أَلَمۡ تَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَأَسۡبَغَ عَلَيۡكُمۡ نِعَمَهُۥ ظَٰهِرَةٗ وَبَاطِنَةٗۗ وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَلَا هُدٗى وَلَا كِتَٰبٖ مُّنِيرٖ 20
Se ẹ ko ri tabi ẹ ko jẹri si - ẹyin eniyan - dajudaju Allah se sise anfaani pẹlu ohun ti nbẹ ni sanmọ ni irọrun fun yin; gẹgẹbi oorun, osupa ati awọn irawọ, O si tun se nirọrun fun yin bakanna ohun ti nbẹ ninu ilẹ gẹgẹ bi awọn ẹranko, igi ati awọn irugbin, O si se asepe awọn idẹkun Rẹ le yin lori, ti o han lati fi oju ri; gẹgẹ bi ẹwa aworan ati isesi ti o dara, ti o si pamọ ni ipamọ laakaye ati imọ, pẹlu bibẹ awọn idẹkun yii, o nbẹ ninu awọn eniyan ti nja ọkan soso Allah niyan laisi imọ ti o gbarale debi imisi lati ọdọ Allah tabi laakaye ti o tan imọlẹ tabi iwe ti o fi oju han ti a sọkalẹ lati ọdọ Allah.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّبِعُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُواْ بَلۡ نَتَّبِعُ مَا وَجَدۡنَا عَلَيۡهِ ءَابَآءَنَآۚ أَوَلَوۡ كَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ يَدۡعُوهُمۡ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ 21
Ti wọn ba sọ fun awọn eniyan ti wọn jiyan yii nipa ọkan soso Allah: ẹ tẹle ohun ti Allah sọkalẹ fun ojisẹ Rẹ ninu imisi naa, wọn sọpe: a ko le tẹle e, bikosepe a o maa tẹle ohun ti a ba awọn asiwaju wa lori rẹ ninu ijọsin awọn ọlọhun wa, se wọn yoo maa tẹle awọn asiwaju wọn koda bi o jasi wipe esu ni o npe wọn - pẹlu ohun ti yoo sọ wọn nu nibi ijọsin awọn oosa - lọsi ibi iya sẹhiiru ni ọjọ igbende?!
۞وَمَن يُسۡلِمۡ وَجۡهَهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٞ فَقَدِ ٱسۡتَمۡسَكَ بِٱلۡعُرۡوَةِ ٱلۡوُثۡقَىٰۗ وَإِلَى ٱللَّهِ عَٰقِبَةُ ٱلۡأُمُورِ 22
Ẹniti o ba da oju kọ Allah, ti o nse afọmọ ijọsin fun Un, ti o si se daadaa nibi isẹ rẹ, paapaa o ti gba ohun ti o yi lati so papọ mọ mu, ẹniti o nreti ọla, ti ko si paya jija ohun ti o gbamun, bẹẹni ọdọ Allah nikan ni idarisi gbogbo alamọri ati ibusẹri si rẹ, Yoo si san ẹnikọọkan lẹsan ohun ti o lẹtọ si.
وَمَن كَفَرَ فَلَا يَحۡزُنكَ كُفۡرُهُۥٓۚ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُهُمۡ فَنُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 23
Ẹniti o ba se aimoore si Allah, ko gbọdọ ba ọ ninu jẹ -ire ojise- keferi rẹ sise, ọdọ Wa nikan ni ibusẹrisi wọn ni ọjọ igbende, a o fun wọn niro ohun ti wọn se ni aida ni ile aye, a o si san wọn lẹsan le lori, dajudaju Allah jẹ onimimọ ohun ti nbẹ ninu igbaaya, nkankan ko pamọ fun Un ninu ohun ti nbẹ nibẹ.
نُمَتِّعُهُمۡ قَلِيلٗا ثُمَّ نَضۡطَرُّهُمۡ إِلَىٰ عَذَابٍ غَلِيظٖ 24
A o fun wọn ni igbadun ohun ti a fun wọn ninu adun ile aye fun asiko diẹ, lẹyin naa a o wa mu wọn lugọ si ibi iya ti o le ni ọjọ igbende, ohun si ni iya ina.
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۚ قُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 25
Ti o ba beere - irẹ ojisẹ - lọwọ awọn ẹlẹbọ wọnyi: taani O da sanmọ, taani o si da ilẹ? Wọn yoo sọpe: Allah ni o da wọn.
لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ 26
Ti Allah nikan ni ohun ti nbẹ ninu sanmọ ati ohun ti nbẹ ninu ilẹ niti isẹda ati nini ati idari, dajudaju ni abọrọ ju gbogbo awọn ẹda Rẹ lọ, ẹni a nyin laye ati lọrun.
وَلَوۡ أَنَّمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن شَجَرَةٍ أَقۡلَٰمٞ وَٱلۡبَحۡرُ يَمُدُّهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦ سَبۡعَةُ أَبۡحُرٖ مَّا نَفِدَتۡ كَلِمَٰتُ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ 27
Ti o ba jasi wipe ohun ti nbẹ nilẹ ninu igi ti a ge ati gege ikọwe ti o jẹ ti omin, ti a si se odo ni jẹlu rẹ, koda ki wọn tun lekun ni odo meje, awọn gbolohun Allah ko le tan nitori ailopin rẹ, dajudaju Allah jẹ alagbara ti ẹnikankan ko le bori, ọjọgbọn nibi isẹda Rẹ ati idari Rẹ.
مَّا خَلۡقُكُمۡ وَلَا بَعۡثُكُمۡ إِلَّا كَنَفۡسٖ وَٰحِدَةٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٌ 28
Dida yin - ẹyin eniyan - tabi ajinde yin ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan, ko jẹ nkankan ayaafi gẹgẹ bi isẹda ẹmin kan soso ati gbigbe e dide nibi rirọrun rẹ, dajudaju Allah jẹ gbọrọ gbọrọ, gbigbọ ohun ẹnikan ko di I lọwọ gbigbọ ohun ẹlomiran, rina rina ti riri nkankan kan ko di I lọwọ riri nkan miran, bakanna sisẹda ẹmijn tabi gbigbe e dide ko le di lọwọ sisẹda miran ati gbigbe e dide.
Awọn idẹkun Allah jẹ okunfa idupẹ fun Un ati nini igbagbọ si I, kii se ọna sise keferi si I.
Ewu ikọse ifọju paapaa julọ nibi awọn alamọri adisọkan.
Pataki jijupa jusẹ fun Allah ati titẹriba fun Un ati sise isẹ daadaa nitori iyọnu Rẹ.
Ailopin awọn gbolohun Allah.