọ ni kọkọ fun awọn ẹlẹbọ ti o korira ohun ti wọn sọkalẹ fun ojisẹ rẹ ni imisi: a o ma tẹle yin nibi apakan alamọri gẹgẹ bi diduro nibi ogun, Allah mọ ohun ti wọn fi pamọ ati ohun ti wọn fi sinu, nkankan ko pamọ fun Un, yoo se afihan ohun ti o ba wu U ninu rẹ fun ojisẹ Rẹ - ti ikẹ ati ọla nbẹ fun -.
فَكَيۡفَ إِذَا تَوَفَّتۡهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَضۡرِبُونَ وُجُوهَهُمۡ وَأَدۡبَٰرَهُمۡ 27
Bawo ni iwọ yoo se ri iya ti o wa nibẹ ati isesi buruku eyiti wọn wa lori rẹ nigbati awọn Malaika ti a fi igbẹmin ran nisẹ ba gba ẹmin wọn, ti wọn nfi kumọ onirin nọ oju wọn ati ẹyin wọn.
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱتَّبَعُواْ مَآ أَسۡخَطَ ٱللَّهَ وَكَرِهُواْ رِضۡوَٰنَهُۥ فَأَحۡبَطَ أَعۡمَٰلَهُمۡ 28
Iya yii jẹ nitoripe tẹle gbogbo ohun ti o le bi Allah ninu si wọn; gẹgẹbi keferi sọbẹ selu, iba Allah ati ojisẹ Rẹ se ọta, wọn si korira ohun ti o le mu wọn sun mọ Ọlọhun wọn ati ohun ti o le mu ki iyọnu Rẹ sẹlẹ; gẹgẹ bi igbagbọ ninu Allah ati itẹle ojisẹ Rẹ, O wa mi ibajẹ ba awọn isẹ wọn.
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَن لَّن يُخۡرِجَ ٱللَّهُ أَضۡغَٰنَهُمۡ 29
Se awọn ti iyemeji nbẹ ninu ọkan wọn ninu awọn sọbẹ selu lero wipe Allah ko nii mu ikorira wọn jade ki o si fi han ni?! Paapaa yoo mu wọn jade pẹlu adanwo ati wahala; ki ẹniti o ni igbagbọ ododo le yatọ si onirọ, ki olugbagbọ ododo si hande, ki sọbẹ selu si yẹpẹrẹ.
Lila igbiyanju si oju ọna Allah bọrun ma nse adayanri awọn sọbẹ selu kuro ni oju opo awọn olugbagbọ ododo.
Pataki rironu si tira Allah ati ewo igunri kuro nibẹ.
Biba ilẹ jẹ ati jija okun ibi wa ninu awọn okunfa kikere ise kongẹ ati ijina si ikẹ Allah.