وَإِنۡ أَرَدتُّمُ ٱسۡتِبۡدَالَ زَوۡجٖ مَّكَانَ زَوۡجٖ وَءَاتَيۡتُمۡ إِحۡدَىٰهُنَّ قِنطَارٗا فَلَا تَأۡخُذُواْ مِنۡهُ شَيًۡٔاۚ أَتَأۡخُذُونَهُۥ بُهۡتَٰنٗا وَإِثۡمٗا مُّبِينٗا 20
Ati wipe ti ẹ ba gbero - ẹyin ọkọ - kikọ obirin silẹ ati fifi ẹlomiran paarọ rẹ, ko si inira kankan fun yin nibi nkan naa, ti o ba jẹ wipe ẹ jẹ ẹniti o ti fun ẹniti ẹ pinnu lati kọ silẹ ni owo ti o pọ, ni owo ori fun un, ko lẹtọ fun yin ki ẹ gba nkankan nibẹ, dajudaju gbigba ohun ti ẹ fun wọn, wọn yoo ka kun adapa irọ ti o fi oju han ati ẹsẹ ti o fi oju han!
وَكَيۡفَ تَأۡخُذُونَهُۥ وَقَدۡ أَفۡضَىٰ بَعۡضُكُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ وَأَخَذۡنَ مِنكُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا 21
Ati wipe bawo ni ẹ yoo se maa gba ohun ti ẹ fun ninu owo ori, lẹyin ohun ti o ti sẹlẹ laarn yin ninu awọn ajọsepọ ati ifẹran ati igbadun ati riran ri awọn kọkọ, toripe dajudaju mima rankan si awọn ohun ti o nbẹ ni awọn ọwọ wọn ninu owo lẹyin alamọri yii, nkan ikorira ni ati ohun ti o buru ja i, ati wipe paapaa wọn ti gba adehun kan ti o rinlẹ, ti o le koko lati ọdọ yin, ohun naa ni sisọ wọn di ẹtọ pẹlu gbolohun Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ati ofin Rẹ.
وَلَا تَنكِحُواْ مَا نَكَحَ ءَابَآؤُكُم مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِلَّا مَا قَدۡ سَلَفَۚ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةٗ وَمَقۡتٗا وَسَآءَ سَبِيلًا 22
Ati wipe ẹ mase fẹ ohun ti awọn baba yin ti fẹ ninu awọn obirin; toripe nkan naa jẹ eewọ ayaafi eyiti o ti siwaju ninu nkan naa siwaju Islam, ko si igbanimu lori rẹ, nkan naa nipa ki awọn ọmọ maa fẹ awọn iyawo awọn baba wọn jẹ alamọri kan ti aburu rẹ tobi, ati okunfa ibinu Ọlọhun Ọba Allah lori ẹniti o ba see, ati wipe o buru ni oju ọna fun ẹniti o ba tọọ.
حُرِّمَتۡ عَلَيۡكُمۡ أُمَّهَٰتُكُمۡ وَبَنَاتُكُمۡ وَأَخَوَٰتُكُمۡ وَعَمَّٰتُكُمۡ وَخَٰلَٰتُكُمۡ وَبَنَاتُ ٱلۡأَخِ وَبَنَاتُ ٱلۡأُخۡتِ وَأُمَّهَٰتُكُمُ ٱلَّٰتِيٓ أَرۡضَعۡنَكُمۡ وَأَخَوَٰتُكُم مِّنَ ٱلرَّضَٰعَةِ وَأُمَّهَٰتُ نِسَآئِكُمۡ وَرَبَٰٓئِبُكُمُ ٱلَّٰتِي فِي حُجُورِكُم مِّن نِّسَآئِكُمُ ٱلَّٰتِي دَخَلۡتُم بِهِنَّ فَإِن لَّمۡ تَكُونُواْ دَخَلۡتُم بِهِنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ وَحَلَٰٓئِلُ أَبۡنَآئِكُمُ ٱلَّذِينَ مِنۡ أَصۡلَٰبِكُمۡ وَأَن تَجۡمَعُواْ بَيۡنَ ٱلۡأُخۡتَيۡنِ إِلَّا مَا قَدۡ سَلَفَۗ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا 23
