ٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي ٱلۡحَجِّۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيۡرَ ٱلزَّادِ ٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُونِ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ 197
Asiko Hajj jẹ awọn osu kan ti a ti mọ, ti o bẹrẹ pẹlu osu Ṣhawwal, ti o si pari pẹlu ọjọ mẹwa ‘dhil-hijja’, ẹniti o ba sọ isẹ Hajj di dandan fun ẹmi ara rẹ, ninu awọn osu yii, ti o si wọ asọ ‘hurumi’ pẹlu rẹ, o ti di eewọ fun lati maa se asepọ pẹlu obirin ati awọn ohun ti o siwaju rẹ, o si waa di dandan nibi ẹtọ rẹ jijẹ eewọ jijade juro ni abẹ asẹ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mima da awọn ẹsẹ, nitori titobi asiko ati aaye naa, o si jẹ eewọ fun, mima se ifanfan, eyiti o le mu ibinu wa tabi ija, gbogbo ohun ti ẹ ba se ninu daadaa, Ọlọhun Ọba Allah mọ, Yoo si san yin lẹsan pẹlu rẹ. ki ẹ si wa iranlọwọ lori sise hajj pẹlu pe ki ẹ mu awọn nkan ti ẹ ni bukaata si ninu ounjẹ ati omi, ki ẹ si lọọ ma wipe ohun ti o dara ju lati fi wa iranlọwọ nibi gbogbo alamọri yin, ohun ni ipaya Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ki ẹ ya bẹru Mi, pẹlu mima mu awọn asẹ Mi wa si imusẹ ati jijina si awọn ohun ti Mo kọ, ẹyin ti ẹni laakaye ti o ni alaafia.
لَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَبۡتَغُواْ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكُمۡۚ فَإِذَآ أَفَضۡتُم مِّنۡ عَرَفَٰتٖ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ عِندَ ٱلۡمَشۡعَرِ ٱلۡحَرَامِۖ وَٱذۡكُرُوهُ كَمَا هَدَىٰكُمۡ وَإِن كُنتُم مِّن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلضَّآلِّينَ 198
Ko si ẹsẹ fun yin, ki ẹ wa arisiki ti o jẹ ẹtọ pẹlu owo sise ati nkan miran ni igbati ẹ nse Hajj lọwọ, ti ẹ ba pada lati ‘Arafah’ lẹyin diduro yin nibẹ ni ọjọ kẹsan, ni ẹniti o dojukọ ‘Muzidalifah’ ni oru ọjọ kẹwa ninu ‘Dhil-Hijja’; ki ẹ yaa maa ranti Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mima se ‘Subhaanallah’ ati mima se ‘Lailaaha illaLLah’ ati mima se adua nibi amin ọwọ ni ‘Muzdalifah’, ki ẹ si ranti Ọlọhun Ọba Allah nititori bi O se fi yin mọna, lọ si ibi awọn amin ẹsin Rẹ ati isẹ sise Hajj lọsi ile Rẹ, paapaa, ẹyin nbẹ siwaju nkan naa, ninu afọnufọra nipa ofin Rẹ.
ثُمَّ أَفِيضُواْ مِنۡ حَيۡثُ أَفَاضَ ٱلنَّاسُ وَٱسۡتَغۡفِرُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 199
Lẹyin igba naa, ki ẹ wa kuro ni ‘Arafah’ gẹgẹ bi awọn eniyan ti wọn nkọse Ibrahim (ki ọla maa jẹ tirẹ) se ma nse, ti kii se gẹgẹ bi ẹniti ko duro ni ibẹ ninu awọn eeyan igba aimọkan se ma nse, ki ẹ si wa forijin lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah lori awọn aseeto yin nibi mimu ohun ti o se ni ofin wa, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Alaforijin fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, ti yoo si tun kẹ wọn.
فَإِذَا قَضَيۡتُم مَّنَٰسِكَكُمۡ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَذِكۡرِكُمۡ ءَابَآءَكُمۡ أَوۡ أَشَدَّ ذِكۡرٗاۗ فَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا وَمَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنۡ خَلَٰقٖ 200
Ti ẹ ba pari awọn isẹ Hajj, ti ẹ si setan nibẹ, ki ẹ ya ranti Ọlọhun Ọba Allah, ki ẹ si pọ ni ẹniti yoo maa se ẹyin fun Un, gẹgẹ bi ẹ se ma nse iyanran pẹlu awọn baba yin, ti ẹ si ma nse ẹyin fun wọn pẹlu, tabi ki iranti yin Ọlọhun Ọba Allah le ju iranti awọn baba yin lọ; toripe gbogbo idẹra kọọkan, ti ẹ fi njẹ igbadun, lati ọdọ Rẹ ni, mimọ fun Un, ti ọla Rẹ si ga, oniranran ni awọn eniyan, o nbẹ ninu wọn alaigbagbọ, ti o si jẹ ẹlẹbọ, eyiti ko ni igbagbọ ayaafi pẹlu isẹmi ile aye yii, ko si nii bẹ Ọlọhun Ọba Allah ayaafi idẹra rẹ ati ọsọ rẹ ninu alaafi, ati owo ati ọmọ, ko si si ipin kankan fun wọn ninu ohun ti Ọlọhun Ọba Allah pese fun awọn ẹru Rẹ, ti wọn jẹ olugbagbọ ododo ni ọjọ ikẹyin, nitori rirankan wọn si aye ati gigunri wọn kuro nibi ọjọ ikẹyin.
وَمِنۡهُم مَّن يَقُولُ رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ حَسَنَةٗ وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ 201
Ikọ kan ninu eniyan jẹ olugbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti o si gba ọjọ ikẹyin gbọ, yoo wa maa bẹ Ọlọhun Ọba Allah rẹ, igbadun aye yii ati isẹ rẹ ni ibẹ, gẹgẹ bi yoo se maa beere ni ọwọ Rẹ jijẹ ere pẹlu Alujanna ati lila kuro nibi iya ina.
أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ نَصِيبٞ مِّمَّا كَسَبُواْۚ وَٱللَّهُ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ 202
Awọn wọn nni, ni ẹniti o npe fun oore meji, ti aye ati ọjọ ikẹyin, nbẹ fun wọn erenjẹ ninu ẹsan ti o tobi, pẹlu ohun ti wọn fi ọwọ wọn se ninu awọn isẹ oloore ni ile aye, Ọlọhun Ọba Allah si ni Ẹniti O yara nibi isesiro isẹ.
O jẹ dandan fun olugbagbọ ododo, pipese silẹ nibi irin ajo aye ati irin ajo ọjọ ikẹyin; tori nkan naa ni Ọlọhun Ọba Allah fi sọ pe dajudaju ipese to loore ju ni ipaya Ọlọhun.
Sise pípọ̀ ni iranti Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni ofin ni igbati isẹ Hajj ba pari.
Yiyatọ ero awọn eniyan, ; o nbẹ ninu wọn ẹniti o gbe gbogbo ero rẹ si ile aye, ko si niibi Ọlọhun Ọba Allah Rẹ leere ohun ti o tayọ sii, o si nbẹ ninu wọn ẹniti yoo maa beere lọwọ Rẹ, oore aye ati ti ọjọ ikẹyin, eleyi ni ẹniti wọn fi se kongẹ ire.