Ọlọhun Ọba Allah se ni eewọ fun yin fifẹ awọn iya yin, koda bi ọna wọn jinna soke; iyumọ rẹ naa ni iya iya, ati iya baba lati ibi abala baba tabi abala iya, ati awọn ọmọbirin yin koda bi ọna wọn jin si isalẹ, ituma rẹ naa ni ọmọbirin rẹ, ati ọmọbirin ọmọbirin rẹ bakanaa ni awọn ọmọbirin ọmọkunrin, ati awọn ọmọbirin obirin koda bi ọna wọn jin si isalẹ, ati awọn ọmọ iya yin lobirin lati ọdọ awọn obi yin mejeeji, tabi lati ọdọ ọkan ninu awọn mejeeji, ati awọn ẹgbọn baba yin lobirin tabi aburu baba yin lobirin, bakanna naa ni awọn ẹgbọn awọn baba yin lobirinati awọn aburu wọn lobirin, ati awọn iya yin koda bi ọna wọn jin soke, ati awọn ẹgbọn iya yin tabi aburu iya yin lobirin, bakanna ni awọn ẹgbọn ẹgbọn awọn iya yin ati awọn aburu wọn lobirin ati awọn ti awọn baba yin koda bi wọn jinna soke, ati awọn ọmọbirin ọmọ iya lọkunrin, ati awọn ọmọ iya lobirin, ati awọn ọmọ wọn koda bi ọna wọn jin silẹ, ati awọn iya yin, awọn ti wọn tọju yin ati awọn ọmọ iya yin lobirin nibi itọju, ati awọn iya awọn iyawo yin yala ẹ ti wọle ti wọn, tabi ẹ ko tii wọle ti wọn, ati awọn ọmọ obirin awọn iyawo yin lati ọdọ ẹlomiran ti o yatọ si yin, awọn ti wọn gbọnju, ti wọn si ngba itọju ninu ile yin lọpọlọpọ, ati wipe bakanna ni pe ti wọn ko ba gba itọju nibẹ, nigbati ẹ ba jẹ wipe ẹ ti wọle ti wọn, ati wipe sugbọn ti ẹ ko ba ti wọle ti wọn, ko si inira kankan fun yin nibi fifẹ awọn ọmọ wọn, ati wipe wọn si ni eewọ fun yin fifẹ awọn iyawo awọn ọmọ yin, awọn ti wọn jẹ ọmọ atinubi fun yin, koda bi wọn ko tii wọle ti wọn, ati wipe yoo maa wọnu idajọ yii awọn iyawo awọn ọmọ yin nibi itọju, ati wipe wọn se ni eewọ fun yin sise akojọ laarin ọmọ iyabirin meji, lati bi iran tabi itọju ayaafi eyiti o ti lọ ninu nkan naa nigba aimọkan, paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti se amojukuro nibẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ alaforinjin fun awọn ẹru Rẹ, oluronu piwada lọsi ọdọ Rẹ, O si jẹ Onikẹ wọn pẹlu, ati wipe o rinlẹ ninu sunnah sise akojọ ni eewọ bakanna laarin obirin ati ẹgbọn baba rẹ tabi aburu baba rẹ, tabi ẹgbọn iya rẹ tabi aburu iya rẹ.
Ti ọkunrin ba wọle tọ obirin rẹ paapaa owo ori rẹ ti di ẹtọ, ko lẹtọ lati kọja aaye lori rẹ tabi ki o panju mọmọ si, koda ki o fẹ pinya pẹlu rẹ ati kikọọ silẹ.
Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) se ni eewọ fifẹ awọn iyawo awọn baba, toripe ibajẹ kan ni, ti laakaye ti o ni alaafia ati adamọ ti o ni alaafia yoo fi oju aida woo.
Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) se alaye ni alaye ti o fọ si wẹwẹ, ẹniti o lẹtọ ki wọn fẹ ninu awọn obirin ati ẹniti o jẹ eewọ, yala o jẹ pẹlu okunfa iran ni tabi jijẹ anọn, tabi itọju ni gbigbe titobi fun un ije omoluabi, ati sisọ kuro nibi ikọja aala.